Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Jèhófà Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Jèhófà Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

“Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—SÁÀMÙ 145:17.

1. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ bí ẹnì kan bá sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa rẹ, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

 ǸJẸ́ ẹnì kan ti sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa rẹ rí, bóyá ó tiẹ̀ dá ọ lẹ́bi pé ohun tó o ṣe ò dára láìmọ ohun tó mú ọ ṣe nǹkan náà? Bó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí, ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà á dùn ọ́ gan-an, kò sì sẹ́ni tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní dùn. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nínú ohun tá a sọ yìí. Ẹ̀kọ́ náà ni pé, kò dára ká máa yára dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ nígbà tá ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀.

2, 3. Kí lèrò àwọn kan nípa àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì tí kò ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tá a fi lè rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè, síbẹ̀ kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa Jèhófà?

2 Ó yẹ ká máa fi kókó yìí sọ́kàn nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn àkọsílẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó lè máà kọ́kọ́ yé wa. Àwọn àkọsílẹ̀ náà, bóyá nípa nǹkan táwọn ìrànṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣe tàbí àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe láyé àtijọ́, lè máà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tá a fi lè rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè wa. Ó dunni pé àwọn kan máa ń ṣàríwísí irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n tiẹ̀ máa ń ṣiyèméjì bóyá Ọlọ́run máa ń ṣẹ̀tọ́ àti òdodo. Síbẹ̀, Bíbélì sọ fún wa pé “olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 145:17) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run “kì í ṣe burúkú.” (Jóòbù 34:12; Sáàmù 37:28) Wá wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá ń sọ ohun tí ò jóòótọ́ nípa rẹ̀!

3 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí márùn-ún tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe. Ẹ sì jẹ́ ká fi wọ́n sọ́kàn bí a óò ṣe máa gbé àwọn ìtàn méjì tó máa ń rú àwọn kan lójú nínú Bíbélì yẹ̀ wò.

Àwọn Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Fára Mọ́ Àwọn Ìdájọ́ Tí Jèhófà Ṣe

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe? Ṣàpèjúwe.

4 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, Jèhófà mọ gbogbo ohun tó wé mọ́ ìdájọ́ tó bá ṣe, àwa ò sì mọ̀ ọ́n. Nítorí náà, ó yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe. Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé adájọ kan dá ẹjọ́ kan ní kóòtù, tó sì jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló mọ adájọ́ yìí bí ẹni mowó pé kì í ṣe ojúsàájú nínú àwọn ẹjọ́ tó ti dá sẹ́yìn. Irú ojú wo ni wàá fi wo ẹnì kan tí kò mọ gbogbo ohun tó wà nídìí ẹjọ́ náà tàbí tí kò mọ àwọn òfin tó so mọ́ ẹjọ́ náà ṣùgbọ́n tó ń sọ pé bí adájọ́ náà ṣe dá ẹjọ́ ọ̀hún kò dára? Ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ tí ẹnì kan bá ń ṣàríwísí ọ̀ràn kan láìmọ̀ gbogbo ohun tó wà nídìí ọ̀ràn náà. (Òwe 18:13) Bí ẹ̀dá èèyàn lásálàsàn bá wá ń sọ pé ohun tí “onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” ṣe kò dára, ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ kan ò jùyẹn lọ!—Jẹ́nẹ́sísì 18:25.

5. Kí la ò gbọ́dọ̀ gbàgbé nígbà tá a bá ń kà nípa ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fáwọn èèyàn kan nínú Bíbélì?

5 Ìdí kejì tó fi yẹ ká fára mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe ni pé Ọlọ́run kò dà bí èèyàn, ó mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kọ̀ọ̀kan. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín, àní láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” (Jeremáyà 17:10) Nítorí náà, nígbà tá a bá ń kà nípa àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé kò sóhun tó pa mọ́ fún Ọlọ́run. Ó mọ èrò ọkàn èèyàn àtàwọn ohun tó mú ẹnì kan hu ìwà tó hù, èyí tí a lè máà rí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sì jẹ́ pé ohun tó gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà nìyẹn.—1 Kíróníkà 28:9.

6, 7. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun máa ń dúró lórí àwọn ìlànà òun tó bá òdodo mu tó sì tọ̀nà, kódà bí yóò tilẹ̀ ná òun ní ohun tó ṣeyebíye? (b) Kí lo yẹ ká máa rántí tá a bá ka nǹkan kan nínú Bíbélì tó ń mú wa ṣiyèméjì bóyá ohun tí Ọlọ́run ṣe tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà?

6 Kíyè sí ìdí kẹta tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe: Ó máa ń dúró lórí àwọn ìlànà rẹ̀ tó jẹ́ òdodo, kódà bí yóò tíẹ̀ ná an ní ohun tó ṣeyebíye. Wo àpẹẹrẹ kan. Nígbà tí Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ ṣe ìràpadà káwọn onígbọràn èèyàn lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ó fi hàn pé òun máa ń dúró lórí àwọn ìlànà òun tó bá òdodo mu tó sì tọ̀nà. (Róòmù 5:18, 19) Síbẹ̀, bí Jèhófà ti ń wo Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó ń jẹ̀rora tó sì kú lórí òpò igi oró ti ní láti mú ọkàn Jèhófà gbọgbẹ́ gidigidi. Kí lèyí sọ fún wa nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “ìràpadà tí Kristi Jésù san,” ó ní: “Èyí jẹ́ láti fi òdodo [Ọlọ́run] hàn.” (Róòmù 3:24-26) Bíbélì mìíràn lédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n pè ní New Century Version túmọ̀ Róòmù 3:25 lọ́nà yìí pé: “Èyí fi hàn pé ohun tó tọ́nà tó sì bójú mu ni Ọlọ́run ń ṣe nígbà gbogbo.” Ká sòótọ́, bí Jèhófà ṣe ṣe ohun ńlá yìí, tó pèsè ìràpadà fún wa fi hàn pé ó ka ṣíṣe “ohun tó tọ̀nà tó sì bójú mu” sí ju ohunkóhun lọ.

7 Nítorí náà, tá a bá ka nǹkan kan nínú Bíbélì tó mú káwọn kan máa ṣiyèméjì bóyá ohun tí Ọlọ́run ṣe tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, kókó kan rèé tó yẹ ká fi sọ́kàn: Nítorí pé Jèhófà máa ń dúró lórí àwọn ìlànà rẹ̀ tó jẹ́ òdodo, kò yọ Ọmọ tirẹ̀ pàápàá nínú ìrora tó yọrí sí ikú. Ṣé kò wá ní tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn? Òótọ́ kan tó dájú ni pé, Jèhófà ṣe ohun tó ta ko àwọn ìlànà rẹ̀ tó jẹ́ òdodo . Ó yẹ kí èyí mú un dá wa lójú pé ohun tó dára ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà gbogbo.—Jóòbù 37:23.

8. Kí nìdí tí kò fi ní bójú mu kí ẹ̀dá èèyàn máa rò pé Jèhófà kì í ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu nínú àwọn ohun kan?

8 Ìdí kẹrin tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe ni pé: Jèhófà dá èèyàn ní àwòrán ara Rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìdí nìyẹn táwa èèyàn fi ní irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, lára rẹ̀ sì ni pé a mọ ohun tó tọ́. Ẹ ò rí i pé kò ní bójú mu rárá bó bá jẹ́ pé òye tí Jèhófà fún wa láti mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ yìí ló tún wá ń mú ká máa rò pé Jèhófà fúnra rẹ̀ kò ní àwọn ànímọ́ yẹn láwọn ọ̀nà kan. Bí a bá ka nǹkan kan nínú Bíbélì tó rú wa lójú, ó yẹ ká rántí pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún kò jẹ́ ká ní òye tó kún mọ́ nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Jèhófà Ọlọ́run tó dá wa ní àwòràn ara rẹ̀, kò kù síbì kan nínú ṣíṣe ìdájọ́ òdodo àti ṣíṣe ohun tó tọ́. (Diutarónómì 32:4) Kò tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí rárá pé ẹ̀dá èèyàn lè máa rò pé àwọn lè jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ!—Róòmù 3:4, 5; 9:14.

9, 10. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi ní láti máa ṣàlàyé fún ẹ̀dá èèyàn ìdí tó fi ṣe àwọn ohun tó ṣe tàbí kó máa sọ ìdí tí ohun tó ṣe fi dára?

