Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní

“Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.

ÌKÌLỌ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nìyẹn nípa ewu tó wà nínú títẹ̀lé ọgbọ́n orí ènìyàn láìronújinlẹ̀. Wọ́n lè fara mọ́ ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pèsè, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní nínú rẹ̀. Tàbí kí wọ́n di ẹni tá a tàn jẹ nípasẹ̀ ìrònú ènìyàn tí kì í dúró sójú kan, èyí tó ti fa ìnira àti ìbànújẹ́ bá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn.—1 Kọ́ríńtì 1:19-21; 3:18-20.

Gbígbé “Ní Ìbámu Pẹ̀lú Kristi”

Kò yé àwọn ajagun ẹ̀sìn tó jagun ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan sẹ́yìn pé gbígbé “ní ìbámu pẹ̀lú Kristi” ju fífẹnu lásán sọ pé àwọ́n dúró ṣinṣin ti Jésù Kristi. (Mátíù 7:21-23) Ohun tó túmọ̀ sí ni gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni láìkù síbì kan, bó ti wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí, ìyẹn Bíbélì. (Mátíù 7:15-20; Jòhánù 17:17) Jésù Kristi sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́.” (Jòhánù 8:31) Ó tún sọ pé: “Gbogbo ènìyàn yóò . . . mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

Ká sòótọ́, àwọn ajagun ẹ̀sìn wọ̀nyẹn ti jìn sí ọ̀fìn “ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.” Kò sì yani lẹ́nu pé àwọn gbáàtúù èèyàn ni a ti tàn jẹ, nígbà tí wọ́n bá rí àwọn aṣáájú ìsìn wọn, ìyẹn àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn gan-an, tí wọ́n ń “di gbajúgbajà nídìí iṣẹ́ ogun.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature tí McClintock àti Strong kọ ti sọ, pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà ló jẹ́ arógunyọ̀, débi pé, ìgbàkigbà tí [ogun] bá ti lè mú àǹfààní èyíkéyìí wá fún wọn, wọn kì í kọ̀ láti jà á.”

Kí ló fa ipò tí ń bani nínú jẹ́ yìí? Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, lẹ́yìn ikú àwọn Kristẹni àpọ́sítélì ọ̀rúndún kìíní, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì tó ti di apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í yà kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi fi kọ́ni láìbojúwẹ̀yìn. (Ìṣe 20:29, 30) Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ńṣe ni ṣọ́ọ̀ṣì tó ti di ẹlẹ́gbin yìí wá di kòríkòsùn ìjọba ayé. Ní ọ̀rúndún kẹrin, nígbà tó kù díẹ̀ kí Kọnsitatáìnì, Olú Ọba Róòmù gbẹ́mìí mì, ó sọ pé òún ti di ẹlẹ́sìn Kristẹni. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tá a dárúkọ rẹ̀ níṣàájú wá sọ pé: “Fífi tí wọ́n fi àmì Àgbélébùú rọ́pò àwọn àmì olórìṣà mú kó di dandan fún gbogbo àwọn Kristẹni láti ṣiṣẹ́ ológun.”

Ó dájú pé kò sí òfin kankan tó sọ pé kí àwọn Kristẹni ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ “àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà,” tó wá látinú èrò orí ènìyàn ló mú kí wọ́n gbójú fo gbogbo àwọn ìlànà Kristi dá. (Kólósè 2:4) Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń lo àwọn iyàn jíjà tó kún fún ìtànjẹ láti dá ogun àti ìjà tí wọ́n máa ń jà láre. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà ṣe sọ, kò yẹ kí ẹnì kan tó láàánú ọmọnìkejì rẹ̀ lójú tàbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa lọ́wọ́ nínú “ìwà bíburú jáì tá a mọ̀ sí ogun, yálà lọ́nà tí wọ́n ń gbà jà á láyé ọjọ́un tàbí láyé òde òní, torí pé èyí kò fi ibì kankan . . . bá àwọn ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni mu.”

