Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 4:1-37

  • Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù (1-4)

    • Iye àwọn onígbàgbọ́ di 5,000 ọkùnrin (4)

  • Ìgbẹ́jọ́ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (5-22)

    • ‘A ò lè ṣàì sọ̀rọ̀’ (20)

  • Àdúrà ìgboyà (23-31)

  • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ pín ohun tí wọ́n ní (32-37)

4  Nígbà tí àwọn méjèèjì ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn àlùfáà, olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn Sadusí+ wá bá wọn.  Inú ń bí wọn torí pé àwọn àpọ́sítélì ń kọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kéde ní gbangba nípa àjíǹde Jésù kúrò nínú ikú.*+  Torí náà, wọ́n gbá wọn mú,* wọ́n sì fi wọ́n sínú àhámọ́+ títí di ọjọ́ kejì, nítorí ilẹ̀ ti ń ṣú.  Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn di onígbàgbọ́, iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).+  Lọ́jọ́ kejì, àwọn alákòóso wọn, àwọn àgbààgbà àti àwọn akọ̀wé òfin kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù,  pẹ̀lú Ánásì+ olórí àlùfáà, Káyáfà,+ Jòhánù, Alẹkisáńdà àti gbogbo mọ̀lẹ́bí olórí àlùfáà.  Wọ́n ní kí Pétérù àti Jòhánù dúró ní àárín wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò wọ́n, wọ́n ní: “Agbára wo tàbí orúkọ ta ni ẹ fi ṣe èyí?”  Ni Pétérù, tí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ bá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin alákòóso àti ẹ̀yin àgbààgbà,  tó bá jẹ́ pé lórí oore tí a ṣe fún ọkùnrin tó yarọ + ni ẹ ṣe ń wádìí lónìí yìí, tí ẹ sì fẹ́ mọ ẹni tó mú ọkùnrin yìí lára dá, 10  kí gbogbo yín àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì yáa mọ̀ pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì,+ ẹni tí ẹ kàn mọ́gi,*+ àmọ́ tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú ikú,+ ni ọkùnrin yìí fi dúró níbí pẹ̀lú ara yíyá gágá níwájú yín. 11  Jésù yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin kọ́lékọ́lé ò kà sí tó ti wá di olórí òkúta igun ilé.’*+ 12  Yàtọ̀ síyẹn, kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíì, nítorí kò sí orúkọ míì+ lábẹ́ ọ̀run tí a fún àwọn èèyàn tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà.”+ 13  Nígbà tí wọ́n rí bí ọ̀rọ̀ ṣe dá lẹ́nu Pétérù àti Jòhánù,* tí wọ́n sì mọ̀ pé wọn ò kàwé* àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù,+ ẹnu yà wọ́n gan-an. Wọ́n wá rántí pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.+ 14  Bí wọ́n ṣe ń wo ọkùnrin tí a ti wò sàn tó dúró pẹ̀lú wọn,+ wọn ò lè fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ náà.+ 15  Torí náà, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n jáde síta gbọ̀ngàn Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fikùn lukùn, 16  wọ́n sọ pé: “Kí ni ká ṣe sọ́rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí?+ Nítorí, ká sòótọ́, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ àmì tó gbàfiyèsí, ó sì ṣe kedere sí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,+ a ò sì lè sọ pé kò ṣẹlẹ̀. 17  Kí ọ̀rọ̀ yìí má bàa tàn kọjá ibi tó dé láàárín àwọn èèyàn, ẹ jẹ́ ká halẹ̀ mọ́ wọn, ká sì sọ fún wọn pé wọn ò tún gbọ́dọ̀ sọ nípa orúkọ yìí fún ẹnikẹ́ni mọ́.”+ 18  Ni wọ́n bá pè wọ́n, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ohunkóhun tàbí kọ́ni nípa orúkọ Jésù mọ́. 19  Àmọ́, Pétérù àti Jòhánù fún wọn lésì pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. 