Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 1:1-26

  • Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-5)

  • Iṣẹ́ ìwàásù máa dé gbogbo ìkángun ayé (6-8)

  • Jésù gòkè lọ sọ́run (9-11)

  • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ ní ìṣọ̀kan (12-14)

  • Wọ́n yan Màtáyásì rọ́pò Júdásì (15-26)

1  Tìófílọ́sì, nínú ìwé àkọ́kọ́ tí mo kọ sí ọ, mo sọ nípa gbogbo ohun tí Jésù ṣe àti ohun tí ó kọ́ni+  títí di ọjọ́ tí Ọlọ́run gbé e lọ sókè,+ lẹ́yìn tó ti tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sọ ohun tí àwọn àpọ́sítélì tó ti yàn máa ṣe.+  Lẹ́yìn tó ti jìyà, ó fara hàn wọ́n láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú.+ Wọ́n rí i jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.+  Nígbà tó ń bá wọn ṣèpàdé, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù,+ àmọ́ ẹ dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí,+ èyí tí ẹ gbọ́ lẹ́nu mi;  lóòótọ́, Jòhánù fi omi batisí, àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín+ láìpẹ́ ọjọ́.”  Nígbà tí wọ́n pé jọ, wọ́n bi í pé: “Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?”+  Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí ìkáwọ́* rẹ̀.+  Àmọ́, ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”*+  Lẹ́yìn tó ti sọ àwọn nǹkan yìí, bí wọ́n ṣe ń wò ó, a gbé e sókè, àwọsánmà sì gbà á lọ mọ́ wọn lójú.+ 10  Bí wọ́n ṣe tẹjú mọ́ sánmà nígbà tó ń lọ, lójijì ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 11  wọ́n sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.” 12  Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù+ láti òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì, tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó tó ìrìn ọjọ́ sábáàtì kan. 13  Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n lọ sínú yàrá òkè tí wọ́n ń gbé. Àwọn ni: Pétérù pẹ̀lú Jòhánù àti Jémíìsì àti Áńdérù, Fílípì àti Tọ́másì, Batolómíù àti Mátíù, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì àti Símónì onítara pẹ̀lú Júdásì ọmọ Jémíìsì.+ 14  Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan, àwọn àti àwọn obìnrin kan+ pẹ̀lú Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 15  Lásìkò yẹn, Pétérù dìde láàárín àwọn ará, (iye àwọn èèyàn* náà lápapọ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́fà [120]) ó sì sọ pé: 16  “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ ṣẹ, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ gba ẹnu Dáfídì sọ nípa Júdásì,+ ẹni tó ṣamọ̀nà àwọn tó wá mú Jésù.+ 17  Nítorí a ti kà á mọ́ wa,+ ó sì ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí. 18  (Ọkùnrin yìí fi owó iṣẹ́ ibi+ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan, àmọ́, ó fi orí sọlẹ̀, ikùn rẹ̀ bẹ́,* gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú síta.+ 19  Gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì pe ilẹ̀ náà ní Ákélídámà ní èdè wọn, ìyẹn, “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) 20  Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Kí ibi tó ń gbé di ahoro, kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú rẹ̀’+ àti pé, ‘Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.’+ 21  Nítorí náà, ó pọn dandan pé nínú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú wa ní gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀* láàárín wa, 22  látìgbà tí Jòhánù ti ṣèrìbọmi fún un+ títí di ọjọ́ tí a gbé e sókè kúrò lọ́dọ̀ wa,+ kí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin yìí di ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”+ 23  Nítorí náà, wọ́n dábàá àwọn méjì, Jósẹ́fù tí wọ́n ń pè ní Básábà, tí wọ́n tún ń pè ní Jọ́sítù àti ẹnì kejì, Màtáyásì. 24  Wọ́n wá gbàdúrà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà,* ìwọ ẹni tó mọ ọkàn gbogbo èèyàn,+ fi ẹni tí o yàn lára àwọn ọkùnrin méjì yìí hàn, 25  tó máa gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti iṣẹ́ àpọ́sítélì yìí, tí Júdásì gbé sílẹ̀ kí ó lè lọ ṣe tirẹ̀.”+ 26  Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké lé wọn,+ kèké sì mú Màtáyásì, a sì kà á mọ́* àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11).

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “dé ìkángun ayé.”
Tàbí “èrò.”
Tàbí “ó bẹ́ ní àárín.”
Ní Grk., “fi ń wọlé, tó sì ń jáde.”
Tàbí “kà á kún,” ìyẹn ni pé, ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó kù ni wọ́n fi ń wò ó.