Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí a Ṣe Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkórìíra

Bí a Ṣe Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkórìíra

Bí a Ṣe Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkórìíra

“[Ẹ] máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.”—MÁTÍÙ 5:44.

Ọ̀PỌ̀ ọjọ́ làwọn olórí fún orílẹ̀-èdè méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá fi jíròrò lórí ọ̀nà àtiwá àlàáfíà. Olórí orílẹ̀-èdè kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nídìí ọrọ̀ ajé bá wọn dá sọ́rọ̀ ọ̀hún, ó lo ipò rẹ̀ àti ìmọ̀ tó ní nípa ìṣèlú láti fi bá wọn yanjú làásìgbò tó ń bẹ láàárín wọn. Àmọ́ kọ̀ ni gbogbo làálàá tí wọ́n ṣe já sí. Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré, orílẹ̀-èdè méjèèjì tún ti wà á kò, ìwé ìròyìn Newsweek pè é ní “ìwà ipá tó burú jù lọ tó tíì wáyé láàárín wọn láti ogún ọdún sẹ́yìn.”

Káàkiri ayé, ìkórìíra àti kèéta láàárín onírúurú ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè kò dópin pẹ̀lú gbogbo ìsapá ńláǹlà táwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè ń ṣe. Léraléra ni ìkórìíra ń fara hàn, ìwà àìmọ̀kan, àìfẹ́ gba èrò ẹlòmíràn, àti ìpolongo èké ló máa ń súnná sí i. Ńṣe làwọn aṣáájú òde òní ń dá oríṣiríṣi ọgbọ́n láti wá ojútùú sọ́ràn náà, àmọ́ wọ́n ti gbàgbé pé nǹkan ògbólógbòó kan báyìí ni ojútùú tó dára jù lọ, nǹkan ọ̀hún sì ti wà pẹ́ látìgbà Ìwàásù Lórí Òkè. Nínú ìwàásù yẹn, Jésù Kristi rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣe nǹkan ni kí wọ́n fi máa ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Ìgbà tó ń sọ̀rọ̀ yẹn ló sọ ọ̀rọ̀ táa fà yọ níbẹ̀rẹ̀. Ó ní, “[Ẹ] máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.” Kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ ìyànjú yẹn jẹ́ ojútùú sí ìṣòro ìkórìíra àti ẹ̀tanú nìkan ni, àmọ́ òun tún ni ojútùú kan oo tó wà!

Ńṣe làwọn oníyèméjì kàn ń fọwọ́ ti èrò pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àti pé kò tiẹ̀ ṣe é mú lò. Àmọ́ ṣá o, bí ìkórìíra bá jẹ́ ohun kan téèyàn kọ́, ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti gbà pé èèyàn lè kọ́ láti má ṣe kórìíra ni? Ìdí abájọ rèé táwọn ọ̀rọ̀ Jésù fi fún ọmọ aráyé ní ìrètí tó dájú. Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé kódà, ó ṣeé ṣe láti fòpin sí kèéta tó ti wà ńlẹ̀ látọdún gbọ́nhan.

Ronú nípa bí nǹkan ṣe rí láàárín àwọn Júù tí wọ́n tẹ́tí sí Jésù nígbà ayé rẹ̀. Ẹ̀yìnkùlé wọn làwọn ọ̀tá wọn wà. Àwọn ọmọ ogun Róòmù kò jẹ́ kí wọ́n rímú mí, wọ́n fagbára mú àwọn Júù sanwó orí rẹpẹtẹ, wọ́n ń fi ìṣèlú ṣe wọ́n báṣubàṣu, wọ́n ń lò wọ́n nílòkulò, wọ́n sì ń kó wọn nífà. (Mátíù 5:39-42) Àní ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn kan ti sọ àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn dọ̀tá torí èdè àìyedè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọ́n ti fi sílẹ̀ láìyanjú tó sì ti wá di ọ̀ràn ńlá. (Mátíù 5:21-24) Ṣó wá yẹ lóòótọ́ kí Jésù retí pé káwọn tóun ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ti pa wọ́n lára?

