“Afọgbọ́nhùwà Máa Ń Ronú Nípa Àwọn Ìṣísẹ̀ Ara Rẹ̀”
“Afọgbọ́nhùwà Máa Ń Ronú Nípa Àwọn Ìṣísẹ̀ Ara Rẹ̀”
TÁ A bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ afọgbọ́nhùwà, ohun tá à ń sọ ni pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ onílàákàyè, ọlọ́gbọ́n, olóye ẹ̀dá àti ẹni tó ń ronú jinlẹ̀ kó tó hùwà. Onítọ̀hún kì í ṣe oníbékebèke tàbí ẹlẹ̀tàn. Òwe 13:16 sọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà.” Ká sòótọ́, kò sóhun tó dà bíi kéèyàn jẹ́ afọgbọ́nhùwà.
Báwo la ṣe lè máa fi ọgbọ́n hùwà nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́? Báwo làwọn ìpinnu tá à ń ṣe àti bá a ṣe ń hùwà sáwọn ẹlòmíràn àtohun tá a máa ń ṣe nínú ipòkípò tá a bá wà ṣe lè fi hàn pé à ń fi ọgbọ́n hùwà? Èrè wo làwọn afọgbọ́nhùwà máa ń jẹ? Àwọn ewu wo ni wọn kì í kó sí? Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú ìwé Òwe 14:12-25. a
Máa Rìn Ní Ọ̀nà Tó Tọ́
Kí ẹnì kan tó lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání kí nǹkan sì máa lọ déédéé nígbèésí ayé rẹ̀, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 14:12) Nítorí náà, ó yẹ ká mọ bá a ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó dà bíi pé ó tọ́ àti ohun tó tọ́. Ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọ̀nà ikú” jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀nà tó jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tàn pọ̀ rẹpẹtẹ. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun kan tó yẹ ká ṣọ́ra fún.
Ojú ẹni iyì àti ẹni ẹ̀yẹ làwọn èèyàn máa fi ń wo àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn gbajúmọ̀ láwùjọ. Bá a bá ń rí bí wọ́n ṣe ń láásìkí àti báwọn èèyàn ṣe ń yẹ́ wọn sí láwùjọ, ó ṣeé ṣe ká máa ronú pé ọ̀nà tó tọ́ ni wọ́n gbà ń ṣe nǹkan. Àmọ́, ọ̀nà wo ni ọ̀pọ̀ lára irú àwọn olówó àti gbajúmọ̀ bẹ́ẹ̀ gbà di ọlọ́rọ̀ àti olókìkí? Ǹjẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ló tọ̀nà? Ǹjẹ́ ọwọ́ wọn mọ̀? Àwọn èèyàn míì sì tún wà tí wọ́n ń forí ṣe fọrùn ṣe nínú ẹ̀sìn wọn. Ṣùgbọ́n, ṣé bí wọ́n ṣe ń fi òótọ́ inú sa gbogbo ipá wọn yìí fi hàn pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni wọ́n ń ṣe?—Róòmù 10:2, 3.
Ẹnì kan lè rò pé ọ̀nà tó tọ́ lòun ń tọ̀, àmọ́ kó jẹ́ pé ńṣe ló ń tan ara ẹ̀ jẹ. Tó bá jẹ́ pé ohun tá a bá kàn ti rò pé ó tọ́ la fi ń ṣèpinnu, ọkàn ara wa la gbára lé yẹn, bẹ́ẹ̀, ọ̀kan àwa ẹ̀dá aláìpé ò lè tọ́ wa sọ́nà torí pé ó ń ṣe àdàkàdekè. (Jeremáyà 17:9) Tí a ò bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, a lè máa rò pé ọ̀nà tí kò tọ́ ni ọ̀nà títọ́. Kí ló wá lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn ní ọ̀nà tó tọ́?
A gbọ́dọ̀ máa fi taratara kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá fẹ́ ní ‘agbára ìwòye tí a ti kọ́ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’ Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ “tipasẹ̀ lílò” kọ́ agbára ìwòye wa, ìyẹn ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Hébérù 5:14) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa jẹ́ kí ohun tó dà bíi pé ó tọ́ mú wa yà kúrò ní ‘ojú ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè.’—Mátíù 7:13, 14.
