Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Rere—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?

Ìwà Rere—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?

GBOGBO wa la fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá sí ẹni tó ń hùwà rere. Àmọ́ kò rọrùn láti jẹ́ ẹni rere nínú ayé yìí torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni “kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (2 Tím. 3:3) Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń gbé ìlànà tiwọn kalẹ̀ nípa ohun rere àti búburú, wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé “ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára.” (Àìsá. 5:20) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa rí àti àìpé wa máa ń jẹ́ kó nira láti jẹ́ ẹni rere. Ó lè máa ṣe àwa náà bíi ti Anne * tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún àmọ́ tó sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti gbà pé mo lè jẹ́ ẹni rere.”

Ohun tó dùn mọ́ wa nínú ni pé gbogbo wa la lè jẹ́ ẹni rere. Ìdí ni pé ìwà rere wà lára àwọn ànímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká ní. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì lágbára ju ohunkóhun tó lè mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ ẹni rere. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká yàn-nà-ná ohun tí ìwà rere jẹ́, ká sì kọ́ bá a ṣe lè túbọ̀ máa hùwà rere.

KÍ NI ÌWÀ RERE?

Tá a bá sọ pé ẹnì kan ní ìwà rere, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà níwà ọmọlúàbí, ó máa ń ṣe ohun tó tọ́, kì í sì í hùwàkiwà. Ẹni rere máa ń wá bó ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà.

O lè ti rí i pé àwọn kan máa ń ṣe ohun rere fáwọn ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn, àmọ́ ṣé ibi tí ìwà rere pin sí nìyẹn? Kéèyàn tó lè jẹ́ ẹni rere lójú Jèhófà, kì í ṣe àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ nìkan ló yẹ kó máa ṣe rere fún. Lóòótọ́, ó níbi tá a lè ṣe rere mọ torí Bíbélì sọ pé “kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníw. 7:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé nínú mi, ìyẹn, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere kankan níbẹ̀.” (Róòmù 7:18) Torí náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan ló lè mú ká ní ànímọ́ yìí.

“JÈHÓFÀ JẸ́ ẸNI RERE”

Jèhófà ló máa ń pinnu ohun tó jẹ́ rere àtohun tó jẹ́ búburú. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ẹni rere ni ọ́, àwọn iṣẹ́ rẹ sì dára. Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.” (Sm. 119:68) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ọ̀nà méjì tí Jèhófà gbà jẹ́ ẹni rere bó ṣe wà nínú ẹsẹ yẹn.

Jèhófà jẹ́ ẹni rere. Kò sígbà tí Jèhófà kì í ṣe rere. Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Màá mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ.” Bí ògo àti oore Jèhófà ṣe ń kọjá, Mósè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini, àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Ẹ́kís. 33:19; 34:6, 7) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí mú kó ṣe kedere pé gbogbo ọ̀nà ni Jèhófà ti jẹ́ ẹni rere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé láyé yìí, Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ ẹni rere, síbẹ̀ òun fúnra ẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.”​—Lúùkù 18:19.

Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹni rere ni

Rere ni àwọn iṣẹ́ Jèhófà. Gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe jẹ́ kó hàn kedere pé ẹni rere ni. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá, àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sm. 145:9) Gbogbo ẹ̀dá ni Jèhófà ń ṣe rere fún, kò yọ ohunkóhun sílẹ̀, ó fún àwa èèyàn ní ẹ̀mí, ó sì ń pèsè ohun tó máa gbé ẹ̀mí wa ró. (Ìṣe 14:17) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń dárí jì wá torí pé ó jẹ́ ẹni rere. Onísáàmù kan sọ pé: “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” (Sm. 86:5) Ó dá wa lójú pé “Jèhófà kò ní fawọ́ ohun rere sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.”​—Sm. 84:11.

“Ẹ KỌ́ BÍ Ẹ ṢE MÁA ṢE RERE”

Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, àwa náà láǹfààní láti máa ṣe rere. (Jẹ́n. 1:27) Síbẹ̀, Bíbélì gba àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run níyànjú pé: “Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere.” (Àìsá. 1:17) Báwo la ṣe lè túbọ̀ di ẹni rere? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ lè jẹ́ káwa Kristẹni di ẹni rere lójú Jèhófà. (Gál. 5:22) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ohun rere ká sì kórìíra ohun tó burú. (Róòmù 12:9) Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lè “fìdí [wa] múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀ rere.”​—2 Tẹs. 2:16, 17.

Ohun kejì ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á kọ́ wa ní “gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere,” á sì mú ká gbára dì “fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (Òwe 2:9; 2 Tím. 3:17) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀, àwọn nǹkan rere nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe lá máa wà lọ́kàn wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi kún àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó ti wà nínú ọkàn wa tẹ́lẹ̀.​—Lúùkù 6:45; Éfé. 5:9.

Ohun kẹta ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe rere. (3 Jòh. 11) A rí àwọn àpẹẹrẹ tó dáa nínú Bíbélì. Kò sí àní-àní pé àwọn àpẹẹrẹ tó dáa jù ni ti Jèhófà àti Jésù. Síbẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ ẹni rere. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì mẹ́nu kan Tàbítà àti Bánábà. (Ìṣe 9:36; 11:22-24) A lè gbé àpẹẹrẹ wọn yẹ̀ wò ká sì kíyè sí àwọn nǹkan rere tí wọ́n ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ ká ronú nípa báwa náà ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Tàbítà àti Bánábà, kíyè sí pé Jèhófà bù kún wọn torí pé wọ́n jẹ́ ẹni rere. Táwa náà bá ń ṣe rere, a máa rí ìbùkún gbà.

A tún lè ronú nípa àwọn ará wa tó ń sapá láti máa ṣe ohun rere lónìí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ tí wọ́n sì “nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” Ká má sì gbàgbé àwọn arábìnrin olóòótọ́ tó ń fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn pé àwọn ń “kọ́ni ní ohun rere.” (Títù 1:8; 2:3) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Roslyn sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń sapá láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kó sì fún wọn níṣìírí nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà míì, síbẹ̀ ó máa ń ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó sì máa ń fún wọn lẹ́bùn kéékèèké tàbí kó ṣe àwọn nǹkan míì fún wọn. Lójú mi, èèyàn dáadáa ni.”

Jèhófà gba àwa èèyàn rẹ̀ níyànjú pé ká “máa wá ohun rere.” (Émọ́sì 5:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà Jèhófà, á sì tún jẹ́ kó máa wù wá láti ṣe ohun tó dáa.

À ń sapá láti máa ṣe rere nígbà gbogbo

Kò yẹ ká máa ronú pé ó dìgbà tá a bá ṣe nǹkan rẹpẹtẹ tàbí tá a ṣe nǹkan ńlá ká tó di oníwà rere. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Tá a bá gbin èso kan, a ò ní ya omi lù ú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ká sì máa retí pé kó hù. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa bomi díẹ̀díẹ̀ sí i látìgbàdégbà, kó lè gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Bí ìwà rere ṣe rí nìyẹn, àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó dà bíi pé kò jọjú tá a bá ṣe fáwọn míì ló máa fi hàn pé a jẹ́ ẹni rere.

Bíbélì rọ̀ wá pé ká “múra tán” láti máa ṣe rere. (2 Tím. 2:21; Títù 3:1) Tá a bá ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn míì, á rọrùn láti rí bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ká sì gbé wọn ró. (Róòmù 15:2) Ìyẹn lè gba pé ká ṣàjọpín àwọn nǹkan tá a ní pẹ̀lú wọn. (Òwe 3:27) Bí àpẹẹrẹ, a lè pè wọ́n pé ká jọ jẹun ká sì fi àǹfààní yẹn gbé ara wa ró. Tá a bá mọ̀ pé ara ẹnì kan ò yá, a lè lọ kí i tàbí ká pè é lórí fóònù, a sì lè fi káàdì ránṣẹ́ sí i. Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ àǹfààní la ní láti máa sọ ‘ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró bó bá ṣe yẹ, kí ó lè ṣe àwọn tó ń gbọ́ wa láǹfààní.’​—Éfé. 4:29.

Bíi ti Jèhófà, ó máa ń wù wá láti ṣe ohun rere fún gbogbo èèyàn, torí náà a kì í ṣe ojúsàájú. Ọ̀nà kan tá a máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. Jésù pàṣẹ fún wa pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, ká sì máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra wa. (Lúùkù 6:27) Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa ṣe ohun tó dáa fáwọn èèyàn torí “kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí.” (Gál. 5:22, 23) Tá a bá ń hùwà rere kódà nígbà tá à ń kojú àdánwò tàbí táwọn èèyàn ń ta kò wá, ìyẹn lè mú káwọn míì wá sínú òtítọ́ ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fògo fún Jèhófà.​—1 Pét. 3:16, 17.

JÈHÓFÀ MÁA BÙ KÚN WA TÁ A BÁ Ń HÙWÀ RERE

Bíbélì sọ pé: “Èèyàn rere máa gba èrè ìwà rẹ̀.” (Òwe 14:14) Kí ni díẹ̀ lára èrè tá a máa rí gbà? Tá a bá ń ṣe ohun tó dáa fáwọn míì, àwọn náà á ṣe bẹ́ẹ̀ sí wa. (Òwe 14:22) Tí wọn ò bá tiẹ̀ ṣe dáadáa sí wa, ẹ jẹ́ ká tẹra mọ́ ìwà rere tá à ń hù torí ìyẹn lè mú kí ọkàn wọn rọ̀, kí inú wọn sì yọ́.​—Róòmù 12:20, àlàyé ìsàlẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ló ti rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣe rere kó sì kórìíra ohun búburú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nancy. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń dàgbà, ìgbé ayé burúkú ni mò ń gbé, mò ń ṣèṣekúṣe mi ò sì bọ̀wọ̀ fún ẹnikẹ́ni. Àmọ́, nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe tí mo sì ń ṣe wọ́n, mo bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀. Ní báyìí mo ti wá níyì lójú ara mi.”

Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká máa hùwà rere ni pé ìwà rere máa ń múnú Jèhófà dùn. Táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ rí ohun tá a ṣe, Jèhófà ń rí i. Ó mọ gbogbo ohun rere tá à ń ṣe àtohun rere tó wà lọ́kàn wa. (Éfé. 6:7, 8) Ó sì dájú pé ó máa san wá lẹ́san. Bíbélì sọ pé: “Ẹni rere ń rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” (Òwe 12:2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti máa hùwà rere nígbà gbogbo. Jèhófà ti ṣèlérí pé “ògo àti ọlá àti àlàáfíà yóò wà fún gbogbo ẹni tó ń ṣe rere.”​—Róòmù 2:10.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.