Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 11:1-19

 • Àwọn ẹlẹ́rìí méjì (1-13)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ fún 1,260 ọjọ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ (3)

  • Wọ́n pa wọ́n, àmọ́ wọn ò sin wọ́n (7-10)

  • Wọ́n pa dà wà láàyè lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ (11, 12)

 • Ìyọnu kejì kọjá, ìkẹta ń bọ̀ (14)

 • Kàkàkí keje (15-19)

  • Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀ (15)

  • Ó máa run àwọn tó ń run ayé (18)

11  A sì fún mi ní esùsú* kan tó dà bí ọ̀pá*+ bó ṣe ń sọ pé: “Dìde, kí o wọn ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀.  Àmọ́ ní ti àgbàlá tó wà ní ìta ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, fi sílẹ̀, má sì wọ̀n ọ́n, torí a ti fún àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì máa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ ìlú mímọ́ náà+ mọ́lẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì+ (42).  Màá mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì fi ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ (1,260) sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.”*  Àwọn yìí ni igi ólífì méjì+ àti ọ̀pá fìtílà méjì ṣàpẹẹrẹ,+ wọ́n dúró síwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.+  Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná á jáde láti ẹnu wọn, á sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Bí a ṣe máa pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ pa wọ́n lára nìyí.  Àwọn yìí ní àṣẹ láti sé òfúrufú* pa+ kí òjò kankan má bàa rọ̀+ ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ní àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀+ àti láti fi gbogbo oríṣiríṣi ìyọnu kọ lu ayé ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́.  Nígbà tí wọ́n bá jẹ́rìí tán, ẹranko tó jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ máa bá wọn jagun, ó máa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa pa wọ́n.+  Òkú wọn sì máa wà lójú ọ̀nà ìlú ńlá náà, èyí tí wọ́n ń pè ní Sódómù àti Íjíbítì lọ́nà ti ẹ̀mí, níbi tí wọ́n ti kan Olúwa wọn pẹ̀lú mọ́gi.  Àwọn kan látinú àwọn èèyàn àti àwọn ẹ̀yà àti àwọn ahọ́n* àti àwọn orílẹ̀-èdè máa fi ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀+ wo òkú wọn, wọn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n tẹ́ òkú wọn sínú ibojì. 10  Àwọn tó ń gbé ní ayé yọ̀ torí wọn, wọ́n ṣe àjọyọ̀, wọ́n sì máa fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn, torí pé àwọn wòlíì méjì yìí ti dá àwọn tó ń gbé ayé lóró. 11  Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọnú wọn,+ wọ́n dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù sì ba àwọn tó rí wọn gidigidi. 12  Wọ́n wá gbọ́ ohùn kan tó ké jáde sí wọn láti ọ̀run pé: “Ẹ máa bọ̀ lókè níbí.” Wọ́n sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú àwọsánmà,* àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn.* 13  Ní wákàtí yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀, ìdá mẹ́wàá ìlú náà sì ṣubú; ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ni ìmìtìtì ilẹ̀ náà pa, ẹ̀rù sì ba àwọn yòókù, wọ́n yin Ọlọ́run ọ̀run lógo. 14  Ìyọnu kejì+ ti kọjá. Wò ó! Ìyọnu kẹta ń bọ̀ kíákíá. 15  Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+ 16  Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọ́run dojú bolẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, 17  wọ́n ní: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè, ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ torí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti ń jọba.+ 18  Àmọ́ inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ náà sì bínú, àkókò wá tó láti ṣèdájọ́ àwọn òkú àti láti san èrè+ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ àti àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn tó ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá àti láti run àwọn tó ń run ayé.”*+ 19  A ṣí ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní ọ̀run, a sì rí àpótí májẹ̀mú rẹ̀ nínú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì rẹ̀.+ Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a sì gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé, òjò yìnyín rẹpẹtẹ sì rọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọ̀pá ìdíwọ̀n.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọ̀run.”
Tàbí “àwọn èdè.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “sì ń wò wọ́n.”
Tàbí “láti pa àwọn tó ń pa ayé run.”