Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èyí Ni Ogún Tẹ̀mí Wa

Èyí Ni Ogún Tẹ̀mí Wa

“Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.”—AÍSÁ. 54:17.

1. Ohun pàtàkì wo ni Jèhófà sọ fún wa nínú Bíbélì?

“ỌLỌ́RUN alààyè, tí ó sì wà pẹ́ títí” ni Jèhófà. Ó sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa wà láàyè títí láé fún wa. Àwọn ohun tó sọ ò sì tíì yí pa dà, torí pé “àsọjáde Jèhófà wà títí láé.” (1 Pét. 1:23-25) Torí náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì yìí fún wa nínú Bíbélì!

2. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ nípa òun?

2 Jèhófà fẹ́ kí gbogbo wa mọ orúkọ òun. Inú Jẹ́nẹ́sísì 2:4 ni orúkọ náà ti kọ́kọ́ fara hàn, nígbà tí Bíbélì ń sọ ìtàn bí ‘Jèhófà Ọlọ́run ṣe dá ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.’ Yàtọ̀ síyẹn, orúkọ Ọlọ́run tún fara hàn nígbà mélòó kan lára wàláà òkúta tó kọ Òfin Mẹ́wàá sí. Bí àpẹẹrẹ, òfin kìíní sọ pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Ẹ́kís. 20:1-17) Èṣù ti gbìyànjú gan-an láti pa Bíbélì run ká má bàa mọ Ọlọ́run àti orúkọ Rẹ̀. Àmọ́, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kò gbà fún un.—Sm. 73:28.

3. Kí tún ni ohun mìíràn tí Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ nínú Bíbélì?

3 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìsìn ti fi kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run ni kò bá Bíbélì mu. Àmọ́, Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Torí náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé Bíbélì ṣàlàyé òtítọ́ fún wa lọ́nà tó ṣe kedere! (Ka Sáàmù 43:3, 4.) Ó wá dà bíi pé à ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ nígbà tí aráyé ń rìn nínú òkùnkùn.—1 Jòh 1:6, 7.

A NÍ OGÚN PÀTÀKÌ

4, 5. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni Ọlọ́run fún wa lọ́dún 1931?

4 Kì í ṣòro láti dá àwọn tó wá láti abúlé tàbí àdúgbò kan náà mọ̀. Ìwà wọn, àṣà wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nǹkan kì í sábàá yàtọ̀, bó sì ṣe máa ń wà láti ìran dé ìran nìyẹn. A lè pe gbogbo èyí ní ogún wọn. Lọ́nà kan náà, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ogún tẹ̀mí. Lára ogún tẹ̀mí yìí ni bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká lóye Bíbélì dáadáa àti bó ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí òun jẹ́ àtàwọn nǹkan tó ti pinnu láti ṣe. Síbẹ̀ Ọlọ́run tún fún wa ní àǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Inú wa dùn láti gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1931

5 Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yìí di apá kan ogún tẹ̀mí wa ní àpéjọ àgbègbè kan tó wáyé lọ́dún 1931, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n tẹ “JW” sára ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà. Àdììtú ni ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ fáwọn ará, olúkúlùkù sì ń sọ ohun tó rò pé ó túmọ̀ sí. Nígbà tó yá la wá mọ̀ pé lẹ́tà méjì tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ wa tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Jehovah’s Witnesses, ni wọ́n. Ká tó ṣe àpéjọ yẹn, Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn èèyàn máa ń pè wá. Àmọ́, ní July 26, ọdún 1931, tó jẹ́ ọjọ́ Sunday, gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà gbà láti máa jẹ́ orúkọ kan tá a mú látinú Bíbélì, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáwọn ará lọ́jọ́ náà! (Ka Aísáyà 43:12.) Arákùnrin kan sọ pé: “Mi ò lè gbàgbé ìhó ayọ̀ àwọn ará àti bí àtẹ́wọ́ wọn ṣe ń dún bí ààrá.” Ó ti lé ní ọgọ́rin [80] ọdún báyìí tí Ọlọ́run ti fi orúkọ náà dá wa lọ́lá. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ la kà á sí láti máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

6. Ohun mìíràn wo ló tún jẹ́ ara ogún tẹ̀mí wa?

6 Ohun mìíràn tún wà tó jẹ́ ara ogún tẹ̀mí wa. Bíbélì sọ ohun pàtàkì kan fún wa nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ohun tó sọ fún wa nípa wọn sì ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa nípa Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Ó dájú pé ìgbà gbogbo ni wọ́n á máa kọ́ àwọn aya àtàwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe lè rí ojú rere Jèhófà. Ó sì ní láti jẹ́ pé irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tí kò fi bá aya ọ̀gá rẹ̀ ṣèṣekúṣe. (Jẹ́n. 39:7-9) Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni náà máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìjọ nípa ohun tí Jésù kọ́ ọ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. (1 Kọ́r. 11:2, 23) Gbogbo ìsọfúnni yìí ló wà nínú Bíbélì ká lè mọ bó ṣe yẹ ká máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. (Ka Jòhánù 4:23, 24.) Òótọ́ ni pé kò sí ẹni tí Bíbélì ò lè ràn lọ́wọ́, àmọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló yẹ ká mọyì rẹ̀ jù lọ.

7. Ìlérí wo ló jẹ́ ara ogún tẹ̀mí wa?

7 Jèhófà ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní pẹ̀lú. (Sm. 118:7) A máa ń kà nípa àwọn ọ̀nà tó ń gbà dáàbò bò wá nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Irú àwọn ìsọfúnni yìí ni kì í jẹ́ ká ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa. Èyí tó tún wá pabanbarì lára ogún tẹ̀mí wa yìí ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa pé ohun ìjà yòówù, tàbí lédè mìíràn, ohun yòówù káwọn alátakò ṣe láti gbéjà kò wá, kò ní ṣe àṣeyọrí sí rere. Bí àwọn míì bá sì gbìyànjú láti parọ́ mọ́ wa nílé ẹjọ́, àṣírí wọn á tú, torí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òdodo wa ti wá. Ìlérí yìí náà jẹ́ ara ogún tẹ̀mí wa. (Aísá. 54:17) Ó dá wa lójú pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn ohun ìjà Sátánì tó máa pa gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà run.

8. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e?

8 Sátánì ti gbìyànjú gan-an láti pa Bíbélì run, ó ti sapá láti sọ orúkọ náà, Jèhófà di ìgbàgbé, kò sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́. Àmọ́, pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ ń já sí, torí pé Jèhófà ń fi àjùlọ hàn án. Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa (1) bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́; (2) bí Jèhófà kò ṣe jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ di ìgbàgbé; àti (3) bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ òtítọ́ lónìí.

JÈHÓFÀ PA BÍBÉLÌ MỌ́

9-11. Báwo ni Jèhófà ṣe pa Bíbélì mọ́?

9 Àwọn ọ̀tá ti sapá lọ́pọ̀ ìgbà láti pa Bíbélì run, àmọ́ ńṣe ni Jèhófà ń pa á mọ́. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì pàápàá ti gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn má ka Bíbélì mọ́. Ní ọdún 1229, Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbógun ti àwọn tó túmọ̀ Bíbélì. Torí náà, wọ́n ṣòfin pé àwọn ọmọ ìjọ kò gbọ́dọ̀ ka Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè ìbílẹ̀. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ níbi àpérò kan tó wáyé lórílẹ̀-èdè Sípéènì, lọ́dún 1234. Nígbà tó di ọdún 1559, Póòpù Paul Kẹrin dá sí ọ̀rọ̀ náà fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sì ṣòfin pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ tẹ Bíbélì, ẹnikẹ́ni kò sì gbọ́dọ̀ ní in lọ́wọ́, láìkọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

10 Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn ṣe ń gbìyànjú tó láti pa Bíbélì run, ńṣe ni Jèhófà ń pa á mọ́. Ní nǹkan bí ọdún 1382, Ọ̀gbẹ́ni John Wycliffe àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ìgbà àkọ́kọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, Ọ̀gbẹ́ni William Tyndale náà túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nítorí èyí, wọ́n pa á lọ́dún 1536. Wọ́n kọ́kọ́ dè é mọ́gi. Ó wá ń kígbe pé: “Olúwa, jọ̀wọ́ la ọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lójú o!” Lẹ́yìn náà, wọ́n fún un lọ́rùn pa, wọ́n sì fi iná sun òkú rẹ̀.

11 Ní ọdún 1535, Ọ̀gbẹ́ni Miles Coverdale náà túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ló gbé ìtumọ̀ rẹ̀ kà. Ó lo apá kan lára Bíbélì tí Ọgbẹ́ni Tyndale túmọ̀. Ó gbé apá tó kù karí ìtumọ̀ èdè Latin àti Bíbélì tí Ọ̀gbẹ́ni Martin Luther tú sí èdè Jámánì. Lóde òní, Bíbélì mìíràn wà lédè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn láti lóye, tí kò fi òtítọ́ pa mọ́, tó sì rọrùn láti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Orúkọ Bíbélì yìí lédè Yorùbá ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún wa láti ní Ìwé Mímọ́ yìí. Ó dájú pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè pa Bíbélì run. Sátánì gan-an ò tó bẹ́ẹ̀!

JÈHÓFÀ PA ORÚKỌ RẸ̀ MỌ́

Látinú Book of Martyrs látọwọ́ Foxe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Tyndale àtàwọn míì kú nítorí Bíbélì

12. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe mú káwọn èèyàn mọ orúkọ náà, Jèhófà?

12 Jèhófà Ọlọ́run ò gbà káwọn èèyàn yọ orúkọ òun kúrò nínú gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì. Àwọn tó ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun rí sí i pé àwọn lo orúkọ náà, Jèhófà ní gbogbo ibi tó ti fara hàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì lédè Hébérù àti Gíríìkì. Orúkọ náà fara hàn ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ó dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [6,973] nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó sì fara hàn ní ìgbà òjìlénígba-ó-dín-mẹ́ta [237] nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ní báyìí, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà ní èdè tó ju mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116] lọ. Iye tá a ti tẹ̀ jáde sì ti ju mílíọ̀nù méjì-dín-lọ́gọ́sàn-án àtààbọ̀ [178,500,000] lọ.

13. Kí ló fi hàn pé látọjọ́ táláyé ti dáyé làwọn èèyàn ti mọ orúkọ Ọlọ́run?

13 Ádámù àti Éfà mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì lo orúkọ náà. (Jẹ́n. 4:1) Nóà pẹ̀lú lo orúkọ Ọlọ́run. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 9:26, ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, Ọlọ́run Ṣémù.” Nígbà tí Ọlọ́run ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, òun náà lo orúkọ náà. Ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.” Ọlọ́run tún sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn. Yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.” (Aísá. 42:8; 45:5) Ìdí tí Jèhófà fi pa orúkọ rẹ̀ mọ́ ni pé ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn tó wà láyé mọ orúkọ náà. Ohun iyì ló jẹ́ fún wa pé à ń lo orúkọ náà Jèhófà, a sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ìyẹn ni onísáàmù náà fi sọ pé: “Ní orúkọ Ọlọ́run wa ni a óò gbé àwọn ọ̀págun wa sókè.”—Sm. 20:5.

14. Yàtọ̀ sí inú Bíbélì, ibo ni orúkọ Ọlọ́run tún ti fara hàn?

14 Inú Bíbélì nìkan kọ́ la ti lè rí orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ náà wà lára Òkúta Móábù, tí wọ́n rí ní ìlú Díbónì. Ìlú yìí fi kìlómítà mọ́kànlélógún jìnnà sí Òkun Òkú, tá a bá gba apá ìlà oòrùn wọ̀ ọ́. Orúkọ Ómírì ọba Ísírẹ́lì wà lára ìtàn tí wọ́n kọ sára òkúta náà. Ìtàn náà sì sọ bí Méṣà, ọba Móábù ṣe ń gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (1 Ọba 16:28; 2 Ọba 1:1; 3:4, 5) Ṣùgbọ́n ohun tó ṣe pàtàkì nípa Òkúta Móábù náà ni pé lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run wà lára rẹ̀. Lẹ́tà mẹ́rin yìí tún fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Àwọn Lẹ́tà Lákíṣì, ìyẹn ni àwọn àpáàdì tàbí àkúfọ́ ìkòkò tí wọ́n rí nílẹ̀ Ísírẹ́lì.

15. Kí ló ń jẹ́ Septuagint? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

15 Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún báyìí tí àwọn atúmọ̀ èdè ti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí èdè Gíríìkì? Ìtàn fi hàn pé àádọ́rin [70] ọdún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà ní ìgbèkùn ní ìlú Bábílónì. Nígbà tí wọ́n kúrò ní ìgbèkùn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn kan lára wọn yàn láti máa gbé ní Bábílónì. Nígbà tó ṣe, ọ̀pọ̀ nínú wọn kó lọ sí ìlú Alẹkisáńdíríà tó wà ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Èdè Gíríìkì tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ kárí ayé nígbà yẹn làwọn èèyàn ń sọ níbẹ̀. Torí náà, àwọn Júù tó kó lọ síbẹ̀ máa nílò Ìwé Mímọ́ Hébérù tá a túmọ̀ sí èdè Gíríìkì. Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì yẹn ló ń jẹ́ Septuagint. Àwọn kan lára ìtumọ̀ náà ní lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ náà, Jèhófà.

16. Báwo ni ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1640 ṣe lo orúkọ Ọlọ́run?

16 Àwọn ìlú kan wà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń ṣàkóso lé lórí nígbà kan. Lára àwọn ìlú yìí ni wọ́n ti kọ́kọ́ túmọ̀ ìwé Sáàmù tí orúkọ Ọlọ́run wà nínú rẹ̀. Orúkọ tí wọ́n pe ìtumọ̀ yìí ni, Bay Psalm Book. Ọdún 1640 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé náà jáde. Ọ̀kan lára ibi tí orúkọ Ọlọ́run sì wà nínú rẹ̀ ni Sáàmù 1:1, 2, tó sọ pé, “ìbùkún ni fún ọkùnrin” tí kì í tẹ́tí sí ìmọ̀ràn àwọn èèyàn búburú, àmọ́ tó máa ń fẹ́ láti tẹ́tí sí “òfin Iehovah.” Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa orúkọ Ọlọ́run wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae.

JÈHÓFÀ PA Ẹ̀KỌ́ ÒTÍTỌ́ MỌ́

17, 18. (a) Kí ni òtítọ́? (b) Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ ara “òtítọ́ ìhìn rere”?

17 À ń fayọ̀ sin “Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Kí ni òtítọ́? A lè sọ pé òtítọ́ ni bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nípa ohun kan láì fi ohunkóhun pa mọ́. Kì í ṣe ohun tí èèyàn kàn hùmọ̀ rẹ̀ lásán. Nínú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń túmọ̀ sí “òtítọ́” sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó jẹ́ òótọ́, ohun tó tọ̀nà àti ohun tó ṣeé gbára lé.

18 Jèhófà pa ẹ̀kọ́ òtítọ́ mọ́, kí àwa tá à ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lónìí lè lóye rẹ̀. (2 Jòh. 1, 2) Òye tá a ní nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Èyí bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, òun náà sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an ni Jésù sọ yẹn, torí pé “òtítọ́ ìhìn rere” wà nínú Bíbélì. Òtítọ́ ìhìn rere yìí ni àpapọ̀ gbogbo nǹkan tí àwa Kristẹni gbà gbọ́. (Gál. 2:14) Lára àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ ìhìn rere ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa orúkọ náà, Jèhófà, ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ẹbọ ìràpadà Jésù, àjíǹde àti Ìjọba Ọlọ́run. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe pa òtítọ́ yìí mọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ náà.

JÈHÓFÀ Ò GBÀ KÍ SÁTÁNÌ FI ÒTÍTỌ́ PA MỌ́

19, 20. Ta ni Nímírọ́dù? Kí làwọn èèyàn gbìyànjú láti ṣe nígbà tó ń ṣàkóso?

19 Lẹ́yìn Ìkún-omi, ọdẹ alágbára kan wà tó ta ko Jèhófà. Nímírọ́dù ni orúkọ rẹ̀. (Jẹ́n. 10:9) Ohun tó ṣe mú kó sọ ara rẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn Sátánì. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá dà bíi ti àwọn tó ta ko Ọmọ Ọlọ́run nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ fún wọn nígbà yẹn pé: “Ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín,” ẹní tí kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.”—Jòh. 8:44.

20 Nímírọ́dù ṣàkóso lórí Bábélì àtàwọn ìlú míì tó wà láàárín odò Tígírísì àti odò Yúfírétì. (Jẹ́n. 10:10) Ó lè jẹ́ pé òun ló pàṣẹ pé káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Bábélì àti ilé gogoro tó wà níbẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 2269 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, ìyẹn ta ko ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn pé káwọn èèyàn máa gbé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀ àwọn èèyàn náà ń sọ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa, kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àmọ́ àwọn èèyàn náà kò ṣàṣeyọrí, torí pé Ọlọ́run “da èdè gbogbo ilẹ̀ ayé rú.” Látàrí ìyẹn, àwọn èèyàn náà kúrò ní Bábélì, wọ́n sì tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 11:1-4, 8, 9) A ti wá rí i báyìí pé òótọ́ ni Sátánì ń gbìyànjú kó lè kẹ̀yìn àwa èèyàn sí Ọlọ́run, kí gbogbo èèyàn sì máa jọ́sìn rẹ̀. Àmọ́, Jèhófà pa ìsìn tòótọ́ mọ́, àwọn èèyàn tó ń fẹ́ láti máa sin Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.

21, 22. (a) Kí nìdí tí ìsìn èké kò fi lè pa ìjọsìn tòótọ́ run? (b) Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Ìsìn èké ti sapá gidigidi láti pa ìsìn tòótọ́ run, àmọ́ kò ṣàṣeyọrí. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sí olùkọ́ tó dà bíi Jèhófà. Ó rí i dájú pé a ní Bíbélì, a mọ orúkọ òun, a sì lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Aísá. 30:20, 21) Tá a bá sin Ọlọ́run bó ṣe fẹ́ ká sin òun, a máa ní ojúlówó ayọ̀. Àmọ́, ìyẹn gba pé ká máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí ní gbogbo ìgbà, ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì máa gbára lé àwọn ìtọ́sọ́nà tá à ń rí gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.

22 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí ibi tí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ èké ti ṣẹ̀ wá. A máa rí i pé Ìwé Mímọ́ ò fi irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ kọ́ wa. A sì máa rí i pé ará ogún tẹ̀mí wa ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a mọ̀ nípa Jèhófà jẹ́.