Ìwé Kejì Jòhánù 1:1-13

  • Ìkíni (1-3)

  • Máa rìn nínú òtítọ́ (4-6)

  • Ṣọ́ra fún àwọn ẹlẹ́tàn (7-11)

    • Ẹ má ṣe kí i (10, 11)

  • Ìbẹ̀wò tó fẹ́ ṣe àti ìkíni (12, 13)

 Àgbà ọkùnrin,* sí obìnrin tí Ọlọ́run yàn àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí mo nífẹ̀ẹ́ tọkàntọkàn. Èmi nìkan kọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ yín, gbogbo àwọn tó ti wá mọ òtítọ́ pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ yín,  torí òtítọ́ tó wà nínú wa, tó sì máa wà pẹ̀lú wa títí láé.  Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà pẹ̀lú òtítọ́ àti ìfẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Ọmọ Baba yóò wà pẹ̀lú wa.  Inú mi dùn gan-an torí mo rí lára àwọn ọmọ rẹ tó ń rìn nínú òtítọ́,+ bí Baba ṣe pa á láṣẹ fún wa.  Torí náà, mò ń rọ̀ ẹ́, ìwọ obìnrin, (àṣẹ tí a ní láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí ọ, kì í ṣe àṣẹ tuntun), pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.+  Èyí sì ni ohun tí ìfẹ́ jẹ́, pé ká máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ rẹ̀.+ Àṣẹ náà nìyí, bí ẹ ṣe gbọ́ ọ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí ẹ máa rìn nínú ìfẹ́.  Nítorí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti wà nínú ayé,+ àwọn tí kò gbà pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara.*+ Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.+  Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ má bàa mú kí iṣẹ́ wa já sí asán, ṣùgbọ́n kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.+  Ẹnikẹ́ni tó bá ń kọjá àyè rẹ̀ tí kò sì tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Kristi kì í ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.+ Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ yìí ni ọ̀rẹ́ Baba àti Ọmọ.+ 10  Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé,+ ẹ má sì kí i. 11  Nítorí ẹni tó bá kí i ti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀. 12  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo fẹ́ bá yín sọ, mi ò fẹ́ fi ìwé àti yíǹkì kọ wọ́n sí yín, àmọ́ mò ń retí láti wá sọ́dọ̀ yín ká lè sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́. 13  Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ, ẹni tí Ọlọ́run yàn, ń kí ọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Alàgbà.”
Ní Grk., “wá nínú ara.”