Àkọsílẹ̀ Lúùkù 23:1-56

  • Jésù wà níwájú Pílátù àti Hẹ́rọ́dù (1-25)

  • Wọ́n kan Jésù àti àwọn ọ̀daràn méjì mọ́gi (26-43)

    • “O máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè” (43)

  • Ikú Jésù (44-49)

  • Wọ́n sìnkú Jésù (50-56)

23  Torí náà, èrò rẹpẹtẹ náà gbéra, gbogbo wọn pátá, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù.+  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án+ pé: “A rí i pé ọkùnrin yìí fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé, ó ní ká má ṣe san owó orí fún Késárì,+ ó sì ń pe ara rẹ̀ ní Kristi ọba.”+  Pílátù wá bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Ó fèsì pé: “Òun ni ìwọ fúnra rẹ ń sọ yẹn.”+  Pílátù wá sọ fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn èrò náà pé: “Mi ò rí ìwà ọ̀daràn kankan tí ọkùnrin yìí hù.”+  Àmọ́ wọn ò gbà, wọ́n ń sọ pé: “Ó ń ru àwọn èèyàn sókè ní ti pé ó ń kọ́ wọn káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí dé ibí yìí pàápàá.”  Nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó béèrè bóyá ará Gálílì ni ọkùnrin náà.  Lẹ́yìn tó rí i dájú pé abẹ́ àṣẹ Hẹ́rọ́dù ló wà, ó ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù,+ tí òun náà wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn.  Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí Jésù, inú rẹ̀ dùn gan-an. Ó ti pẹ́ tó ti fẹ́ rí Jésù torí ó ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa rẹ̀,+ ó sì ń retí pé kí òun rí i kó ṣiṣẹ́ àmì díẹ̀.  Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó, àmọ́ kò dá a lóhùn rárá.+ 10  Síbẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń dìde ṣáá, wọ́n sì ń fẹ̀sùn kàn án kíkankíkan. 11  Hẹ́rọ́dù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá kàn án lábùkù,+ ó wọ aṣọ tó rẹwà fún un láti fi ṣe ẹlẹ́yà,+ ó sì ní kí wọ́n mú un pa dà sọ́dọ̀ Pílátù. 12  Ọjọ́ yẹn gan-an ni Hẹ́rọ́dù àti Pílátù di ọ̀rẹ́, torí ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀tá ni àwọn méjèèjì jẹ́ síra wọn. 13  Pílátù wá pe àwọn olórí àlùfáà, àwọn alákòóso àti àwọn èèyàn jọ, 14  ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú ọkùnrin yìí wá sọ́dọ̀ mi pé ó ń mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀. Ẹ wò ó! Mo yẹ̀ ẹ́ wò níwájú yín, àmọ́ mi ò rí ẹ̀rí pé ọkùnrin yìí jẹ̀bi ìkankan nínú ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án.+ 15  Kódà, Hẹ́rọ́dù náà ò rí ẹ̀rí, torí ó dá a pa dà sọ́dọ̀ wa, ẹ wò ó! kò ṣe ohunkóhun tí ikú fi tọ́ sí i. 16  Torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́,+ màá sì tú u sílẹ̀.” 17  * —— 18  Àmọ́ gbogbo èrò kígbe pé: “Pa ọkùnrin yìí dà nù,* kí o sì tú Bárábà sílẹ̀ fún wa!”+ 19  (Wọ́n ti fi ọkùnrin yìí sẹ́wọ̀n torí ìdìtẹ̀ sí ìjọba tó wáyé nínú ìlú náà àti nítorí ìpànìyàn.) 20  Pílátù tún gbóhùn sókè bá wọn sọ̀rọ̀, torí ó fẹ́ tú Jésù sílẹ̀.+ 21  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”*+ 22  Ó sọ fún wọn lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Mi ò rí ohunkóhun tó ṣe tí ikú fi tọ́ sí i; torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́, màá sì tú u sílẹ̀.” 23  Ni wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé àfi kó pa á,* ọ̀rọ̀ wọn ló sì borí.+ 24  Torí náà, Pílátù pinnu pé òun máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. 25  Ó tú ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìpànìyàn, àmọ́ ó fa Jésù lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i. 26  Bí wọ́n ṣe ń mú un lọ, wọ́n mú ẹnì kan, ìyẹn Símónì ará Kírénè, ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, wọ́n sì gbé òpó igi oró* náà lé e pé kó gbé e tẹ̀ lé Jésù.+ 27  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé e, títí kan àwọn obìnrin tó ń lu ara wọn ṣáá torí ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún nítorí rẹ̀. 28  Jésù yíjú sí àwọn obìnrin náà, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, ẹ má sunkún torí mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ sunkún torí ara yín àti àwọn ọmọ yín;+ 29  torí ẹ wò ó! ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn èèyàn máa sọ pé, ‘Aláyọ̀ ni àwọn àgàn, àwọn ilé ọlẹ̀ tí kò bímọ àti àwọn ọmú tí ọmọ kò mu!’+ 30  Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn òkè ńláńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’+ 31  Tí wọ́n bá ṣe àwọn nǹkan yìí nígbà tí igi ṣì tutù, kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá rọ?” 32  Wọ́n tún ń mú àwọn ọkùnrin méjì míì tí wọ́n jẹ́ ọ̀daràn lọ, kí wọ́n lè pa wọ́n pẹ̀lú rẹ̀.+ 33  Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń pè ní Agbárí,+ wọ́n kàn án mọ́gi níbẹ̀, àwọn ọ̀daràn náà sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 34  Àmọ́ Jésù ń sọ pé: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Bákan náà, wọ́n ṣẹ́ kèké láti fi pín aṣọ rẹ̀.+ 35  Àwọn èèyàn sì dúró, wọ́n ń wòran. Àmọ́ àwọn alákòóso ń yínmú, wọ́n ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kó gba ara rẹ̀ là tó bá jẹ́ òun ni Kristi ti Ọlọ́run, Àyànfẹ́.”+ 36  Àwọn ọmọ ogun pàápàá fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n wá, wọ́n sì fún un ní wáìnì kíkan,+ 37  wọ́n ń sọ pé: “Tó bá jẹ́ ìwọ ni Ọba Àwọn Júù, gba ara rẹ là.” 38  Àkọlé kan tún wà lórí rẹ̀ pé: “Ọba Àwọn Júù nìyí.”+ 39  Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n gbé kọ́ síbẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í bú u+ pé: “Ṣebí ìwọ ni Kristi, àbí ìwọ kọ́? Gba ara rẹ là, kí o sì gba àwa náà là!” 40  Ẹnì kejì bá a wí, ó sọ fún un pé: “Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, ní báyìí tó jẹ́ pé ìdájọ́ kan náà nìwọ náà gbà? 41  Ó tọ́ sí àwa, torí pé ohun tó yẹ wá là ń gbà yìí torí àwọn ohun tí a ṣe; àmọ́ ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó burú.” 42  Ó wá sọ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.”+ 43  Ó sì sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”+ 44  Ó ti tó nǹkan bíi wákàtí kẹfà* báyìí, síbẹ̀ òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án,*+ 45  torí pé oòrùn ò ràn; aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ wá ya délẹ̀ ní àárín.+ 46  Jésù sì ké jáde, ó sọ pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.*+ 47  Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, ó ní: “Ní tòótọ́, olódodo ni ọkùnrin yìí.”+ 48  Nígbà tí gbogbo èrò tó kóra jọ síbẹ̀ láti wòran rí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀, wọ́n pa dà sílé, wọ́n ń lu àyà wọn. 49  Gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́n sì dúró ní ọ̀ọ́kán. Bákan náà, àwọn obìnrin tó tẹ̀ lé e láti Gálílì wà níbẹ̀, wọ́n rí àwọn nǹkan yìí.+ 50  Wò ó! ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Jósẹ́fù, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ ni, èèyàn dáadáa ni, ó sì jẹ́ olódodo.+ 51  (Ọkùnrin yìí ò tì wọ́n lẹ́yìn nígbà tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí wọ́n ṣe.) Arimatíà, ìlú àwọn ará Jùdíà, ló ti wá, ó sì ń retí Ìjọba Ọlọ́run. 52  Ọkùnrin yìí wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kí wọ́n gbé òkú Jésù fún òun. 53  Ó wá gbé e sọ̀ kalẹ̀,+ ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa* dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta,+ tí wọn ò tẹ́ ẹnì kankan sí rí. 54  Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́+ ni, Sábáàtì+ ò sì ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀. 55  Àmọ́ àwọn obìnrin tó bá a wá láti Gálílì tẹ̀ lé e lọ, wọ́n yọjú wo ibojì* náà, wọ́n sì rí i bí wọ́n ṣe tẹ́ òkú rẹ̀,+ 56  wọ́n wá pa dà lọ pèsè èròjà tó ń ta sánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà. Àmọ́ wọ́n sinmi ní Sábáàtì+ bí a ṣe pa á láṣẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “Mú ẹni yìí lọ.”
Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kàn án mọ́gi.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “ó mí èémí àmíkẹ́yìn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”