Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 13:1-52

  • Wọ́n rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti lọ ṣe míṣọ́nnárì (1-3)

  • Iṣẹ́ ìwàásù ní Sápírọ́sì (4-12)

  • Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Áńtíókù ti Písídíà (13-41)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ tó fún wọn láṣẹ láti yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè (42-52)

13  Ní Áńtíókù, àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ wà nínú ìjọ tó wà níbẹ̀,+ àwọn ni: Bánábà, Símíónì tí wọ́n ń pè ní Nígérì, Lúkíọ́sì ará Kírénè àti Mánáénì tó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù alákòóso agbègbè náà, àti Sọ́ọ̀lù.  Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ Jèhófà,* tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ sọ pé: “Ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù+ sọ́tọ̀ fún mi kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.”+  Lẹ́yìn tí wọ́n gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.  Torí náà, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ rán jáde yìí lọ sí Séléúkíà, wọ́n sì wọkọ̀ láti ibẹ̀ lọ sí Sápírọ́sì.  Nígbà tí wọ́n dé Sálámísì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù sì wà lọ́dọ̀ wọn, ó ń ṣe ìránṣẹ́.*+  Nígbà tí wọ́n ti gba gbogbo erékùṣù náà kọjá títí dé Páfò, wọ́n bá ọkùnrin Júù kan pàdé tó ń jẹ́ Baa-Jésù, oníṣẹ́ oṣó àti wòlíì èké ni.  Ó wà pẹ̀lú Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀,* ọkùnrin onílàákàyè ni. Ọkùnrin yìí pe Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ara rẹ̀ ti wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  Àmọ́ Élímà oníṣẹ́ oṣó náà (torí bí wọ́n ṣe túmọ̀ orúkọ rẹ̀ nìyẹn) bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wọ́n, ó fẹ́ yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.  Ni Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n tún ń pè ní Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, bá tẹjú mọ́ ọn, 10  ó sì sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin tí oríṣiríṣi jìbìtì àti ìwà ibi kún ọwọ́ rẹ̀, ìwọ ọmọ Èṣù,+ ìwọ ọ̀tá gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo, ṣé o kò ní ṣíwọ́ yíyí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà* po ni? 11  Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà* wà lára rẹ, wàá fọ́ lójú, o ò ní rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún àkókò kan.” Lójú ẹsẹ̀, kùrukùru tó ṣú àti òkùnkùn bò ó, ó sì ń táràrà, ó ń wá ẹni tó máa di òun lọ́wọ́ mú lọ. 12  Bí alákòóso ìbílẹ̀ náà ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó di onígbàgbọ́, torí ẹ̀kọ́ Jèhófà* yà á lẹ́nu gan-an. 13  Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ wọ ọkọ̀ òkun láti Páfò, wọ́n sì dé Pẹ́gà ní Panfílíà. Àmọ́ Jòhánù+ fi wọ́n sílẹ̀, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù.+ 14  Àmọ́, wọ́n tẹ̀ síwájú láti Pẹ́gà, wọ́n sì wá sí Áńtíókù ní Písídíà. Wọ́n wọ sínágọ́gù+ ní ọjọ́ Sábáàtì, wọ́n sì jókòó. 15  Lẹ́yìn kíka Òfin+ àti ìwé àwọn Wòlíì fún àwọn èèyàn, àwọn alága sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, tí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí fún àwọn èèyàn, ẹ sọ ọ́.” 16  Ni Pọ́ọ̀lù bá dìde, ó sì ń fọwọ́ ṣàpèjúwe, ó sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fetí sílẹ̀. 17  Ọlọ́run àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba ńlá wa, ó gbé àwọn èèyàn náà ga nígbà tí wọ́n jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fi ọwọ́ agbára* mú wọn jáde kúrò níbẹ̀.+ 18  Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ló fi fara dà á fún wọn ní aginjù.+ 19  Lẹ́yìn tó pa orílẹ̀-èdè méje run ní ilẹ̀ Kénáánì, ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún fún àwọn baba ńlá wa.+ 20  Gbogbo èyí wáyé láàárín nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) ọdún. “Lẹ́yìn náà, ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di ìgbà wòlíì Sámúẹ́lì.+ 21  Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n ní àwọn fẹ́ ọba,+ Ọlọ́run sì fún wọn ní Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó fi ogójì (40) ọdún jọba. 22  Lẹ́yìn tó mú un kúrò, ó gbé Dáfídì dìde láti jẹ́ ọba wọn,+ ẹni tó jẹ́rìí nípa rẹ̀, tó sì sọ pé: ‘Mo ti rí Dáfídì ọmọ Jésè,+ ẹni tí ọkàn mi fẹ́;+ yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.’ 23  Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tó ṣe, látọ̀dọ̀ ọmọ* ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti mú olùgbàlà wá fún Ísírẹ́lì, ìyẹn Jésù.+ 24  Kí ẹni yẹn tó dé, Jòhánù ti wàásù ní gbangba fún gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì nípa ìrìbọmi tó jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà.+ 25  Àmọ́ bí Jòhánù ṣe ń parí iṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó ń sọ pé: ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kọ́ ni ẹni náà. Àmọ́, ẹ wò ó! Ẹnì kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí mi ò tó bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ tú.’+ 26  “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin àtọmọdọ́mọ ìdílé Ábúráhámù àti àwọn yòókù láàárín yín tó bẹ̀rù Ọlọ́run, a ti fi ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí ránṣẹ́ sí wa.+ 27  Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn alákòóso wọn kò dá ẹni yìí mọ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ onídàájọ́, wọ́n mú àwọn ohun tí àwọn Wòlíì sọ ṣẹ,+ èyí tí à ń kà sókè ní gbogbo sábáàtì. 28  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìdí kankan tó fi jẹ̀bi ikú,+ wọ́n ní kí Pílátù jẹ́ kí wọ́n pa á.+ 29  Nígbà tí wọ́n ti mú gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nípa rẹ̀ ṣẹ, wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ lórí òpó igi,* wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì.*+ 30  Àmọ́ Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú,+ 31  ọjọ́ púpọ̀ ni àwọn tó bá a lọ láti Gálílì sí Jerúsálẹ́mù fi rí i. Àwọn yìí ló wá ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn.+ 32  “Nítorí náà, ìhìn rere nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wa là ń kéde fún yín. 33  Ọlọ́run ti mú un ṣẹ pátápátá fún àwa ọmọ wọn bó ṣe jí Jésù dìde;+ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú sáàmù kejì pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi, òní ni mo di bàbá rẹ.’+ 34  Bí Ó ṣe jí i dìde nínú ikú, tí kò sì jẹ́ kó pa dà sí ara tó lè díbàjẹ́ mọ́, ó sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: ‘Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì hàn sí ọ, èyí tó jẹ́ òtítọ́.’*+ 35  Bákan náà, ó tún wà nínú sáàmù míì pé: ‘O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’+ 36  Dáfídì ní tirẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn fún* Ọlọ́run ní ìran rẹ̀, ó sùn nínú ikú, wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ó sì rí ìdíbàjẹ́.+ 37  Àmọ́, ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde kò rí ìdíbàjẹ́.+ 38  “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín,+ 39  àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò lè sọ pé ẹ ò jẹ̀bi rẹ̀ nípasẹ̀ Òfin Mósè,+ ni à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.+ 40  Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì má bàa ṣẹ sí yín lára, pé: 41  ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣègbé, nítorí mò ń ṣe iṣẹ́ kan lásìkò yín, iṣẹ́ tí ẹ ò ní gbà gbọ́ láé bí ẹnì kan bá tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún yín.’”+ 42  Nígbà tí wọ́n ń jáde lọ, àwọn èèyàn bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e. 43  Torí náà, lẹ́yìn tí àpéjọ sínágọ́gù parí, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe* tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, bí àwọn yìí sì ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+ 44  Ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú náà ló kóra jọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.* 45  Nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ èèyàn, inú bí wọn* gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ òdì ta ko àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.+ 46  Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+ 47  Nítorí Jèhófà* ti pa àwọn ọ̀rọ̀ yìí láṣẹ fún wa pé: ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí o lè jẹ́ ìgbàlà fún gbogbo ayé.’”+ 48  Nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì ń yin ọ̀rọ̀ Jèhófà* lógo, gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́. 49  Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà. 50  Àmọ́ àwọn Júù ru àwọn obìnrin olókìkí tó bẹ̀rù Ọlọ́run àti àwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú náà sókè, wọ́n gbé inúnibíni+ dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn. 51  Torí náà, wọ́n gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù sí wọn, wọ́n sì lọ sí Íkóníónì.+ 52  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń ní ìdùnnú+ àti ẹ̀mí mímọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “olùrànlọ́wọ́.”
Gómìnà ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso ìpínlẹ̀. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “ọwọ́ tó ròkè.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “igi.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ṣeé gbíyè lé; ṣeé gbára lé.”
Tàbí “ṣe ìfẹ́.”
Ìyẹn, àwọn tó gba ẹ̀sìn Júù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “wọ́n jowú.”