Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Ń wá ‘Péálì Olówó Iyebíye’ Lónìí

Àwọn Èèyàn Ń wá ‘Péálì Olówó Iyebíye’ Lónìí

Àwọn Èèyàn Ń wá ‘Péálì Olówó Iyebíye’ Lónìí

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí.”—MÁTÍÙ 24:14.

1, 2. (a) Kí ni àwọn Júù tó wà nígbà ayé Jésù rò nípa Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí ní Jésù ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn lóye tó kún rẹ́rẹ́ nípa Ìjọba náà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

 Ọ̀RỌ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló gbòde kan láàárín àwọn Júù nígbà tí Jésù wà láyé. (Mátíù 3:1, 2; 4:23-25; Jòhánù 1:49) Àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni ò kọ́kọ́ mọ ibi tí ìṣàkóso rẹ̀ máa gbòòrò dé, wọn ò sì mọ bí agbára rẹ̀ ṣe máa tó. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọn ò mọ̀ pé ìjọba ti ọ̀run ló máa jẹ́. (Jòhánù 3:1-5) Kódà àwọn kan lára àwọn tó wá di ọmọlẹ́yìn Jésù ò lòye ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, wọn ò sì mọ ohun táwọn máa ṣe láti wà lára àwọn tó máa bá Kristi ṣàkóso.—Mátíù 20:20-22; Lúùkù 19:11; Ìṣe 1:6.

2 Bí àkókò ti ń lọ, Jésù fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́, títí kan àpèjúwe péálì olówó iyebíye tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ́ tó ṣáájú. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ní láti sapá gidigidi kí wọ́n tó lè wọ Ìjọba ọ̀run. (Mátíù 6:33; 13:45, 46; Lúùkù 13:23, 24) Èyí ti ní láti wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an nítorí kò pẹ́ sí àkókò yẹn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà polongo ìhìn rere Ìjọba náà títí dé àwọn apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé. Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìròyìn nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn wà nínú ìwé Ìṣe àwọn Àpọ́sítélì.—Ìṣe 1:8; Kólósè 1:23.

3. Kí ni Jésù sọ nípa Ìjọba náà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tiwa yìí?

3 Báwo ni nǹkan ṣe wá rí lónìí? Àwọn ìbùkún Párádísè òrí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba náà là ń wàásù rẹ̀ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì tí Jésù sọ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó sọ ní pàtó pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:3, 14; Máàkù 13:10) Ó tún ṣàlàyé fún wọn pé wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí láìfi ọ̀pọ̀ ìdènà àti ìṣòro tí wọ́n máa dojú kọ pè, títí kan inúnibíni táwọn èèyàn máa ṣe sí wọn. Síbẹ̀, ó mú un dá wọn lójú pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:9-13) Gbogbo èyí ló máa gba pé kéèyàn ní irú ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni àti ìfọkànsìn tí oníṣòwò arìnrìn-àjò inú àkàwé Jésù ní. Ǹjẹ́ a rí àwọn tó ń fi irú ìgbàgbọ́ àti ìtara bẹ́ẹ̀ wá Ìjọba náà lónìí?

Ayọ̀ Téèyàn Ń Ní Nígbà Tó Bá Rí Òtítọ́

4. Ipa wo ni òtítọ́ Ìjọba náà ń ní lórí àwọn èèyàn lónìí?

4 Inú oníṣòwò tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àkàwé rẹ̀ yẹn dùn gan-an nígbà tó rí ohun tó gbà pé ó jẹ́ “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga.” Ayọ̀ náà ló jẹ́ kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí i pé péálì náà tẹ òun lọ́wọ́. (Hébérù 12:1) Bákan náà ni òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ ṣe ń fa àwọn èèyàn mọ́ra lónìí tó sì ń mú wọn ṣe ohun tó tọ́. Èyí mú wa rántí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin A. H. Macmillan sọ. Arákùnrin yìí kọ nípa bí òun fúnra òun ṣe wá Ọlọ́run tóun sì tún fẹ́ mọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ó kọ ọ́ sínú ìwé tó pè ní Faith on the March (Ìgbàgbọ́ Ń Tẹ̀ Síwájú). Ó ní: “Ohun tí mo ti rí ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ṣì ń wá kiri lọ́dọọdún. Èèyàn bí èmi àti ìwọ sì làwọn náà, nítorí pé inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ni wọ́n ti wá. Onírúurú èèyàn ni wọ́n, ọmọdé wà níbẹ̀, àgbà sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Òtítọ́ kì í ṣe ojúsàájú. Kò sẹ́ni tí ò lè fà mọ́ra.”

