Àkọsílẹ̀ Mátíù 7:1-29

 • ÌWÀÁSÙ ORÍ ÒKÈ (1-27)

  • Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́ (1-6)

  • Ẹ máa béèrè, ẹ máa wá kiri, ẹ máa kan ilẹ̀kùn (7-11)

  • Òfin Oníwúrà (12)

  • Ẹnubodè tóóró (13, 14)

  • Àwọn èso wọn la máa fi mọ̀ wọ́n (15-23)

  • Ilé orí àpáta, ilé orí iyanrìn (24-27)

 • Bí Jésù ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò lẹ́nu (28, 29)

7  “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́,+ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́;  torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́,+ òṣùwọ̀n tí ẹ sì fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n fún yín.+  Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ?+  Àbí báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé, wò ó! igi ìrólé wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?  Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.  “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀,+ kí wọ́n má bàa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kí wọ́n wá yíjú pa dà, kí wọ́n sì fà yín ya.  “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín;+ ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín;+  torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà,+ gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún.  Ní tòótọ́, èwo nínú yín ló jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè búrẹ́dì, ó máa fún un ní òkúta? 10  Tó bá sì béèrè ẹja, kò ní fún un ní ejò, àbí ó máa fún un? 11  Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ohun tó dáa+ ló máa fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!+ 12  “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.+ Ní tòótọ́, ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí nìyí.+ 13  “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé,+ torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀; 14  nígbà tó jẹ́ pé, ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.+ 15  “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké+ tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn,+ àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú.+ 16  Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀. Àwọn èèyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún, wọn kì í sì í kó ọ̀pọ̀tọ́ jọ láti ara òṣùṣú, àbí wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?+ 17  Bákan náà, gbogbo igi rere máa ń so èso rere, àmọ́ gbogbo igi tó ti jẹrà máa ń so èso tí kò ní láárí.+ 18  Igi rere ò lè so èso tí kò ní láárí, igi tó ti jẹrà ò sì lè so èso rere.+ 19  Gbogbo igi tí kò bá so èso rere la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.+ 20  Torí náà, ní tòótọ́, èso àwọn èèyàn yẹn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.+ 21  “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́.+ 22  Ọ̀pọ̀ máa sọ fún mi ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Olúwa, Olúwa,+ ṣebí a fi orúkọ rẹ sọ tẹ́lẹ̀, a fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì fi orúkọ rẹ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára?’+ 23  Àmọ́, màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’+ 24  “Torí náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tó sì ṣe é máa dà bí ọkùnrin kan tó ní òye, tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.+ 25  Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò wó, torí pé orí àpáta ni ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà. 26  Bákan náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò sì ṣe é máa dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn.+ 27  Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà,+ àmọ́ kò lè dúró, ńṣe ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” 28  Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu,+ 29  torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ,+ kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé