Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Tó Ní Àǹfààní Wíwà Pẹ́ Títí

Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Tó Ní Àǹfààní Wíwà Pẹ́ Títí

Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Tó Ní Àǹfààní Wíwà Pẹ́ Títí

ÌGBÀ gbogbo ni Jésù Kristi ń ṣàánú àwọn tíyà ń jẹ. Fún àpẹẹrẹ, ó bọ́ àwọn tébi ń pa ó sì wo àwọn aláìsàn sàn. (Mátíù 14:14-21) Àmọ́, iṣẹ́ wo gan an ló mú ní ọ̀kúnkúndùn? Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí. Àkọsílẹ̀ yìí wà ní orí àkọ́kọ́ ìwé Ìhìn Rere Máàkù.

Nígbà tí Jésù wà ní Kápánáúmù, nítòsí Òkun Gálílì, wọ́n mú un lọ sí ilé Símónì, tàbí Pétérù. Níbẹ̀, àrùn ‘ibà dá ìyá ìyàwó Símónì dùbúlẹ̀,’ Jésù sì wò ó sàn. (Máàkù 1:29-31) Lẹ́yìn ìgbà náà, lèrò rẹpẹtẹ, títí kan àwọn èèyàn “tí onírúurú àìsàn ń mú kí wọ́n ṣàmódi” bá bẹ̀rẹ̀ sí í péjọ sẹ́nu ọ̀nà ilé Pétérù, Jésù sì wo àwọn náà sàn. (Máàkù 1:32-34) Nígbà tílẹ̀ ṣú, oníkálùkù lọ sùn.

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì “nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́,” Jésù rọra yọ́ dìde ó sì jáde nínú ilé náà lọ “sí ibi tí ó dá,” níbi tó ti “bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà.” Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà jí, wọ́n wo ìta, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tí wọ́n ń dúró lẹ́nu ọ̀nà. Kí ni wọ́n máa ṣe báyìí o? Wọn ò rí Jésù! Kíá, Pétérù àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá Jésù rí wọ́n sì sọ fún un pé: “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ.” (Máàkù 1:35-37; Lúùkù 4:42) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ fún Jésù pé: ‘Èwo lò ń ṣe níbí yìí kẹ̀? Lálẹ́ àná, ó ṣàṣeyọrí ńláǹlà nínú iṣẹ́ ìwòsàn tóo ṣe fáwọn aláìsàn. Lónìí báyìí, àǹfààní bàǹtàbanta tún ti ń dúró dè ọ́!’

Àmọ́ wo bí Jésù ṣe dáhùn ná: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú.” Ọ̀rọ̀ ki sínú èsì tó fún wọn yìí o. Jésù kò padà sí ilé Pétérù mọ́ láti tún lọ wo àwọn mìíràn sàn. Ó fi ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ hàn nígbà tó sọ pé: “Nítorí fún ète yìí [ìyẹn láti wàásù] ni mo ṣe jáde lọ.” (Máàkù 1:38, 39; Lúùkù 4:43) Kí ni Jésù ń sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ná? Ṣíṣe oore jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì lójú rẹ̀, àmọ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni olórí iṣẹ́ táa rán Jésù.—Máàkù 1:14.

Níwọ̀n bí Bíbélì sì ti rọ àwọn Kristẹni láti “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ [Jésù] pẹ́kípẹ́kí,” ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere wà fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní nígbà tó bá kan èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni. (1 Pétérù 2:21) Bíi ti Jésù, wọ́n máa ń ran àwọn èèyàn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́—gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ti jẹ́ ká mọ̀. Bákan náà bíi ti Jésù, iṣẹ́ kíkọ́ni ní ìhìn Bíbélì nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fi ṣíwájú. a (Mátíù 5:14-16; 24:14; 28:19, 20) Àmọ́, ìdí wo ló fi yẹ kí yíyọ̀ǹda ara ẹni láti kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú Bíbélì jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni pàtàkì tó kù?

Ìdí Tí Ẹ̀kọ́ Bíbélì Fi Ṣàǹfààní àti Ọ̀nà Tó Gbà Rí Bẹ́ẹ̀

Òwe àwọn ará Éṣíà kan fúnni ní ìdáhùn náà. Ó sọ pé: “Bóo bá ń wéwèé ohun tóo máa fi ọdún kan ṣe, lọ dáko. Bó bá jẹ́ ọdún mẹ́wàá ni, igi ni kóo gbìn. Bó bá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ọdún ni, kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.” Kò sí àní-àní pé, tó bá dọ̀rọ̀ ká pèsè ojútùú tó máa wà pẹ́ títí, pàtàkì ni ẹ̀kọ́ jẹ́, nítorí pé ó ń ran èèyàn lọ́wọ́ láti lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Ìdí rèé o, tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni alákòókò díẹ̀ àti alákòókò kíkún tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà fi ń lo àkókò wọn, okun wọn, àtàwọn ohun ìní wọn láti pèsè ẹ̀kọ́ Bíbélì fún gbogbo èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́. Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe yìí tí ẹ̀rí sì fi hàn pé ó gbéṣẹ́ ń nípa lórí àwọn èèyàn yíká ayé. Lọ́nà wo?