5. Àbájáde tó wúni lórí wo la rí nínú ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004?

5 A ti rí i pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn, nítorí pé ọdọọdún ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọlọ́kàn tútù èèyàn ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bí nǹkan ṣe rí ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004 gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ọdún iṣẹ́ ìsìn náà bẹ̀rẹ̀ láti September 2003 sí August 2004. Láàárín oṣù méjìlá yẹn, àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé méjìlélọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìndínlógún [262,416] èèyàn ló fi ẹ̀rí hàn pé àwọn tí ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Èyí sì wáyé ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè, níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́rùn-ún, ọgọ́rùn-ún mẹ́tà àti mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [6,085,387] lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè fi òtítọ́ tí ń fúnni ní ìyè látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ onírúurú èèyàn tó wá látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra.—Ìṣípayá 7:9.

6. Kí ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run máa pọ̀ sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún?

6 Kí ló mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe? Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló ń fa àwọn tó ní ọkàn tó dáa wọ̀nyí sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. (Jòhánù 6:65; Ìṣe 13:48) Àmọ́, ohun kan tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá ni ẹ̀mí àìmọtara ẹni táwọn tó ń lo gbogbo ara wọn nínú iṣẹ́ Ìjọba náà ní àti bí wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn. Nígbà tí Arákùnrin Macmillan wà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin, ó kọ̀wé pé: “Látìgbà tí mo ti kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún ìran ènìyàn tó ń ṣàìsàn tó sì ń kú yìí, ìrètí tí mo ní nínú ohun tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yẹn sọ kò tíì yingin. Ìgbà yẹn ni mo ti pinnu láti wádìí kí n lè túbọ̀ mọ̀ nípa ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni, kí n bàa lè ran àwọn mìíràn bíi tèmi lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa ní ìmọ̀ nípa Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, tí wọ́n sì tún fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ohun rere tó fẹ́ ṣe fún ìran ènìyàn.”

7. Àwọn ìrírí wo ló jẹ́ ká mọ ayọ̀ àti ìtara àwọn tó rí òtítọ́ Bíbélì?

7 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní náà ní irú ìtara bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti Daniela láti ìlú Vienna, ní orílẹ̀-èdè Austria. Ó sọ pé: “Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni Ọlọ́run ti jẹ́ ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ . Ó máa ń wù mi kí n mọ orúkọ rẹ̀ nítorí pé ‘Ọlọ́run’ tá a máa ń pè é yẹn kò dà bí orúkọ létí mi. Àmọ́ mo ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sílé wa. Wọ́n ṣàlàyé gbogbo ohun tí mo fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run fún mi. Bí mo ṣe rí òtítọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín nìyẹn o, kò sì láfiwé! Inú mi dùn débi pé kíá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún gbogbo èèyàn.” Kò pẹ́ tí ìtara tó ní yìí fí mú kí àwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. Daniela ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àmọ́, lójú tèmi ńṣe ló dà bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń nímùúṣẹ, nítorí mo ti ka ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé àwọn èèyàn á kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn òun, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí wọn nítorí orúkọ òun. Inú mi dùn gan-an, ó sì tún jọ mí lójú pẹ̀lú.” Láìpẹ́, Daniela ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bóun ṣe máa di míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn tí Daniela ṣègbéyàwó, òun àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Helmut, bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ara China, àwọn ọmọ ilẹ̀ Philippines àtàwọn ará Íńdíà tó wà nílùú Vienna. Daniela àti Helmut ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì báyìí ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà.

