Hábákúkù 2:1-20
2 Ibi tí mo ti ń ṣe olùṣọ́ ni èmi yóò dúró sí,+Èmi yóò sì dúró lórí odi ààbò.
Èmi yóò máa ṣọ́nà kí n lè mọ ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ miÀti ohun tí èmi yóò sọ nígbà tó bá bá mi wí.
2 Jèhófà wá dá mi lóhùn pé:
“Kọ ìran náà sílẹ̀, kí o sì kọ ọ́ sára wàláà,+ kó hàn kedere,Kí ẹni tó ń kà á sókè lè rí i kà dáadáa.*+
3 Àkókò tí ìran náà máa ṣẹ kò tíì tó,Ó ń yára sún mọ́lé,* kò sì ní lọ láìṣẹ.
Tó bá tiẹ̀ falẹ̀,* ṣáà máa retí rẹ̀!*+
Torí yóò ṣẹ láìkùnà.
Kò ní pẹ́ rárá!
4 Wo ẹni tó ń gbéra ga;*Kì í ṣe olóòótọ́ nínú ọkàn rẹ̀.
Àmọ́ ìṣòtítọ́* yóò mú kí olódodo wà láàyè.+
5 Torí pé wáìnì ń tanni jẹ lóòótọ́,Ọwọ́ ẹni tó jọ ara rẹ̀ lójú kò ní tẹ àfojúsùn rẹ̀.
Kì í* ní ìtẹ́lọ́rùn bí Isà Òkú;*Ó dà bí ikú, kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn.
Ó ń kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ,Ó sì ń kó gbogbo èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀.+
6 Ṣé kì í ṣe gbogbo wọn ló máa pa òwe, àṣamọ̀ àti àlọ́ láti bá a jà?+
Wọ́n á sọ pé:
‘Ẹni tó ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ gbé!
Tó sì ń mú kí gbèsè ọrùn rẹ̀ pọ̀ sí i.
Ìgbà wo ló máa ṣe èyí dà?
7 Ǹjẹ́ àwọn tó yá ọ lówó kò ní dìde sí ọ lójijì?
Wọ́n á ta jí, wọ́n á sì fipá mì ọ́ jìgìjìgì,Wọ́n á sì kó ọ bí ẹrù tí wọ́n kó dé látojú ogun.+
8 Torí ìwọ náà ti kó ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lẹ́rù,Gbogbo èèyàn yóò kó ọ lẹ́rù,+Nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tí o ta sílẹ̀
Àti ìwà ipá tí o hù sí ayé,Sí àwọn ìlú àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+
9 Ẹni tó ń kó èrè tí kò tọ́ jọ fún ilé rẹ̀ gbé!
Kó lè kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ibi gíga,Kó má bàa kó sínú àjálù.
10 O ti gbèrò ohun tó kó ìtìjú bá ilé rẹ.
O ṣẹ̀ sí ara* rẹ bí o ṣe pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.+
11 Òkúta yóò ké jáde láti inú ògiri,Igi ìrólé yóò sì dá a lóhùn látorí àjà.
12 Ẹni tó ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ ìlú gbé,Àti ẹni tó ń fi àìṣòdodo tẹ ìlú dó!
13 Wò ó! Ṣé kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló ń mú kí àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ kára fún ohun tó ṣì máa jóná,Tó sì ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe wàhálà lásán?+
14 Torí gbogbo ayé yóò ní ìmọ̀ nípa ògo Jèhófà
Bí ìgbà tí omi bo òkun.+
15 Ẹni tó ń fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní nǹkan mu gbé!
Tó ń fi ìbínú àti ìkanra ṣe é, kó lè mú kí wọ́n yó,Kó lè wo ìhòòhò wọn!
16 Àbùkù ni wọn yóò fi kàn ọ́ dípò ògo.
Ìwọ náà mu ún, kí o sì ṣí adọ̀dọ́ rẹ tí wọn ò dá sí gbangba.*
Ife ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà yóò dé ọ̀dọ̀ rẹ,+Ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ mọ́lẹ̀;
17 Torí ìwà ipá tí o hù sí Lẹ́bánónì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀,Ìparun tó dẹ́rù ba àwọn ẹranko yóò dé bá ọ,Nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tí o ta sílẹ̀
Àti ìwà ipá tí o hù sí ayé,Sí àwọn ìlú àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+
18 Kí ni àǹfààní ère,Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?
Kí ni àǹfààní ère onírin* àti olùkọ́ èké,Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+
19 O gbé, ìwọ tí ò ń sọ fún igi pé: “Dìde!”
Tàbí fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀ pé: “Gbéra nílẹ̀! Máa kọ́ wa!”
Wò ó! Wúrà àti fàdákà ni wọ́n fi bò ó,+Kò sì sí èémí kankan nínú rẹ̀.+
20 Àmọ́ Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+
Gbogbo ayé, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀!’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “lọ́nà tó já geere.”
^ Tàbí “ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹ.”
^ Tàbí “dà bíi pé ó falẹ̀.”
^ Tàbí “máa fojú sọ́nà fún un.”
^ Tàbí “Wò ó! Ọkàn rẹ̀ ń wú fùkẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ìgbàgbọ́.”
^ Tàbí “Ọkàn rẹ̀ kì í.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kí o sì máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.”
^ Tàbí “ère dídà.”