20  Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”+ 21  Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti halẹ̀ mọ́ wọn sí i, wọ́n dá wọn sílẹ̀, torí wọn ò rí ìdí tí wọ́n á fi fìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì tún ro ti àwọn èèyàn náà,+ torí ńṣe ni gbogbo wọn ń yin Ọlọ́run lógo lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀. 22  Nítorí ọkùnrin tí wọ́n fi iṣẹ́ ìyanu* wò sàn yìí ti lé lẹ́ni ogójì (40) ọdún. 23  Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ bá àwọn èèyàn wọn, wọ́n sì ròyìn ohun tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. 24  Nígbà tí wọ́n gbọ́, gbogbo wọn jọ gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sọ pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn,+ 25  tó sì tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ gbẹnu Dáfídì+ baba ńlá wa tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ sọ pé: ‘Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe awuyewuye, tí àwọn èèyàn sì ń ṣe àṣàrò lórí ohun asán? 26  Àwọn ọba ayé dúró, àwọn alákòóso sì kóra jọ láti dojú kọ Jèhófà* àti ẹni àmì òróró* rẹ̀.’+ 27  Ní tòótọ́, Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ńtíù Pílátù+ pẹ̀lú àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì kóra jọ ní ìlú yìí láti dojú kọ Jésù, ìránṣẹ́ rẹ mímọ́, ẹni tí o fòróró yàn,+ 28  kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun tí o ti pinnu nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ràn rẹ pé kó ṣẹlẹ̀.+ 29  Ní báyìí, Jèhófà,* fiyè sí ìhàlẹ̀ wọn, kí o sì jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà, 30  bí o ṣe ń na ọwọ́ rẹ jáde láti múni lára dá, tí àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* sì ń ṣẹlẹ̀+ nípasẹ̀ orúkọ Jésù ìránṣẹ́ rẹ mímọ́.”+ 31  Nígbà tí wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀* tán, ibi tí wọ́n kóra jọ sí mì tìtì, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ 32  Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó di onígbàgbọ́ wá ṣọ̀kan ní inú* àti ọkàn, kódà kò sí ìkankan nínú wọn tó sọ pé ohun tí òun ní jẹ́ tòun, ṣe ni wọ́n jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní.+ 33  Pẹ̀lú agbára ńlá, àwọn àpọ́sítélì ń jẹ́rìí nìṣó nípa àjíǹde Jésù Olúwa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí sì wà lórí gbogbo wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. 34  Ní ti tòótọ́, kò sẹ́ni tó ṣaláìní láàárín wọn,+ torí ṣe ni gbogbo àwọn tó ní ilẹ̀ tàbí ilé ń tà wọ́n, tí wọ́n sì ń mú owó ohun tí wọ́n tà wá, 35  wọ́n á sì fi sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+ Àwọn náà á wá pín in fún ẹnì kọ̀ọ̀kan bí ohun tó nílò bá ṣe pọ̀ tó.+ 36  Nítorí náà, Jósẹ́fù, tí àwọn àpọ́sítélì tún ń pè ní Bánábà+ (tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú”, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀), tó jẹ́ ọmọ Léfì, ọmọ ìbílẹ̀ Sápírọ́sì, 37  ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó sì mú owó náà wá, ó sì fi sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àjíǹde kúrò nínú ikú nípasẹ̀ ọ̀ràn Jésù.”
Tàbí “mú wọn.”
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “olórí igun.”
Tàbí “bí Pétérù àti Jòhánù ṣe fi ìgboyà sọ̀rọ̀.”
Tàbí “mọ̀wé,” ìyẹn ni pé wọn ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì; kò túmọ̀ sí pé wọn ò lè kàwé.
Tàbí “àmì.”
Tàbí “Kristi.”
Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí “tí wọ́n ti gbàdúrà taratara.”
Ní Grk., “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.