Wọn Ò Juwọ́ Sílẹ̀

8. Kí ni ọ̀nà kan tó mérè wá tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àwọn sì kọ́wọ́ ti Ìjọba náà lẹ́yìn?

8 Láìsí àní-àní, iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì jẹ́ ọ̀nà kan táwọn èèyàn Jèhófà lóde òní gbà ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àwọn sì kọ́wọ́ ti Ìjọba náà lẹ́yìn. Bíi ti oníṣòwò inú àpèjúwe Jésù yẹn làwọn tó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn yìí ṣe múra tán láti rìnrìn-àjò lọ síbi tó jìnnà gan-an nítorí ìhìn rere Ìjọba náà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé àwọn míṣọ́nnárì ń rìnrìn àjò kí wọ́n lè gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà o. Àwọn ló lọ ń sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn tó wà ní ibi tó jìnnà jù lọ láyé, tí wọ́n ń kọ́ wọn tí wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. (Mátíù 28:19, 20) Wọ́n ní láti fara da ìyà ńláǹlà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àmọ́ ìfaradà tí wọ́n ní yìí ń mú kí wọ́n rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà.

9, 10. Àwọn ìrírí alárinrin wo làwọn míṣọ́nnárì ní láwọn ibi tó jìnnà réré, bí orílẹ̀-èdè Central African Republic?

9 Àpẹẹrẹ kan rèé, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún àti ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́rin [16,184] làwọn tó wá sí ibi Ìrántí Ikú Kristi ní orílẹ̀-èdè Central African Republic lọ́dún tó kọjá. Iye yẹn jẹ́ nǹkan bí ìlọ́po méje iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́rùn ní orílẹ̀-èdè yẹn. Nítorí pé ìbi tó pọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè náà ni kò ní iná mànàmáná, ìta gbangba lábẹ́ ìbòòji igi làwọn èèyàn ti máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Nítorí ìdí èyí, kò sóhun táwọn míṣọ́nnárì lè ṣe ju kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn níta gbangba, kí wọ́n sì máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lábẹ́ igi tó ní ìbòòji. Yàtọ̀ sí pé ìta gbangba yẹn mọ́lẹ̀ kedere, ó sì tutù ju inú ilé lọ, ó tún ní àǹfààní mìíràn pẹ̀lú. Àwọn èèyàn náà fẹ́ràn Bíbélì gan-an, ọ̀rọ̀ nípa ìsìn ni wọ́n sì máa ń sọ jù. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó ń kọjá á rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń bá ẹnì kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n á sì wá jókòó tì wọ́n.

10 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí míṣọ́nnárì kan ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níwájú ilé, ọkùnrin kan tó ń gbé ní àdúgbò kejì wá bá wọn níbẹ̀. Ó sọ pé àwọn míṣọ́nnárì náà ò tíì dé ilé òun, òun fẹ́ kí wọ́n máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú àwọn míṣọ́nnárì náà dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà sì ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́. Àwọn ọlọ́pàá sábà máa ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí dúró lójú títì lórílẹ̀-èdè yẹn. Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ bá wọn wí tàbí wọ́n fẹ́ gbowó lọ́wọ́ wọn o. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó jáde kẹ́yìn ni wọ́n fẹ́ gbà lọ́wọ́ wọn tàbí kí wọ́n fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn nítorí àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n kà ní àkàgbádùn.

11. Láìfi àwọn ìṣòro pè, ojú wo làwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì fi ń wo iṣẹ́ ìsìn wọn?

11 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì bọ̀ láti nǹkan bí ogójì ọdún sí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ló ṣì ń bá iṣẹ́ náà lọ láìbojú wẹ̀yìn. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfaradà gidi làwọn yẹn jẹ́ fún gbogbo wa! Láti ọdún méjìlélógójì sẹ́yìn làwọn tọkọtaya kan ti jọ ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọkọ náà sọ pé: “A ti ní ìṣòro púpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn ibà fojú wa rí màbo fún ọdún márùndínlógójì. Síbẹ̀, a ò kábàámọ̀ rí pé a jẹ́ míṣọ́nnárì.” Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ìgbà la máa ń rí ohun tó yẹ ká tìtorí rẹ̀ máa dúpẹ́. A máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, ó sì rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá wá sípàdé tí wọ́n sì tibẹ̀ di ojúlùmọ̀ ara wọn, bí ìgbà tí ìdílé kan jọ pàdé pọ̀ ni àkókò ìpàdé náà máa ń rí.”

