Sí Títù 2:1-15

  • Ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní fún tọmọdé tàgbà (1-15)

    • Kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ (12)

    • Ìtara fún iṣẹ́ rere (14)

2  Àmọ́ ní tìrẹ, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ máa bá ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní* mu.+  Kí àwọn àgbà ọkùnrin má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, ẹni tó ní àròjinlẹ̀, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára, tí ìfẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀, tó sì ní ìfaradà.  Bákan náà, kí àwọn àgbà obìnrin jẹ́ ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, kí wọ́n má ṣe jẹ́ abanijẹ́, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ọ̀mùtí, kí wọ́n máa kọ́ni ní ohun rere,  kí wọ́n lè máa gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú* láti nífẹ̀ẹ́ ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn,  láti jẹ́ aláròjinlẹ̀, oníwà mímọ́, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ilé,* ẹni rere, tó ń tẹrí ba fún ọkọ,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  Bákan náà, máa gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ aláròjinlẹ̀.+  Ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ àpẹẹrẹ nínú àwọn iṣẹ́ rere. Máa fọwọ́ pàtàkì mú kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí kò lábààwọ́n,*+  máa lo ọ̀rọ̀ tó dáa* tí wọn kò lè ṣàríwísí rẹ̀;+ kí ojú lè ti àwọn alátakò, kí wọ́n má sì rí ohun tí kò dáa* sọ nípa wa.+  Kí àwọn ẹrú máa tẹrí ba fún àwọn ọ̀gá wọn nínú ohun gbogbo,+ kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọ́n má sì gbó wọn lẹ́nu, 10  kí wọ́n má ṣe jí nǹkan wọn,+ ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tí èèyàn lè fọkàn tán pátápátá, kí wọ́n lè túbọ̀ ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà.+ 11  Nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ti hàn kedere, kí onírúurú èèyàn lè rí ìgbàlà.+ 12  Èyí ń kọ́ wa pé ká kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀,+ ká sì máa fi àròjinlẹ̀, òdodo àti ìfọkànsìn Ọlọ́run gbé nínú ètò àwọn nǹkan yìí,*+ 13  bí a ti ń dúró de àwọn ohun aláyọ̀ tí à ń retí+ àti bí Ọlọ́run Olódùmarè ṣe máa fara hàn nínú ògo pẹ̀lú Olùgbàlà wa, Jésù Kristi, 14  ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nítorí wa+ kó lè tú wa sílẹ̀*+ kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà tí kò bófin mu, kó sì wẹ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́, àwọn ohun ìní rẹ̀ pàtàkì, tí wọ́n ní ìtara fún iṣẹ́ rere.+ 15  Máa sọ nǹkan wọ̀nyí, máa gbani níyànjú, kí o sì máa fi gbogbo àṣẹ tí o ní bá wọn wí.+ Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan fojú kéré rẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “pe orí wọn wálé; kọ́ wọn.”
Tàbí “tọ́jú ilé.”
Tàbí kó jẹ́, “kíkọ́ni láìlábààwọ́n.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “ohun búburú.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “rà wá pa dà; gbà wá sílẹ̀.”