Lẹ́tà sí Àwọn Ará Kólósè 2:1-23

  • Kristi, àṣírí mímọ́ Ọlọ́run (1-5)

  • Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn ẹlẹ́tàn (6-15)

  • Ohun gidi náà ni Kristi (16-23)

2  Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí ìsapá mi ṣe pọ̀ tó lórí yín, lórí àwọn tó wà ní Laodíkíà+ àti lórí gbogbo àwọn tí kò tíì rí mi lójúkojú.*  Èyí jẹ́ kí a lè tu ọkàn wọn lára,+ kí a lè so wọ́n pọ̀ di ọ̀kan nínú ìfẹ́,+ kí wọ́n sì lè ní gbogbo ọrọ̀ tó ń wá látinú òye wọn tó dájú hán-ún, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tó péye nípa àṣírí mímọ́ Ọlọ́run, ìyẹn Kristi.+  Inú rẹ̀ ni a fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.+  Mò ń sọ èyí kí ẹnì kankan má bàa fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ.  Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nínú ara, mo wà pẹ̀lú yín nínú ẹ̀mí, inú mi ń dùn bí mo ṣe ń rí i pé ẹ wà létòlétò,+ ìgbàgbọ́ yín sì fìdí múlẹ̀ nínú Kristi.+  Nítorí náà, bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa rìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀,  kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì máa dàgbà nínú rẹ̀,+ kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,+ bí a ṣe kọ́ yín, kí ẹ sì máa kún fún ọpẹ́.+  Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán+ mú yín lẹ́rú* látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn, nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kì í ṣe nínú Kristi;  torí pé inú rẹ̀ ni gbogbo ànímọ́* Ọlọ́run pé sí.+ 10  Torí náà, ẹ ti ní ohun gbogbo nípasẹ̀ rẹ̀, ẹni tó jẹ́ orí gbogbo ìjọba àti àṣẹ.+ 11  Àjọṣe tí ẹ ní pẹ̀lú rẹ̀ ti mú kí a dádọ̀dọ́* ẹ̀yin náà pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́* tí a kò fi ọwọ́ ṣe nípa bíbọ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+ ìyẹn ìdádọ̀dọ́ tó jẹ́ ti Kristi.+ 12  A sin yín pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìbatisí rẹ̀,+ àjọṣe tí ẹ sì ní pẹ̀lú rẹ̀ mú kí a gbé ẹ̀yin náà dìde+ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú iṣẹ́ agbára Ọlọ́run, ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú.+ 13  Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́* ẹran ara yín, Ọlọ́run mú kí ẹ wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú,+ 14  ó pa ìwé àfọwọ́kọ rẹ́,*+ èyí tí àwọn àṣẹ wà nínú rẹ̀,+ tó sì lòdì sí wa.+ Ó mú un kúrò lọ́nà bí ó ṣe kàn án mọ́ òpó igi oró.*+ 15  Ó ti tú àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ sí borokoto, ó fi wọ́n hàn ní gbangba pé a ti ṣẹ́gun wọn,+ ó ń fi òpó igi oró* darí wọn lọ nínú ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun. 16  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan dá yín lẹ́jọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń mu+ tàbí lórí àjọyọ̀ kan tí ẹ ṣe tàbí òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.+ 17  Àwọn nǹkan yẹn jẹ́ òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀,+ àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.+ 18  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mú kí ẹ̀bùn náà bọ́ mọ́ yín lọ́wọ́,+ ẹni tó fẹ́ràn ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀tàn àti ọ̀nà ìjọsìn àwọn áńgẹ́lì, “tó dúró lórí”* àwọn ohun tó ti rí. Ní tòótọ́, kò sídìí tó fi yẹ kó gbéra ga, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó ń ronú lọ́nà ti ara, 19  kò sì di orí náà mú ṣinṣin,+ ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ara fi ń rí ohun tó nílò, tó sì so gbogbo rẹ̀ pọ̀ di ọ̀kan nípasẹ̀ àwọn oríkèé àti àwọn iṣan tó de eegun pọ̀, tó ń mú kó máa dàgbà sókè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.+ 20  Bí ẹ bá ti kú pẹ̀lú Kristi nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé,+ kí ló dé tí ẹ̀ ń gbé ìgbé ayé yín bíi pé ẹ ṣì jẹ́ apá kan ayé bí ẹ ṣe ń fi ara yín sábẹ́ àwọn àṣẹ tó sọ pé:+ 21  “Má dì í mú, má tọ́ ọ wò, má fọwọ́ kàn án,” 22  ní ti gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣègbé lẹ́yìn lílò, gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látọwọ́ èèyàn ṣe sọ?+ 23  Bó tiẹ̀ dà bíi pé àwọn nǹkan yẹn bọ́gbọ́n mu, ṣe ni àwọn tó ń ṣe wọ́n yan ọ̀nà ìjọsìn tiwọn fúnra wọn. Wọ́n ń fìyà jẹ ara wọn+ torí wọ́n fẹ́ kí àwọn èèyàn máa rò pé àwọn nírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yẹn kò ní àǹfààní kankan téèyàn bá fẹ́ borí ìfẹ́ ti ara.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “rí ojú mi nínú ẹran ara.”
Tàbí “gbé yín lọ bí ẹran tí a mú.”
Ìyẹn, ìwà àti ìṣe.
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “àìkọlà.”
Tàbí “wọ́gi lé ìwé àfọwọ́kọ.”
Tàbí kó jẹ́, “òun fúnra rẹ̀ ń.”
Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ẹ̀kọ́ àdììtú àwọn abọ̀rìṣà.