Wọ́n “Ka Ohun Gbogbo sí Àdánù”

12. Báwo lèèyàn ṣe ń fi hàn pé òun mọyì bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó?

12 Nígbà tí oníṣòwò arìnrìn-àjò náà rí péálì olówó iyebíye yẹn, “ó jáde lọ, ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́, ó sì rà á.” (Mátíù 13:46) Àwọn tó mọyì bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó máa ń múra tán láti yááfì ohun téèyàn gbà pé ó ṣeyebíye. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó máa gbádùn ògo Ìjọba náà pẹ̀lú Kristi sọ pé: “Ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.”—Fílípì 3:8.

13. Báwo lẹnì kan ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè Czech?

13 Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọ̀ gan-an nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè rí ìbùkún Ìjọba náà gbà. Bí àpẹẹrẹ, ní October 2003, ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún tó tún jẹ́ ọ̀gá ilé ìwé kan ní orílẹ̀-èdè Czech rí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tó kà á tán, kíá ló wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ̀ kàn kí wọ́n lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí gbogbo bó ṣe ń gbèrò láti di olórí ìlú kó sì tibẹ̀ gbé àpótí ìbò tí wọ́n á fi yàn án sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin? Ó yàn láti gbájú mọ́ nǹkan mìíràn tó yàtọ̀, ìyẹn ni eré ìje ìyè. Ó di olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọ ilé ìwé mi máa ń gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ gan-an lọ́wọ́ mi.” Ó fi ẹ̀rí hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà nígbà tó ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan ní July 2004.

14. (a) Kí ni ìhìn rere Ìjọba náà ti mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀ wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀?

14 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé ló ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà lọ́nà kan náà yìí. Wọ́n ti jáde kúrò nínú ayé burúkú yìí, wọ́n ti fi ìwà wọn àtijọ́ sílẹ̀, wọn ò bá àwọn tí wọ́n ń bá kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ kẹ́gbẹ́ mọ́, wọn ò si lépa àwọn nǹkan ayé mọ́. (Jòhánù 15:19; Éfésù 4:22-24; Jákọ́bù 4:4; 1 Jòhánù 2:15-17) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe gbogbo èyí? Nítorí pé ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run jọ wọ́n lójú ju ohunkóhun mìíràn tí ayé ìsinsìnyí lè fúnni. Ǹjẹ́ ọ̀ràn ìhìn rere Ìjọba náà máa ń rí bẹ́ẹ̀ lára ìwọ náà? Ǹjẹ́ ó ń mú kí o ṣe àwọn ìyípadà kan kó o lè mú ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ, ìwà rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó ò ń lépa bá ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe mu? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí ìbùkún yàbùgà-yabuga fún ọ nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú pẹ̀lú.

Ìkórè Náà Ti Ń Lọ Sópin Rẹ̀

15. Kí la sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

15 Onísáàmù kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ.” “Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀” àti “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá” ti “àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere” wà lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú yìí. (Sáàmù 68:11; 110:3) Kí ló ti jẹ́ àbájáde aápọn àti ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni àwọn èèyàn Jèhófà, lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

16. Fúnni ní àpẹẹrẹ kan nípa báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ń sapá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba náà?

16 Aṣáájú ọ̀nà kan tàbí ẹnì kan tó ń fi gbogbo ìgbà pòkìkí Ìjọba náà ní Íńdíà ronú nípa ohun tóun lè ṣe tí àwọn adití tó lé ní mílíọ̀nù méjì ní orílẹ̀-èdè náà á fi gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Aísáyà 35:5) Obìnrin náà wá forúkọ sílẹ̀ ní ilé ìwé kan nílùú Bangalore níbi tí wọ́n ti ń kọ́ni ní èdè àwọn adití. Ibẹ̀ ló ti ráyè bá ọ̀pọ̀ àwọn adití sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Ìjọba náà, ó tún ṣètò wọn sí àwùjọ kéékèèké tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, àwọn èèyàn tó lé ní méjìlá ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn ìyẹn, aṣáájú ọ̀nà yìí bá ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ òdì pàdé níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó kan. Ìlú Calcutta ni odi yìí ti wá, ó béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ó sì wù ú láti túbọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà. Àmọ́, ìṣòro kan wà. Ọ̀dọ́kùnrin yìí ní láti padà lọ bẹ̀rẹ̀ kọ́lẹ́ẹ̀jì kan tó fẹ́ lọ ní ìlú Calcutta, tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà sílùú tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó náà, kò sì sí Ẹlẹ́rìí kankan tó mọ èdè àwọn adití níbẹ̀. Ó sá gbogbo ipá rẹ̀ láti bẹ baba rẹ̀ kó lè jẹ́ kó lọ sí ilé ìwé tó wà nílùú Bangalore, kó lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lọ. Ó jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, nígbà tó sì tó nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Òun náà tún kọ́ àwọn adití bíi mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan ẹni kan tí wọ́n ti jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ láti kékeré. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ti Íńdíà ti ń ṣètò bí àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe máa kọ́ èdè àwọn adití báyìí, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ ní ìpínlẹ̀ yẹn.