Ìgbà tí “Ọkàn-Àyà Lè Wà Nínú Ìrora”
Ǹjẹ́ inú wa lè dùn bá ò bá ní ìbàlẹ̀ ọkàn? Ǹjẹ́ ẹ̀rín àti fàájì lè mú kí ohun tó ń bani lọ́kàn jẹ́ fúyẹ́? Ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání kéèyàn tìtorí pé òun ní ẹ̀dùn ọkàn kó wá máa mu ọtí àmujù láti fi pàrònú rẹ́ tàbí kó máa lo oògùn olóró tàbí kó máa ṣe ìṣekúṣe? Rárá o. Ọlọ́gbọ́n ọba Òwe 14: 13a.
náà sọ pé: “Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora.”—Ẹ̀rín lè máà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹnì kan ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ ìyẹn ò ní kí ẹ̀dùn ọkàn náà lọ. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún . . . ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín; ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.” (Oníwàásù 3:1, 4) Àmọ́, bí ẹ̀dùn ọkàn náà ò bá lọ, a gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí i. Kódà a lè wá “ìdarí jíjáfáfá” tó bá pọn dandan, ìyẹn ni pé ká wá ìtọ́sọ́nà àwọn tó lè ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 24:6) b Ẹ̀rín àti fàájì dára láyè tiẹ̀, àmọ́ àwọn ohun míì wà tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣèkìlọ̀ nípa ṣíṣe àwọn eré tí kò bójú mu àti ṣíṣe àṣejù nínú eré ìnàjú, ó ní: “Ẹ̀dùn-ọkàn . . . ni ayọ̀ yíyọ̀ máa ń parí sí.”—Òwe 14:13b.
Báwo Làwọn Aláìṣòótọ́ Àtàwọn Èèyàn Rere Ṣe Lè Ní Ìtẹ́lọ́rùn?
Ọba Ísírẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹni tí ó jẹ́ aláìṣòtítọ́ ní ọkàn-àyà yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ọ̀nà ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ènìyàn rere nínú àwọn ìyọrísí ìbálò rẹ̀.” (Òwe 14:14) Báwo làwọn aláìṣòótọ́ àtàwọn ènìyàn rere ṣe lè ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí wọ́n ń ṣe?
Kò sóhun tó kan ẹni tó bá jẹ́ aláìṣòótọ́ kan jíjíhìn fún Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ṣíṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà kì í ṣe nǹkan pàtàkì lójú irú ẹni bẹ́ẹ̀. (1 Pétérù 4:3-5) Àwọn nǹkan tara tí onítọ̀hún ń kó jọ nìkan ló tẹ́ ẹ lọ́rùn. (Sáàmù 144:11-15a) Àmọ́, ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn ló jẹ ẹni rere lógún. Ó máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run nínu gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ohun tó ń ṣe nítorí pé Jèhófà ni Ọlọ́run rẹ̀, bó sì ṣe ń jọ́sìn Ẹni Gíga Jù Lọ ń fún un ní ayọ̀ tó pọ̀ gan-an.—Sáàmù 144:15b.
Má Ṣe ‘Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Gbogbo Ọ̀rọ̀’
Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tí kò ní ìrírí àtàwọn tí ń fi ọgbọ́n hùwà, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Tẹ́nì kan bá jẹ́ afọgbọ́nhùwà, wọn ò lè tètè rí onítọ̀hún tàn jẹ. Dípò kó máa gba gbogbo ohun táwọn èèyàn bá sọ gbọ́ tàbí kó kàn máa jẹ́ káwọn ẹlòmíràn darí òun, ńṣe ló máa kọ́kọ́ fara balẹ̀ ronú lórí ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé. Bó bá ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀, tó sì ti gbé e yẹ̀ wò dáadáa, ìgbà yẹn ló máa tó pinnu ohun tó yẹ kóun ṣe.
Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ìbéèrè yìí, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run wà?” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń sọ tàbí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn inú ayé lẹni tó bá jẹ́ aláìní ìrírí máa ń gbà gbọ́. Àmọ́ afọgbọ́nhùwà máa ń fara balẹ̀ gbé ohun tó gbọ́ yẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ó jẹ́ òtítọ́. Ó máa ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Róòmù 1:20 àti Hébérù 3:4. Tọ́rọ̀ bá di ti ìjọsìn Ọlọ́run, afọgbọ́nhùwà kì í gba ọ̀rọ̀ àwọn olórí ìsìn gbọ́ láìṣe ìwádìí kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń “dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 4:1.
Á mà dára o ká fiyè sí ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ gbà wá pé ká má ṣe “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀”! Ó yẹ káwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni fi kókó pàtàkì yìí sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ báni wí. Ó yẹ kí ẹni tó ń báni wí mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó sọ̀rọ̀. Ó yẹ kó tẹ́tí sílẹ̀ sí tọ̀tún-tòsì kó sì gbé ọ̀rọ̀ wọn yẹ̀ wò dáadáa kó lè báni wí lọ́nà tó tọ́ kí ìbáwí náà má bàa fì sọ́nà kan.—Òwe 18:13; 29:20.
“Ènìyàn Tí Ó Ní Agbára Láti Ronú Ni A Kórìíra”
Ọba Ísírẹ́lì tún tọ́ka sí ohun mìíràn tó mú káwọn ọlọ́gbọ́n yàtọ̀ sáwọn arìndìn, ó ní: “Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù, ó sì yí padà kúrò nínú ìwà búburú, ṣùgbọ́n arìndìn ń bínú kíkankíkan, ó sì ní ìgbọ́kànlé nínú ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá ń yára bínú yóò hu ìwà òmùgọ̀, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní agbára láti ronú ni a kórìíra.”—Òwe 14:16, 17.
Ọlọ́gbọ́n máa ń bẹ̀rù àwọn ohun tó lè tìdí ìwà àìtọ́ yọ. Ìyẹn ló fi máa ń kíyè sára tó sì máa ń fi ìmoore hàn tí wọ́n bá fún un ní ìmọ̀ràn tó lè ràn án lọ́wọ́ kó má bàa hùwà búburú. Àmọ́ àwọn arìndìn kì í ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀. Wọn kì í gba ìmọ̀ràn ẹlòmíì torí pé wọ́n fọkàn tán ara wọn. Nítorí pé inú tètè máa ń bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wọn máa ń hùwà òmùgọ̀. Àmọ́ o, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń kórìíra ẹni tó bá ní agbára láti ronú?
Nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ìtumọ̀ méjì ni ọ̀rọ̀ tá a tú sí “agbára láti ronú” ní. Àkọ́kọ́, ó túmọ̀ sí ìfòyemọ̀ tàbí làákàyè. (Òwe 1:4; 2:11; 3:21) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún túmọ̀ sí èrò ibi tàbí ìpètepèrò láti ṣeni ní jàǹbá.—Sáàmù 37:7; Òwe 12:2; 24:8.
Bó bá jẹ́ pé ẹni tó ń gbèrò ibi síni ni ọ̀rọ̀ náà “ènìyàn tí ó ní agbára láti ronú” ń tọ́ka sí, yóò rọrùn fún wa láti mọ ìdí táwọn èèyàn fi máa kórìíra irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o ò gbà pé àwọn tí kì í lo agbára ìrònú wọn lè kórìíra ẹni tó bá jẹ́ olóye? Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń kórìíra àwọn tó ń lo làákàyè wọn tí wọn ò sì jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Bákan náà, àwọn èèyàn máa ń pẹ̀gàn àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń lo agbára ìrònú wọn dáadáa tí wọn ò sì jẹ́ káwọn ojúgbà wọn tí wọ́n ń hùwàkiwà sọ wọ́n dà bí wọ́n ṣe dà. Ká sòótọ́, ayé yìí tó wà lábẹ́ agbára Sátánì Èṣù kórìíra àwọn tó ń fi òótọ́ inú jọ́sìn Ọlọ́run.—1 Jòhánù 5:19.
“Àwọn Ènìyàn Búburú Yóò Ní Láti Tẹrí Ba”
Ohun mìíràn ṣì tún wà tó mú káwọn afọgbọ́nhùwà yàtọ̀ sáwọn aláìní ìrírí. “Dájúdájú, aláìní ìrírí yóò fi ìwà òmùgọ̀ ṣe ìní, ṣùgbọ́n àwọn afọgbọ́nhùwà yóò gbé ìmọ̀ rù gẹ́gẹ́ bí ìwérí.” (Òwe 14:18) Ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání làwọn aláìní ìrírí máa ń ṣe torí pé wọn kò ní òye. Ìwà òmùgọ̀ ni wọ́n sì máa ń hù nígbèésí ayé wọn. Àmọ́ tàwọn afọgbọ́nhùwà ò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ńṣe ni ìmọ̀ máa ń ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí adé ṣe máa ń gbé ọba níyì.
Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Àwọn ènìyàn búburú yóò ní láti tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere, àti àwọn ènìyàn burúkú ní àwọn ẹnubodè olódodo.” (Òwe 14:19) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ẹni rere ló máa lékè àwọn ẹni burúkú. Ìwọ wo bí àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i lónìí àti bí ìgbé ayé wọn ti dùn tó. Táwọn alátakò kan bá rí gbogbo ìbùkún tí Jèhófà ń rọ̀jò sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀, wọ́n á “tẹrí ba” fún obìnrin ìṣàpẹẹrẹ ti Jèhófà tó wà lọ́run, èyí táwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ń ṣojú fún. Ó pẹ́ tán nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, àwọn alátakò yìí á gbà pé apá tó wà lọ́run lára ètò Jèhófà ni èyí tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé ń ṣojú fún.—Aísáyà 60:1, 14; Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 16:14, 16.
“Fí Ojú Rere Hàn sí Àwọn Tí Ìṣẹ́ Ń Ṣẹ́”
Sólómọ́nì tún sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó jẹ́ ìwà ọmọ aráyé, ó ní: “Lójú ọmọnìkejì rẹ̀ pàápàá, ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra, ṣùgbọ́n púpọ̀ ni ọ̀rẹ́ ọlọ́rọ̀.” (Òwe 14:20) Bí ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá aláìpé ṣe rí nìyẹn o! Ohun táwọn èèyàn máa rí jẹ ni wọ́n ń wá, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn olọ́rọ̀ ni wọ́n máa ń gbé gẹ̀gẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí kò bá lọ́rọ̀ kò jẹ́ nǹkan kan lójú wọn. Bí àwọn tó ń bá olówó ṣọ̀rẹ́ tiẹ̀ pọ̀, ọ̀rẹ́ wọn kì í pẹ́ lọ títí àní gẹ́gẹ́ bí owó rẹ̀ ṣe lè tán nígbàkigbà. Ṣé ó wá yẹ ká máa lo owó tàbí ọ̀rọ̀ dídùn láti fi mú káwọn èèyàn bá wa ṣọ̀rẹ́?
Tá a bá wo irú ẹni tí àwa fúnra wa jẹ́, tá a sì rí i pé ẹni tó máa ń wá ojú rere àwọn ọlọ́rọ̀ àti ẹni tó máa ń fojú pa àwọn tálákà rẹ́ la jẹ́ ńkọ́? A ní láti rántí pé Bíbélì sọ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò dára. Ó sọ pé: “Ẹni tí ń tẹ́ńbẹ́lú ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n aláyọ̀ ni ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.”—Òwe 14:21.
Ó yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ àwọn tí nǹkan nira fún ro ara wa wò. (Jákọ́bù 1:27) Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Ó yẹ ká fún wọn ní “àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé,” ìyẹn àwọn nǹkan bí owó, oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ, ká sì rí i pé a ò jìnnà sí wọn. (1 Jòhánù 3:17) Aláyọ̀ lẹni tó bá ń fi ojú rere hàn sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, torí pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Báwo Ni Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí fún Àwọn Afọgbọ́nhùwà Àtàwọn Òmùgọ̀?