9 Ìdí karùn-ún tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ Jèhófà ni pé, òun ni “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Nítorí náà, kò sídìí tó fi yẹ kó máa ṣàlàyé fún èèyàn ìdí tó fi ṣe àwọn ohun tó ṣe tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ìdí tí ohun tó ṣe fi dára. Òun ni Amọ̀kòkò tí kò lẹ́gbẹ́, bí amọ̀ làwa ẹ̀dá èèyàn rí lọ́wọ́ rẹ̀, ó lè ṣe sí wa bó bá ṣe tọ́ lójú rẹ̀. (Róòmù 9:19-21) Kí la jẹ́, tí a óò fi máa bi Ọlọ́run léèrè pé kí ló mú un ṣe àwọn ohun tó ṣe, àwa tó jẹ́ pé amọ̀ lásánlàsàn ni wá lọ́wọ́ rẹ̀? Nígbà tí ọnà tí Ọlọ́run gbà bá aráyé lò kò yé baba ńlá náà, Jóòbù, Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà. Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò ha sọ ìdájọ́ òdodo mi di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀? Ìwọ yóò ha pè mí ní ẹni burúkú, kí o bàa lè jàre?” Nígbà tí Jóòbù rí i pé ọ̀rọ̀ tí òun sọ kò bọ́gbọ́n mu, ó ronú pìwà dà. (Jóòbù 40:8; 42:6) Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra, ká má ṣe sọ pé Ọlọ́run ń ṣe ohun tí kò dára!

10 Ní báyìí, a ti rí àwọn ìdí tó yè kooro tó fi yẹ ká gbà pé ohun tó dára ni Jèhófà ń ṣe nígbà gbogbo. Bá a ṣe wá ní àwọn kókó yìí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká gbé ìtàn méjì tó máa ń rú àwọn kan lójú nínú Bíbélì yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ jẹ́ nípa ohun tí ìrànṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣe, èkejì sì jẹ́ nípa ìdájọ́ kan tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe.

Kí Nìdí Tí Lọ́ọ̀ti Fi Yọ̀ọ̀da Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Fáwọn Èèyànkéyàn?

11, 12. (a) Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì méjì lọ sí Sódómù. (b) Àwọn ìbéèrè wo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti gbé sí àwọn kan lọ́kàn?

11 Ìtàn kan wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 19 tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe rán àwọn áńgẹ́lì méjì lọ sí ìlú Sódómù. Lọ́ọ̀tì sọ fáwọn áńgẹ́lì tó dé bá a làlejò yìí pé ilé òun ni wọ́n máa sùn. Àmọ́ nígbà tó dòru, àwọn èèyànkéyàn kan látinú ìlú náà yí ilé Lọ́ọ̀tì ká, wọ́n ní kó mú àwọn àlejò náà jáde káwọn lè bá wọn ṣèṣèkúṣe. Lọ́ọ̀tì pàrọwà fún wọn, àmọ́ ẹ̀yìn etí wọn ni gbogbo àrọwà náà bọ́ sí. Tórí kí Lọ́ọ̀tì lè dáàbò bo àwọn àlejò rẹ̀, ó sọ fáwọn èèyànkéèyàn náà pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ má ṣe hùwà búburú. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i, àwọn ọmọbìnrin méjì ni mo ní tí wọn kò tíì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde fún yín. Nígbà náà kí ẹ ṣe sí wọn bí ó bá ti dára ní ojú yín. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí nìkan ni kí ẹ má ṣe ohunkóhun sí, ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi wá sábẹ́ òjìji òrùlé mi.” Àmọ́ àwọn èèyàn yìí ò tiẹ̀ dá Lọ́tì lóhùn, díẹ̀ ló sì kù kí wọ́n fọ́ ilẹ̀kùn ilé rẹ̀. Làwọn áńgẹ́lì tí Lọ́ọ̀tì gbà lálejò náà bá bu ìfọ́jú lu àwọn olórí gbígbóná èèyàn náà.—Jẹ́nẹ́sísì 19:1-11.

12 Ìtàn yìí ti mú kí àwọn kan béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Wọ́n rò ó pé: ‘Kí nìdí tí Lọ́ọ̀tì á fi yọ̀ọ̀da àwọn ọmọ rẹ̀ fáwọn tí ìṣekuṣe ti yí lórí yẹn torí pé ó fẹ́ dáàbò bo àwọn àlejò rẹ̀? Ṣé ohun tó ṣe yẹn bójú mu? Ṣé kì í ṣe ìwà ojo ló hù yẹn?’ Tá a bá wo ohun tó ṣe yìí, kí nìdí tí Ọlọ́run á fi mí sí Pétérù láti pe Lọ́ọ̀tì ní “olódodo”? Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí ohun tí Lọ́ọ̀tì ṣe ni? (2 Pétérù 2:7, 8) Ẹ jẹ́ ká jọ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò ká má bàa sọ ohun tí kò yẹ.

13, 14. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tí Lọ́ọ̀tì ṣe? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Lọ́ọ̀tì kò ṣojo?