17. Sọ ohun tó wú ọ lórí jù lọ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdún 2004 tó wà lójú èwé 19 sí 22.

17 Tó o bá wo ojú ìwé 19 sí 22 ìwé ìròyìn yìí, wàá rí ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004. Fara balẹ̀ wò ó, kó o sì fojú ara rẹ rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà jákèjádò ayé ń fi gbogbo ara wá ‘péálì olówó iyebíye’ náà kiri lónìí.

‘Ẹ Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’

18. Àwọn ìsọfúnni wo ni Jésù ò mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn, kí sì nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?

18 Ẹ jẹ́ ká tún padà gbé ọ̀rọ̀ oníṣòwò arìnrìn-àjò inú àpèjúwe Jésù yẹn yẹ̀ wò. A rí i pé Jésù ò sọ ohunkóhun nípa ọ̀nà tí oníṣòwò náà máa gbà gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́yìn tó ti ta gbogbo ohun tó ní. Ká sòótọ́, àwọn kan lè máa béèrè pé: ‘Báwo ló ṣe máa jẹun, aṣọ wo ló máa wọ̀, ilé wo ló sì máa gbé nísinsìnyí tí kò ní ohunkóhun mọ́? Àǹfààní wo ni péálì olówó iyebíye yẹn máa ṣe fún un?’ Àwọn ìbéèrè tó bọ́gbọ́n mu nìyẹn lóòótọ́ tá a bá fojú èèyàn ẹlẹ́ran ara wò ó. Àmọ́, ǹjẹ́ Jésù fúnra rẹ̀ ò rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín”? (Mátíù 6:31-33) Kókó inú àpèjúwe yẹn ni pé ó yẹ kéèyàn fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run kó sì máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ Ìjọba náà. Ǹjẹ́ a rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́ nínú èyí?

19. Kí ni ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe Jésù nípa péálì olówó iyebíye?

19 Ì báà jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhìn rere àtàtà yìí ni o, tàbí ó ti pẹ́ gan-an tá a ti ń wá Ìjọba náà tá a sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tó máa mú wá fáwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti jẹ́ kí Ìjọba náà jẹ́ ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ tó sì ń gba àfiyèsí wa jù lọ. Àwọn àkókò líle koko la wà lóòótọ́, àmọ́ a ní àwọn ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti gbà gbọ́ pé ohun tó jẹ́ ojúlówó tí kò sì láfiwé là ń wọ̀nà fún, bíi péálì tí oníṣòwò yẹn rí. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé àti ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” là ń gbé. (Mátíù 24:3) Bíi ti oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn, ẹ jẹ́ káwa náà ní ìtara àtọkànwá fún Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa yọ̀ pé a láǹfààní láti polongo ìhìn rere náà.—Sáàmù 9:1, 2.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló ń mú kí àwọn olùjọsìn tòótọ́ máa pọ̀ sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún?

• Irú ẹ̀mí wo làwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní?

• Àwọn ìyípadà wo làwọn kan ti ṣe nítorí ìhìn rere Ìjọba náà?

• Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe péálì olówó iyebíye tí Jésù sọ?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 19-22]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2004 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

‘Onírúurú èèyàn ni òtítọ́ máa ń fà mọ́ra.’—A. H. Macmillan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Daniela àti Helmut wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ní ìlú Vienna

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àwọn míṣọ́nnárì òde òní ń rí ìbùkún yàbùgà-yabuga bíi ti oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

“Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn”