Sí Àwọn Ará Róòmù 7:1-25

  • Àpèjúwe bí a ṣe dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ Òfin (1-6)

  • Òfin fi ẹ̀ṣẹ̀ hàn (7-12)

  • Ó ń bá ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀yá ìjà (13-25)

7  Ǹjẹ́ a lè sọ pé ẹ ò mọ̀, ẹ̀yin ará, (torí àwọn tó mọ òfin ni mò ń bá sọ̀rọ̀,) pé Òfin jẹ́ ọ̀gá lórí èèyàn ní gbogbo ìgbà tó bá fi wà láàyè?  Bí àpẹẹrẹ, òfin de obìnrin tí a gbé níyàwó mọ́ ọkọ rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin náà bá wà láàyè; àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, a dá a sílẹ̀ kúrò lábẹ́ òfin ọkọ rẹ̀.+  Torí náà, nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè, a ó pè é ní alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin rẹ̀, kì í sì í ṣe alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, a ti sọ ẹ̀yin náà di òkú sí Òfin nípasẹ̀ ara Kristi, kí ẹ lè di ti ẹlòmíì,+ ẹni tí a gbé dìde kúrò nínú ikú,+ kí a lè máa so èso fún Ọlọ́run.+  Torí nígbà tí à ń gbé lọ́nà ti ara, àwọn ìfẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin mú kó hàn síta ń ṣiṣẹ́ nínú ara* wa, kí ó lè mú èso ikú jáde.+  Àmọ́ ní báyìí, a ti dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Òfin,+ torí a ti kú sí èyí tó ń ká wa lọ́wọ́ kò tẹ́lẹ̀, kí a lè jẹ́ ẹrú ní ọ̀nà tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ kì í sì í ṣe ní ọ̀nà àtijọ́ nípasẹ̀ àkọsílẹ̀ òfin.+  Kí wá ni ká sọ? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ká sòótọ́, mi ò bá má ti mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í bá ṣe Òfin.+ Bí àpẹẹrẹ, mi ò bá má mọ ojúkòkòrò ká ní Òfin ò sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.”+  Àmọ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe rí àyè nípasẹ̀ àṣẹ, ó mú kí n máa ṣojúkòkòrò lóríṣiríṣi ọ̀nà, nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ òkú.+  Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí mo wà láàyè láìsí òfin. Àmọ́ nígbà tí àṣẹ dé, ẹ̀ṣẹ̀ tún sọ jí, mo sì kú.+ 10  Àṣẹ tó yẹ kó yọrí sí ìyè+ ni mo rí pé ó yọrí sí ikú. 11  Nítorí bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe rí àyè nípasẹ̀ àṣẹ, ó sún mi dẹ́ṣẹ̀, ó sì tipasẹ̀ rẹ̀ pa mí. 12  Torí náà, Òfin jẹ́ mímọ́ láyè ara rẹ̀, àṣẹ sì jẹ́ mímọ́, ó jẹ́ òdodo, ó sì dára.+ 13  Nígbà náà, ṣé ohun tó dára ló yọrí sí ikú mi ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ẹ̀ṣẹ̀ ni, kí a lè fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ló yọrí sí ikú mi nípasẹ̀ ohun tó dára,+ kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àṣẹ, ẹ̀ṣẹ̀ á túbọ̀ burú sí i.+ 14  Nítorí a mọ̀ pé Òfin jẹ́ ti ẹ̀mí, àmọ́ mo jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.+ 15  Ohun tí mò ń ṣe kò yé mi. Torí kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni mò ń ṣe, àmọ́ ohun tí mo kórìíra ni mò ń ṣe. 16  Síbẹ̀, tí mo bá ń ṣe ohun tí mi ò fẹ́, á jẹ́ pé mo gbà pé Òfin dára nìyẹn. 17  Àmọ́ ní báyìí, ẹni tó ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbé inú mi ni.+ 18  Nítorí mo mọ̀ pé nínú mi, ìyẹn, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere kankan níbẹ̀; torí ó ń wù mí láti ṣe ohun tó dára, àmọ́ mi ò ní agbára láti ṣe é.+ 19  Nítorí kì í ṣe rere tí mo fẹ́ ni mò ń ṣe, búburú tí mi ò fẹ́ ni mò ń ṣe. 20  Torí náà, tó bá jẹ́ pé ohun tí mi ò fẹ́ ni mò ń ṣe, ẹni tó ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbé inú mi ni. 21  Mo wá rí òfin yìí nínú ọ̀rọ̀ mi pé: Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.+ 22  Nínú mi lọ́hùn-ún,+ mo nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an, 23  àmọ́ mo rí òfin míì nínú ara* mi+ tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀+ tó wà nínú ara* mi. 24  Èmi abòṣì èèyàn! Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí? 25  Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa! Torí náà, nínú èrò inú mi, mo jẹ́ ẹrú òfin Ọlọ́run, àmọ́ nínú ẹran ara mi, mo jẹ́ ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”