Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 5:1-42

  • Ananáyà àti Sàfírà (1-11)

  • Àwọn àpọ́sítélì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì (12-16)

  • Wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ (17-21a)

  • Wọ́n tún mú wọn wá síwájú Sàhẹ́ndìrìn (21b-32)

    • ‘Ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò èèyàn’ (29)

  • Ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì (33-40)

  • Wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé (41, 42)

5  Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà pẹ̀lú Sàfírà ìyàwó rẹ̀ ta àwọn ohun ìní kan.  Àmọ́, ó yọ lára owó náà pa mọ́, ìyàwó rẹ̀ sì mọ̀ sí i, ó wá mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+  Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ananáyà, kí ló dé tí Sátánì fi kì ọ́ láyà láti parọ́ + fún ẹ̀mí mímọ́,+ tí o fi yọ lára owó ilẹ̀ náà pa mọ́?  Ní gbogbo ìgbà tó wà lọ́wọ́ rẹ, ṣé kì í ṣe tìrẹ ni? Lẹ́yìn tí o sì tà á, ṣé kì í ṣe ìkáwọ́ rẹ ló wà ni? Kí ló dé tí o fi ro irú nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Èèyàn kọ́ lo parọ́ fún, Ọlọ́run ni.”  Bí Ananáyà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú. Jìnnìjìnnì sì bo gbogbo àwọn tó gbọ́ nípa rẹ̀.  Àwọn ọ̀dọ́kùnrin bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e jáde, wọ́n sì sin ín.  Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta, ìyàwó rẹ̀ wọlé, àmọ́ kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀.  Pétérù sọ fún un pé: “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ̀yin méjèèjì ta ilẹ̀ náà nìyí?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”  Ni Pétérù bá sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀yin méjèèjì fi fohùn ṣọ̀kan láti dán ẹ̀mí Jèhófà* wò? Wò ó! Àwọn tó lọ sin ọkọ rẹ ti wà lẹ́nu ọ̀nà, wọ́n á gbé ìwọ náà jáde.” 10  Lójú ẹsẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ Pétérù, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wọlé, wọ́n bá a tí ó ti kú, wọ́n gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ rẹ̀. 11  Jìnnìjìnnì wá bo gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tó gbọ́ nípa nǹkan yìí. 12  Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* ló ń ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn àpọ́sítélì láàárín àwọn èèyàn;+ gbogbo wọn sì máa ń pé jọ nínú Ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì.+ 13  Àmọ́, àwọn míì ò láyà láti dara pọ̀ mọ́ wọn; síbẹ̀, àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ wọn dáadáa. 14  Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣe ni àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa ń dara pọ̀ mọ́ wọn, iye wọn sì pọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.+ 15  Kódà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n á tẹ́ wọn síbẹ̀ lórí àwọn ibùsùn kéékèèké àti ẹní, kí ó lè jẹ́ pé tí Pétérù bá ń kọjá, ó kéré tán, òjìji rẹ̀ á kọjá lára àwọn kan nínú wọn.+ 16  Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá láti àwọn ìlú tó wà ní àyíká Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn àti àwọn tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá, gbogbo wọn sì ń rí ìwòsàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. 17  Àmọ́ àlùfáà àgbà dìde àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n wà nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn Sadusí, inú bí wọn* gidigidi. 18  Wọ́n gbá àwọn àpọ́sítélì mú,* wọ́n sì tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n ìlú.+ 19  Àmọ́ ní òru, áńgẹ́lì Jèhófà* ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà,+ ó mú wọn jáde, ó sì sọ pé: 20  “Ẹ lọ dúró sínú tẹ́ńpìlì, kí ẹ sì máa sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn èèyàn.” 21  Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n wọ tẹ́ńpìlì ní àfẹ̀mọ́jú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. Nígbà tí àlùfáà àgbà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé, wọ́n pe Sàhẹ́ndìrìn àti gbogbo àpéjọ àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì ní kí wọ́n lọ mú àwọn àpọ́sítélì wá látinú ẹ̀wọ̀n. 22  Àmọ́ nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ dé ibẹ̀, wọn ò rí wọn nínú ẹ̀wọ̀n. Torí náà, wọ́n pa dà wá ròyìn, 23  wọ́n ní: “A bá ẹ̀wọ̀n ní títì pa, àwọn ẹ̀ṣọ́ dúró lẹ́nu àwọn ilẹ̀kùn, àmọ́ nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, a ò rí ẹnì kankan níbẹ̀.” 24  Tóò, nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn olórí àlùfáà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn wọn dà rú torí wọn ò mọ ohun tí èyí máa yọrí sí. 25  Àmọ́ ẹnì kan wá, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọkùnrin tí ẹ fi sẹ́wọ̀n wà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n dúró, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn.” 26  Ni olórí ẹ̀ṣọ́ bá lọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, ó sì mú àwọn àpọ́sítélì wọlé, àmọ́ kì í ṣe tipátipá, torí wọ́n ń bẹ̀rù kí àwọn èèyàn má lọ sọ wọ́n lókùúta.+ 27  Torí náà, wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì ní kí wọ́n dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn. Àlùfáà àgbà wá bi wọ́n ní ìbéèrè, 28  ó sì sọ pé: “A kìlọ̀ fún yín gidigidi pé kí ẹ má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí,+ síbẹ̀, ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù, ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sórí wa.”+ 29  Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù wá fún wọn lésì pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.+ 30  Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa gbé Jésù dìde, ẹni tí ẹ pa, tí ẹ sì gbé kọ́ òpó igi.*+ 31  Ọlọ́run gbé ẹni yìí ga sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ láti jẹ́ Olórí Aṣojú+ àti Olùgbàlà,+ kí ó lè mú kí Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+ 32  Àwa ni ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan yìí,+ bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀mí mímọ́,+ èyí tí Ọlọ́run fún àwọn tó ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí alákòóso.” 33  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n gbaná jẹ,* wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n dà nù. 34  Àmọ́ Farisí kan tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì + dìde nínú Sàhẹ́ndìrìn; olùkọ́ Òfin tí gbogbo èèyàn kà sí ni, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú àwọn ọkùnrin náà lọ síta fúngbà díẹ̀. 35  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ ro ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkùnrin yìí dáadáa o. 36  Bí àpẹẹrẹ, ní ìjelòó, Téúdásì dìde, ó sọ pé èèyàn pàtàkì ni òun, àwọn bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) èèyàn sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. Àmọ́ wọ́n pa á dà nù, gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé e tú ká, wọ́n sì dàwátì. 37  Lẹ́yìn rẹ̀, Júdásì ará Gálílì dìde ní àkókò ìforúkọsílẹ̀, ó sì fa àwọn èèyàn sẹ́yìn ara rẹ̀. Ọkùnrin yẹn náà ṣègbé, gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé e sì tú ká. 38  Nítorí náà, níbi tọ́rọ̀ dé yìí, màá sọ fún yín pé kí ẹ má tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Torí tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ èèyàn ni ète tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; 39  àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ ò ní lè bì wọ́n ṣubú.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ kàn rí i pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run jà ni.”+ 40  Ni wọ́n bá gba ìmọ̀ràn rẹ̀, wọ́n sì pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba,*+ wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́, wọ́n wá fi wọ́n sílẹ̀. 41  Torí náà, wọ́n jáde kúrò níwájú Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n ń yọ̀+ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù. 42  Lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé,+ wọ́n ń kọ́ni láìdábọ̀, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí “Ìloro.”
Tàbí “wọ́n jowú.”
Tàbí “mú àwọn àpọ́sítélì.”
Tàbí “igi.”
Tàbí “ó dùn wọ́n wọra.”
Tàbí “wọ́n lù wọ́n.”