13 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé, Bíbélì kò sọ pé ohun tí Lọ́ọ̀tì ṣe dára tàbí kò dára, ńṣe ló kàn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Bákan náà ni Bíbélì kò sọ ohun tí Lọ́ọ̀tì ń rò lọ́kàn fún wa tàbí ohun tó mú un ṣe nǹkan tó ṣe yẹn. Nígbà tó bá jíǹde nígbà “àjíǹde àwọn olódodo,” ó ṣeé ṣe kó ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀—Ìṣe 24:15.

14 Lọ́ọ̀tì kì í ṣe ojo èèyàn rárá. Ohun tó dé bá a yẹn kúrò ní kékeré. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì sọ pé àwọn alèjò náà “wá sábẹ́ òjìji òrùlé” òun, ohun tó ń sọ ni pé ó ti di dandan kóun dáàbò bò wọ́n kí ohunkóhun má ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́ èyí kò rọrùn fún un. Òpìtàn kan tó jẹ́ Júù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus sọ pé, àwọn ará Sódómù “kì í hùwà tó dáa sáwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bẹ̀rù Ọlọ́run . . . Wọ́n kórìíra àjèjì, wọ́n sì máa ń bá ara wọn ṣèṣekúṣe lọ́nà tó burú jáì.” Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo èyí náà, Lọ́ọ̀tì kò bẹ̀rù àwọn èèyànkéèyàn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jáde síta lọ bá àwọn ọkùnrin tínú ń bí náà ó sì pàrọwà fún wọn. Kódà ó “ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn tí ó jáde” síta.—Jẹ́nẹ́sísì 19:6.

15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbàgbọ́ tí Lọ́ọ̀tì ní ló mú kó ṣe ohun tó ṣe?

15 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Kí nìdí tí Lọ́ọ̀tì fi lè yọ̀ọ̀da àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fáwọn èèyànkéèyàn yẹn?’ Dípò tí wàá fi máa sọ pé ohun tí Lọ́ọ̀tì ṣe ò dáa, o ò ṣe ronú nípa àwọn nǹkan tó lè fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbàgbọ́ tí Lọ́ọ̀tì ní ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Lọ́ọ̀tì kò ṣàìmọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe kó Sárà yọ, ìyẹn ìyàwó Ábúráhámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Lọ́ọ̀tì. Rántí pé nítorí ẹwà tí Sárà ní, Ábúráhámù sọ fún un pé kó pe òun ní ẹ̀gbọ́n rẹ̀ káwọn èèyàn má bàa pa òun nítorí àtifẹ́ Sárà. a Ẹ̀yìn náà ni wọ́n wá mú Sárà lọ sílé Fáráò. Àmọ́ Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò jẹ́ kí Fáráò bá Sárà ṣèṣekúṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 12:11-20) Nítorí náà ó ṣeé ṣe kí Lọ́ọ̀tì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run á dáàbò bo àwọn ọmọ òun bó ṣe dáàbò bo Sárà. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn, Jèhófà lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, ó dá sí ọ̀rọ̀ náà, àwọn èèyànkéèyàn náà ò sì fọwọ́ kan àwọn ọmọbìnrin náà.

16, 17. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Lọ́ọ̀tì fẹ́ da nǹkan rú mọ́ àwọn èèyàn Sódómù lójú? (b) Ohun yòówù tí Lọ́ọ̀tì ì báà ní lọ́kàn, kí ló yẹ kó dá wa lójú?

16 Tún wo ohun mìíràn tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Lọ́ọ̀tì fẹ́ da nǹkan rú mọ́ àwọn aráabí yẹn lójú. Ó ṣeé ṣe kó ní in lọ́kàn pé àwọn èèyànkéèyàn náà ò ní nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọmọbìnrin òun nítorí ìwà ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ tó ti gbé àwọn ará Sódómù wọ̀ bí ẹ̀wù. (Júúdà 7) Kókó mìíràn tún ni pé, àwọn ọmọbìnrin náà ti lẹ́ni tí wọ́n fẹ́ fẹ́ nílùú náà, torí náà, ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, tàbí alábàáṣiṣẹ́ àwọn ọkùnrin tó fẹ́ fẹ́ wọn yìí wà lára àwọn èèyànkéèyàn náà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:14) Lọ́ọ̀tì lè rò pé èyí lè mú káwọn kan lára wọn sọ pé káwọn yòókù má ṣe fọwọ́ kan àwọn ọmọbìnrin náà. Bí ìmọ̀ àwọn èèyàn náà ò bá sì ṣọ̀kan, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má ṣe àwọn ọmọ náà ní jàǹbá. b

17 Ohun yòówù tí Lọ́ọ̀tì ì báà ní lọ́kàn tó fi ṣe ohun tó ṣe yẹn, ohun kan rèé tó yẹ kó dá wa lójú: Ìyẹn ni pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó tọ̀nà ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà gbogbo, ó ní láti ní ìdí pàtàkì tó fi ka Lọ́ọ̀tì sí “olódodo.” Tá a bá sì wo ìwà asínwí táwọn ará Sódómù máa ń hù, ǹjẹ́ a lè máa ṣiyèméjì pé ohun tí Jèhófà ṣe kò tọ̀nà bó ṣe pa àwọn èèyàn ìlú burúkú yẹn run?—Jẹ́nẹsísì 19:23-25.

Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Lu Úsà Pa?

18. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì fẹ́ gbé Àpótí Ẹ̀rí wá sí Jerúsálẹ́mù? (b) Kí ni ìbéèrè tí ìtàn yìí lè gbé sáwọn kan lọ́kàn?

18 Ìtàn mìíràn tó lè máa rú àwọn kan lójú ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì fẹ́ dá àpótí májẹ̀mú padà sí Jerúsálẹ́mù. Orí kẹ̀kẹ́ tí màlúù ń fà ni wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí náà lé, Úsà àti arákùnrin rẹ̀ sì ń lọ níwájú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ń bọ̀ títí dé ilẹ̀ ìpakà Nákónì, Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde wàyí sí àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì gbá a mú, nítorí tí màlúù náà fẹ́rẹ̀ẹ́ fa ìdojúdé. Látàrí ìyẹn, ìbínú Jèhófà ru sí Úsà, Ọlọ́run tòótọ́ sì ṣá a balẹ̀ níbẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ náà, tí ó fi kú níbẹ̀ nítòsí àpótí Ọlọ́run tòótọ́.” Nígbà tí wọ́n tún gbìyànjú láti gbé Àpótí Ẹ̀rí náà lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, tí wọ́n sì gbé e lọ́nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, ìyẹn nípa jíjẹ́ kí àwọn ọmọ Kóhátì tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì gbé e sorí èjìká wọn, aburú kankan ò ṣẹlẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 6:6, 7; Númérì 4:15; 7:9; 1 Kíróníkà 15:1-14) Àwọn kan lè máa béèrè pé: ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ní láti bínú tó bẹ́ẹ̀ yẹn? Ṣebí Úsà kàn ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí Àpótí Ẹ̀rí náà ṣubú ni.’ Yóò dára ká gbé àwọn kókó kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ yẹ̀ wò ká má bàa sọ ohun tí kò tọ́.

19. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi lè ṣe ohun tí kò tọ́ láéláé?

19 Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kò jẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́. (Jóòbù 34:10) Bó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé kò nífẹ̀ẹ́ nìyẹn. Látinú ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin, a mọ̀ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ìyẹn nìkan kọ́, Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ [Ọlọ́run].” (Sáàmù 89:14) Báwo ni Jèhófà á ṣe wá ṣe ohun tí kò tọ́? Bó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa sọ jíjẹ́ tó jẹ́ ọba aláṣẹ láye àti lọ́run di ohun yẹpẹrẹ.

20. Àwọn ìdí wo ló fi yẹ kí Úsà mọ̀ nípa àwọn òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa Àpótí Ẹ̀rí náà?

20 Má ṣe gbàgbé pé ó yẹ kí Úsà mọ̀ pé ohun tí òun fẹ́ ṣe yẹn kò tọ́. Àmì pé Jèhófà wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Àpótí Ẹ̀rí náà jẹ́. Òfin Mósè dìídì sọ pé ẹni tí kò bá lẹ́tọ̀ọ́ láti fọwọ́ kan àpótí náà kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, Òfin náà sì kìlọ̀ pé ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò kú. (Númérì 4:18-20; 7:89) Nítorí náà, gbígbé àpótí mímọ́ yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń fọwọ́ kékeré mú. Úsà ti ní láti mọ ohun tí Òfin náà sọ dáadáa nítorí pé ọmọ Léfì ni (bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe àlùfáà). Yàtọ̀ síyẹn, ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó wáyé, wọ́n wá gbé Àpótí náà pa mọ́ sílé bàbá Úsà. (1 Sámúẹ́lì 6:20–7:1) Àpótí yìí sì ti lo àádọ́rin ọdún níbẹ̀ kó tó di pé Dáfídì sọ pé òun fẹ́ gbé e kúrò. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti kékeré gan-an ni Úsà ti mọ àwọn òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa Àpótí Ẹ̀rí náà.

21. Látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úsà, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa rántí pé Jèhófà máa ń rí ohun tó wà nínú ọkàn?

21 Bí a ṣe sọ níṣàájú, Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ìwà àìlọ́wọ̀” ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe ohun tí Úsà ṣe yìí, Jèhófà lè ti rí i pé ìwà ‘àwa-la-wà-ńbẹ̀’ ni Úsà hù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ náà kò dìídì mẹ́nu kan èyí. Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀yájú èèyàn ni Úsà, tó máa ń kọjá ayè rẹ̀? (Òwe 11:2) Ṣé bó ṣe ń lọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí tí wọ́n ti gbé pa mọ́ sílé wọn yìí lè mú kó máa ka ara rẹ̀ sẹ́ni pàtàkì? (Òwe 8:13) Ṣé ó lè jẹ́ pé Úsà ò nígbàgbọ́ rárá ni, débi tó fi ń rò pé ọwọ́ Jèhófà kúrú, pé kò lè ṣe é kí àpótí mímọ́ tó dúró fún wíwà níbẹ̀ Rẹ̀ má ṣubú? Ohun yòówù kó jẹ́, ó yẹ kó dá wa lójú pé ohun tó tọ̀nà ni Jèhófà ṣe. Ó ti ní láti rí nǹkan kan nínú ọkàn Úsà tó mú kó ṣe ìdájọ́ ojú ẹsẹ̀ fún un.—Òwe 21:2.

Kókó Patàkì Kan Tó Lè Mú Ká Fọkàn Tán Jèhófà

22. Báwo ni ọgbọ́n Jèhófà ṣe hàn nínú bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ṣe ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kan kínníkínní?

22 A rí ọgbọ́n Jèhófà tí kò láfiwé nínú bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ṣe ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kan kínníkínní. Jèhófà tipá bẹ́ẹ̀ fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a fọkàn tán òun. Látinú àwọn kókó tá a ti gbé yẹ̀ wò, ǹjẹ́ kò hàn sí wa kedere pé ọ̀pọ̀ ìdí ló fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe? Ká sòótọ́, bá a bá fi òótọ́ inú kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìsí ẹ̀tànú kankan lọ́kàn wa, ohun tá a máa mọ̀ nípa Jèhófà á pọ̀ débi tí yóò fi dá wa lójú pé ohun tó tọ́ tó sì bójú mu ló ń ṣe nígbà gbogbo. Nítorí náà, bí àwọn ohun kan nínú Bíbélì bá ń gbé àwọn ìbéèrè kan wá sọ́kàn wa tá ò sì tètè rí ìdáhùn tó ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká fi gbogbo ọkàn tán Jèhófà pé ohun tó tọ́ ló ṣe nípa ohun tá a kà náà.

23. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà nípa àwọn ohun tó ṣì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

23 A tún lè fọkàn tán Jèhófà nínú àwọn nǹkan tó ṣì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé nígbà tí ìdájọ́ rẹ̀ bá dé lákòókò ìpọ́njú ńlá tó sún mọ́lé yìí, kò ní “gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:23) Ìdí tí kò fi ní ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti àìṣègbè. A tún lè fọkàn tán Jèhófà pátápátá pé nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, gbogbo ohun tá a nílò pátá ló máa ṣe fún wa lọ́nà tó dára jù lọ lójú rẹ̀.—Sáàmù 145:16.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó yẹ kí Ábúráhámù bẹ̀rù lóòótọ́. Ìwé ayé ọjọ́un kan sọ nípa ọba Fáráò kan tó ní káwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra lọ mú arẹwà obìnrin kan wá kí wọ́n sì pa ọkọ rẹ̀.

b Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun mìíràn tó ṣeé ṣe kó mú Lọ́ọ̀tì ṣe ohun tó ṣe yìí, wo Ile-Iṣọ Na June 1, 1980, ojú ìwé 30.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí làwọn ìdí tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe?

• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe sọ ohun tí kò tọ́ nípa bí Lọ́ọ̀tì ṣe yọ̀ọ̀da àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fáwọn èèyànkéèyàn yẹn?

• Àwọn kókó wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí Jèhófà fi lu Úsà pa?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà nípa àwọn ohun tó ṣì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]