Bí ìlànà Bíbélì tó sọ pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú” ṣe kan àwọn afọgbọ́nhùwà náà ló kan àwọn òmùgọ̀. (Gálátíà 6:7) Ohun tó dára ni ọlọ́gbọ́n ń ṣe àmọ́ elétekéte ni òmùgọ̀ èèyàn. Ọlọ́gbọ́n ọba náà béèrè pé: “Àwọn tí ń hùmọ̀ ibi kì yóò ha máa rìn gbéregbère?” Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé wọ́n ti ṣìnà. “Ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ ń bẹ ní ti àwọn tí ń hùmọ̀ ohun rere.” (Òwe 14:22) Àwọn èèyàn máa ń ran àwọn ẹni rere lọ́wọ́, Ọlọ́run sì máa ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí wọn.
Sólómọ́nì tún sọ ọ̀rọ̀ kan láti fi hàn pé ẹni tó bá ń ṣe iṣẹ́ àṣekára yóò ní láárí àti pé èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí tó bá kàn ń pariwo ẹnu lásán láìtẹpá mọ́ṣẹ́. Ó sọ pé: “Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè lásán-làsàn máa ń tẹ̀ sí àìní.” (Òwe 14:23) Láìsí àní-àní, ìlànà yìí kan àwọn ìgbòkègbodò wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá ń sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ ìwàásù, a ó rí ìbùkún tó wà nínú fífi ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń gbani là kọ́ àwọn èèyàn. Tá a bá sì ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yẹ ní ṣíṣe nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, a óò ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
Ìwé Òwe 14:24 sọ pé: “Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn; ìwà òmùgọ̀ àwọn arìndìn jẹ́ ìwà òmùgọ̀.” Èyí lè túmọ̀ sí pé ọgbọ́n táwọn ọlọ́gbọ́n ń sapá láti ní ni ọrọ̀ wọn, ó sì dà bí adé fún wọn, tàbí ká sọ pé ó ń ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́. Àmọ́ ní tàwọn òmùgọ̀, ńṣe ni ìwà òmùgọ̀ wọn ń peléke sí i. Ìwé kan sọ pé, òwe yìí tún lè túmọ̀ sí pé “ohun ọ̀ṣọ́ ni ọrọ̀ jẹ́ fáwọn tó máa lò ó dáadáa . . . [àmọ́] ìwà òmùgọ̀ làwọn òmùgọ̀ kàn ń hù ṣáá.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, nǹkan máa ń lọ déédéé fún àwọn ọlọ́gbọ́n ju àwọn òmùgọ̀ lọ.
Ọba Ísírẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń dá àwọn ọkàn nídè, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ ẹlẹ́tàn ń gbé irọ́ pátápátá yọ.” (Òwe 14:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbẹ́jọ́, wo bí kókó yìí ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù wa ná. A ní láti jẹ́rìí sí òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá a ṣe ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ìjẹ́rìí yìí ń dá àwọn olóòótọ́ ọkàn nídè kúrò nínú ẹ̀sìn èké, ó sì ń gba ẹ̀mí là. Tá a bá ń fiyè sí ara wa àti sí ẹ̀kọ́ wa nígbà gbogbo, a ó gba ara wa àtàwọn tí ń fetí sí wa là. (1 Tímótì 4:16) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí láìkáàárẹ̀, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a jẹ́ afọgbọ́nhùwà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ka àlàyé tá a ṣe lórí ìwé Òwe 14:1-11, wo Ilé Ìṣọ́ November 15, 2004, ojú ìwé 26 sí 30.
b Wo Jí! April 22, 1988, ojú ìwé 11 sí 16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A gbọ́dọ̀ máa fi taratara kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ tá a bá fẹ́ mọ bá a ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ kíkó ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ lè jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn lóòótọ́?