Ogun làwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tí wọn kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristi náà máa ń yíjú sí láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Bíi tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ti pa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹlẹ́sìn kan náà àtàwọn mìíràn nítorí pé orílẹ̀-èdè wọn, ìjọba wọn àti ìsìn wọn yàtọ̀ síra wọn. Wọ́n ti lo ìwà ipá tàbí ìhalẹ̀mọ́ni láti fi tipátipá mú káwọn ẹlòmíràn ṣe ẹ̀sìn wọn. Àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyí ti lọ́wọ́ nínú pípa àwọn èèyàn nípakúpa nínú àwọn ogun tó ti wáyé, nítorí kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá. Wọn ò fi ibì kankan yàtọ̀ sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.

Wọn Yàtọ̀ Gédégédé sí Ayé

Kí lohun tó mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní láti yẹra fún àwọn ogun tó ń fẹ̀mí ṣòfò àti ọ̀rọ̀ ìṣèlú ayé ìgbà yẹn? Ìlànà pàtàkì méjì kan ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Èkíní, wọ́n rántí àṣẹ tí Jésù pa fún àpọ́sítélì Pétérù nígbà tó fi idà gbèjà Jésù, pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Èkejì, wọ́n fi èsì tí Jésù fún Pílátù sọ́kàn, nígbà tó béèrè pé irú ìjọba wo ni ti Jésù. Èsì ọ̀hún ni pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.”—Jòhánù 18:36.

Báwo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe mú àwọn ìlànà wọ̀nyí lò? Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ayé, wọn ò dá sí tọ̀tún tòsì rárá nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí ti ogun. (Jòhánù 15:17-19; 17:14-16; Jákọ́bù 4:4) Wọn ò gbé ohun ìjà láti fi pa ọmọnìkejì wọn. Ìtàn mú un ṣe kedere pé, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn Júù tàbí àwọn ẹgbẹ́ ológun tó ń ṣojú fún ìjọba Róòmù. Síbẹ̀ náà, wọn ò gbìyànjú láti máa júwe ọ̀nà tó yẹ káwọn alákòóso ìṣèlú tọ̀ fún wọn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹrù iṣẹ́ àwọn aláṣẹ ìjọba yẹn nìyẹn.—Gálátíà 6:5.

Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, Justin Martyr kọ̀wé nípa àwọn Kristẹni pé, wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.” (Míkà 4:3) Nígbà tí Tertullian ń fèsì ọ̀rọ̀ àwọn kan tó ń sọ pé kò bójú mu báwọn Kristẹni ṣe láwọn ò wọṣẹ́ ológun, ó bi wọ́n pé: “Ṣé a lè gbà pé ó bófin mu láti lo idà, nígbà tí Olúwa ti polongo pé ẹni tó bá lo idà á tipa idà ṣègbé?”

“Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”

Kíkọ̀ táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kọ̀ láti jagun mú kí nǹkan nira fún wọn. Òdìkejì pátápátá lèyí jẹ́ sí ohun táwọn èèyàn ìgbà yẹn gbà gbọ́. Celsus, tó jẹ́ ọ̀tá ìsìn Kristẹni, fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ojú tí wọ́n fi wo ọ̀ràn ogun. Ìgbàgbọ́ tiẹ̀ ni pé, gbogbo èèyàn pátá ló gbọ́dọ̀ lọ sógun nígbàkigbà táwọn aláṣẹ bá ti lè sọ pé ó yá. Àmọ́ láìka inúnibíni lílékenkà tí wọ́n ń ṣe sáwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sí, wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí èèyàn èyí tó ta ko àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi fi kọ́ni. Wọ́n sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 4:19; 5:29.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjọba Násì ń ṣàkóso nílẹ̀ Jámánì, wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú àwọn ogun afẹ̀jẹ̀wẹ̀ tí Hitler ṣagbátẹrù rẹ̀. Wọ́n múra tán láti fara da inúnibíni rírorò, kódà wọ́n gbà láti kú tó bá jẹ́ ohun tó gbà nìyẹn, dípò kí wọ́n ba àìdásí-tọ̀túntòsì wọn bíi Kristẹni jẹ́. Ìròyìn sọ pé, ìjọba Násì “ju ìdajì wọn sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa ìdá kan nínú mẹ́rin wọn” nítorí pé wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì. (Ìwé Of Gods and Men lo sọ bẹ́ẹ̀.) Nípa báyìí, nínú gbogbo ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí wọ́n pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ẹ̀mí èyíkéyìí lára wọn ò tọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ́. Kàkà tí àwọn Ẹlẹ́rìí ì bá fi pa àwọn mìíràn, wọ́n ṣe tán láti fi ẹ̀mí ara wọn dí i, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ lára wọn ti ṣe.

Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá? Dájúdájú, ọ̀kan ni pé: Àìmọye ìgbà ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí èèyàn ti yọrí sí ìkórìíra àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti láàárín àwọn èèyàn. Oníwàásù 8:9 tọ̀nà nígbà tó sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Lájorí ohun tó sì fa èyí la rí nínú ìwé Jeremáyà 10:23, níbi tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Rárá o, Ọlọ́run kò dá àwọn ẹ̀dá èèyàn láti máa darí ara wọn láìfi tirẹ̀ ṣe kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Kò fún èèyàn ní agbára yẹn. Gbogbo ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látẹ̀yìnwá fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa bí ẹnì kan kò lè yí ohun táwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè ń ṣe padà nítorí pé àwọn ohun tó fa ìbànújẹ́ látẹ̀yìnwá náà ni wọ́n tún ń dágbá lé, bẹ́ẹ̀ la ò sì fún wa láṣẹ láti máa rọ̀ wọ́n pé ọ̀nà báyìí ni kí wọ́n tọ̀. Àmọ́, a kò ní láti jẹ́ kí wọ́n tì wá láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìjà wọn ká sì wá di ara wọn. Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14) Ká má bàa di apá kan àwọn tí ń bá ara wọn jà nínú ayé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì la gbọ́dọ̀ fi máa tọ́ ìgbésí ayé wa, a ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí èèyàn tí kì í dúró sójú kan.—Mátíù 7:24-27; 2 Tímótì 3:16, 17.

Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu

Kì í ṣe àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá àtàwọn tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nìkan ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a lè gbára lé tànmọ́lẹ̀ sí. Ó pèsè ìtọ́sọ́nà tó dájú fún wa nípa ọjọ́ ọ̀la. (Sáàmù 119:105; Aísáyà 46:9-11) Ó tún ṣàlàyé fún wa ní kedere nípa ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe sọ́rọ̀ ayé yìí. Kò ní gba àwọn èèyàn láyè láti pa ilẹ̀ ayé run, kò ní gbà kí wọ́n fi ìwà òmùgọ̀ wọn ṣi agbára tí wọ́n ń rí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lò. Ọlọ́run á rí sí i pé ilẹ̀ ayé wa di Párádísè gẹ́gẹ́ bó ti pinnu rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.—Lúùkù 23:43.

Lórí kókó yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:21, 22) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, níwọ̀n bí àwọn àkókò làásìgbò wọ̀nyí ti jẹ́ ẹ̀rí pé a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Ohun kan tó sì dájú ni pé, ó níye àkókò tí Ọlọ́run dá fún àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí; àkókò ọ̀hún sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi yé wa pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17; Dáníẹ́lì 2:44.

Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé,” yóò sì wá fi ayé tuntun kan tí “òdodo yóò . . . máa gbé” rọ́pò ayé oníwà ipá tá à ń gbé inú rẹ̀ báyìí. (Ìṣípayá 11:18; 2 Pétérù 3:10-13) Lẹ́yìn náà, ní ti àwọn tó bá ṣẹ́ kù, “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:1-4) Ogun àti ìwà ipá kò ní sí mọ́ títí ayé, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 2:4 yóò nímùúṣẹ ní kíkún nígbà náà, èyí tó sọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Ìwọ náà lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu tó máa wà títí ayé yìí, bó o bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.—Jòhánù 17:3.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Jésù sọ pé Ìjọba òun kì í ṣe apá kan ayé yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé níbi tí àwọn èèyàn á ti di ẹni pípé