ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ February 2013

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ àkànṣe ogún tí Jèhófà fún àwa èèyàn rẹ̀. Ó tún ṣàlàyé bá a ṣe lè dúró síbi ààbò Jèhófà.

Èyí Ni Ogún Tẹ̀mí Wa

Máa gbé àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún gbogbo èèyàn yẹ̀ wò àti ohun tó ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀, èyí á jẹ́ kó o lè túbọ̀ mọyì ogún tẹ̀mí wa.

Ǹjẹ́ O Mọyì Ogún Tẹ̀mí Wa?

Tó o bá mọ̀ nípa ogún tẹ̀mí wa tó o sì mọyì rẹ̀, ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.

Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Olú Ọba Gbọ́ Ìhìn Rere

Ìgbà gbogbo ni Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù. Wo bí àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe lè rán ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe bíi tiẹ̀.

Dúró Sí Ibi Ààbò Jèhófà

Kí ni àfonífojì ààbò túmọ̀ sí, báwo sì ní àwọn tó ń sin Jèhófà ṣe lè rí ààbò níbẹ̀?

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Tàn Ẹ́ Jẹ

Nígbà míì, ọkàn wa lè máa wí àwíjàre nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí kò dára. Kí lá jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an?

Sá Fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá ẹ Lọ́lá

Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí Ọlọ́run dá ẹ lọ́lá? Kí ló lè mú kí Ọlọ́run á dá ẹ lọ́lá?

Ìbátan Káyáfà Ni

Ohun tí wọ́n hú jáde nípa Míríámù jẹ́ ká mọ pé àwọn tí Bíbélì dárúkọ wọn gbé ayé lóòótọ́, a sì mọ ìdílé wọn.

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Ohun Mánigbàgbé” Tó Bọ́ Sákòókò

Wo bí sinimá túntun tó ń jẹ́ “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá” ṣe ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá ní Jámánì lọ́wọ́ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.