Bí wọ́n ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní òye Bíbélì kí wọ́n sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn gidi inú rẹ̀, ó ń mú kí wọ́n lè túbọ̀ kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Wọ́n ń rí okun gbà láti hùwà rere, ìyẹn ohun tí wọ́n nílò láti borí àwọn àṣà tó ń pani lára. Nelson, ọ̀dọ́ kan tó ń gbé ní Brazil tún sọ àǹfààní mìíràn tí ẹ̀kọ́ Bíbélì ń fúnni, ó ní: “Àtìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti ń láyọ̀ nítorí pé ìgbésí ayé mi ti wá nítumọ̀ báyìí.” (Oníwàásù 12:13) Ọ̀rọ̀ ẹgbàágbèje èèyàn mìíràn, lọ́mọdé lágbà, tí àwọn náà ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́nu àìpẹ́ yìí kò tàsé ti Nelson. Yàtọ̀ sí pé ìhìn Ìjọba Ọlọ́run máa ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀, ó tún ń fúnni ní ìrètí amóríyá nípa ọjọ́ ọ̀la, ìyẹn ìrètí tó ń mú kí ìgbésí ayé wu èèyàn láti gbé, kódà ká tiẹ̀ ní èèyàn wà nínú ipò tó le koko. (1 Tímótì 4:8)—Wo àpótí náà, “Àwọn Àǹfààní Tí Ìjọba Ọlọ́run Á Mú Wá.”

Nípa kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kan tí àǹfààní rẹ̀ máa wà pẹ́ títí. Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ìwọ fojú inú wo kíkópa nínú iṣẹ́ kan tí àǹfààní rẹ̀ jẹ́ títí ayérayé—lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí o, kò tún sí iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn tó ṣàǹfààní ju ìyn lọ! Ṣe ìyẹn kọ́ ni irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wàá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bí o bá ṣiṣẹ́ lórí ìkésíni yìí, o ò ní kábàámọ̀ rẹ̀ láé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú ojú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wo iṣẹ́ wíwàásù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fi wò ó, pé ohun tó pọndandan ni fáwọn Kristẹni tòótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere, kì í ṣe ìdí kankan fún mi láti ṣògo, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi.” (1 Kọ́ríńtì 9:16) Síbẹ̀síbẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù wọn jẹ́ èyí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti ṣe nítorí pé fúnra wọn ni wọ́n yàn láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n sì mọ̀ dájú pé ẹrù iṣẹ́ wà nídìí àǹfààní yẹn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Bóo bá ń wéwèé ohun tóo máa fi ọdún kan ṣe, lọ dáko. Bó bá jẹ́ ọdún mẹ́wàá ni, igi ni kóo gbìn. Bó bá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ọdún ni, kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ó Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́, Ó Tún Ń Fún Wọn Nírètí

Nadine, nọ́ọ̀sì ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì kan láti ilẹ̀ Faransé tó mọ ìtọ́jú àwọn àrùn tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ olóoru ní àmọ̀dunjú wà lára àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ṣiṣẹ́ ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà. Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láìpẹ́ yìí, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń bi mí léèrè pé kí lohun tó ń mú mi ṣe èyí. Mo nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; mo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, mo sì fẹ́ lo ara mi láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Pé mo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń sún mi láti máa ran àwọn tí ìyà ń jẹ lọ́wọ́ àti láti máa fún wọn nírètí.” Bí Nadine ti ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ ní Áfíríkà, ó tún ń lò lára àkókò rẹ̀ fún iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ń ṣe.

[Àwọn àwòrán]

Nadine ní Áfíríkà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn Àǹfààní Tí Ìjọba Ọlọ́run Á Mú Wá

Jọ̀wọ́, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí nínú Bíbélì rẹ kóo sì rí bí Ọlọ́run ṣe ṣèlérí pé òun á bójú tó ìṣòro ènìyàn láwọn apá ibi wọ̀nyí:

Ìlera “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”Ìṣípayá 21:4; Aísáyà 33:24; 35:5, 6.

Ìmọ̀ “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”Aísáyà 11:9; Hábákúkù 2:14.

Rírí Iṣẹ́ ṢeDájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán.”Aísáyà 65:21-23.

Oúnjẹ “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”Sáàmù 67:6; 72:16; Aísáyà 25:6.

Ìṣòro Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà “Jèhófà ti ṣẹ́ ọ̀pá àwọn ẹni burúkú . . . Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu.”Aísáyà 14:5, 7.

Ìdájọ́ Òdodo “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.”Aísáyà 11:3-5; 32:1, 2.