Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 11:1-30

  • Pétérù ròyìn fún àwọn àpọ́sítélì (1-18)

  • Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wà ní Áńtíókù ti Síríà (19-26)

    • Ìgbà àkọ́kọ́ tí a pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni (26)

  • Ágábù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa mú (27-30)

11  Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ará tó wà ní Jùdíà gbọ́ pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  Torí náà, nígbà tí Pétérù wá sí Jerúsálẹ́mù, àwọn tó ń ti ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́*+ lẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí rẹ̀,*  wọ́n sọ pé: “O wọ ilé àwọn tí kò dádọ̀dọ́,* o sì bá wọn jẹun.”  Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà fún wọn, ó ní:  “Ìlú Jópà ni mo wà tí mo ti ń gbàdúrà, mo sì rí ìran kan nígbà tí mo wà lójú ìran, ohun* kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí a fi igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì wá tààrà sọ́dọ̀ mi.+  Bí mo ṣe tẹjú mọ́ ọn, mo rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin orí ilẹ̀, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹran tó ń fàyà fà* àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.  Mo tún gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi pé: ‘Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!’  Àmọ́ mo sọ pé: ‘Rárá o, Olúwa, torí ohun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ kò wọ ẹnu mi rí.’  Nígbà kejì, ohùn tó wá láti ọ̀run náà sọ pé: ‘Yéé pe àwọn ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.’ 10  Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, a sì fa gbogbo rẹ̀ pa dà sókè ọ̀run. 11  Ní àkókò yẹn náà, àwọn ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé tí a wà, wọ́n rán wọn sí mi láti Kesaríà.+ 12  Ni ẹ̀mí bá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láìṣiyèméjì rárá. Àwọn arákùnrin mẹ́fà yìí náà bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà. 13  “Ó ròyìn fún wa bí ó ṣe rí áńgẹ́lì tó dúró ní ilé rẹ̀ tó sì sọ pé: ‘Rán àwọn èèyàn sí Jópà, kí o sì ní kí wọ́n pe Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù wá,+ 14  yóò sọ ohun tó máa mú kí ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ rí ìgbàlà.’ 15  Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn bó ṣe bà lé wa ní ìbẹ̀rẹ̀.+ 16  Ni mo bá rántí ọ̀rọ̀ tí Olúwa máa ń sọ, pé: ‘Jòhánù fi omi batisí,+ àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.’+ 17  Torí náà, tí Ọlọ́run bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà tí ó fún àwa tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí màá fi dí Ọlọ́run lọ́wọ́?”*+ 18  Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọn ò ta kò ó mọ́,* wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé: “Tóò, Ọlọ́run ti fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láǹfààní láti ronú pìwà dà kí àwọn náà lè ní ìyè.”+ 19  Nígbà náà, àwọn tí ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù mú kí wọ́n tú ká+ ń lọ títí dé Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù, àmọ́ àwọn Júù nìkan ni wọ́n ń wàásù fún.+ 20  Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn tó wá láti Sápírọ́sì àti Kírénè wá sí Áńtíókù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, wọ́n ń kéde ìhìn rere Jésù Olúwa. 21  Yàtọ̀ síyẹn, ọwọ́ Jèhófà* wà lára wọn, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́, wọ́n sì yíjú sí Olúwa.+ 22  Ìròyìn nípa wọn dé ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rán Bánábà+ lọ títí dé Áńtíókù. 23  Nígbà tó dé, tó sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, inú rẹ̀ dùn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa fi gbogbo ọkàn wọn ṣègbọràn sí Olúwa;+ 24  èèyàn rere ni, ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ Olúwa.+ 25  Nítorí náà, ó lọ sí Tásù láti wá Sọ́ọ̀lù kàn.+ 26  Lẹ́yìn tó rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Odindi ọdún kan ni wọ́n fi ń pé jọ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ, wọ́n sì kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, Áńtíókù ni Ọlọ́run ti kọ́kọ́ mú kí á máa pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.+ 27  Ní àkókò yẹn, àwọn wòlíì+ wá láti Jerúsálẹ́mù sí Áńtíókù. 28  Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Ágábù + dìde, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí pé ìyàn ńlá máa tó mú ní gbogbo ilẹ̀ ayé+ tí à ń gbé, èyí sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ lásìkò Kíláúdíù. 29  Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé,+ láti fi nǹkan ìrànwọ́*+ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà; 30  ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn, wọ́n fi rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sí àwọn alàgbà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “bá a jiyàn.”
Tàbí “kọlà.”
Ní Grk., “oríṣi ohun èlò.”
Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”
Tàbí “dènà Ọlọ́run?”
Ní Grk., “wọ́n dákẹ́.”
Tàbí “ìpèsè adínṣòrokù.”