Ohun Tí “Ìfẹ́” Túmọ̀ Sí

Kọ́kọ́ fi sọ́kàn pé nígbà tí Jésù dárúkọ “ìfẹ́,” kì í ṣe irú èyí tó máa ń wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ló ń sọ. Ọrọ̀ Gíríìkì táa lò fún ìfẹ́ nínú Mátíù 5:44 wá látinú ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe. Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ìfẹ́ tí ìlànà ń darí tàbí táa gbé karí ìlànà. Kò fi dandan béèrè pé kó ní ìfẹ́ni ọlọ́yàyà nínú. Nítorí pé ìlànà òdodo ló ń darí rẹ̀, irú ìfẹ́ yẹn ń mú kéèyàn máa wá ire àwọn ẹlòmíràn, láìka ìwà tí wọn ì báà hù sí. Ìfẹ́ a·gaʹpe lè tipa bẹ́ẹ̀ borí ìbára ẹni ṣọ̀tá. Jésù fúnra rẹ̀ fi irú ìfẹ́ yìí hàn, dípò tí ì bá gbé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kàn án mọ́gi ṣépè, ńṣe ló gbàdúrà pé: “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Lúùkù 23:34.

Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa retí pé àwọn èèyàn á gbọ́ tí wọ́n á sì tẹ̀ lé gbogbo ẹ̀kọ́ Jésù pátápátá tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì? Rára o, torí Bíbélì fi hàn pé ńṣe layé yìí á máa burú sí i títí táá fi kàgbákò. Ìwé 2 Tímótì 3:13, sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” Àmọ́ ṣá o, nì kọ̀ọ̀kan lè jáwọ́ nídìí ìwà ìkórìíra bí wọ́n bá fara balẹ̀ kọ́ àwọn ìlànà òdodo nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àkọsílẹ̀ fi hàn kedere pé ọ̀pọ̀ ti kọ́ láti dènà ìwà ìkórìíra tó yí wọn ká lọ́tùn-ún lósì. Gbé àwọn bíi mélòó kan tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ yẹ̀ wò.

Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́

Àtìgbà tí José ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá ló ti ń bá wọn jagun abẹ́lẹ̀ torí pé ó wà nínú ẹgbẹ́ apániláyà. a Ohun tí wọ́n kọ́ ọ ni pé kó kórìíra àwọn èèyàn ti wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn ló fa ìṣègbè tó wà káàkiri. Ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé tó bá ṣeé ṣe, kóun pa wọ́n dànù. Rírí tí José rí ọ̀pọ̀ lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń kú mú kí inú bẹ̀rẹ̀ sí bí i, ó sì fẹ́ gbẹ̀san. Tó bá ń ṣe àwọn bọ́ǹbù kéékèèké lọ́wọ́, ó máa ń béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Èé ṣe tí ìrora fi pọ̀ tó báyìí? Bí Ọlọ́run bá wà, ṣé kì í róhun tó ń ṣẹlẹ̀ ni?’ Àìmọye ìgbà ló máa ń bú sẹ́kún, tí ilé ayé á sú u, ìbànújẹ́ á sì dorí rẹ̀ kodò.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, José rí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wà ládùúgbò rẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ tó lọ sípàdé ló ti rí bí ìfẹ́ ṣe jọba níbẹ̀. Tọ̀yàyàtọ̀yàyà ni gbogbo èèyàn fi kí i. Nígbà tó yá, ìjíròrò tó dá lórí kókó náà “Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìwà Ibi?” dáhùn àwọn ìbéèrè gan-an tó ń béèrè. b

Nígbà tó yá, bí ìmọ̀ tí José ń rí látinú Bíbélì ṣe ń pọ̀ sí i mú kó ṣe àwọn àtúnṣe nínú ìgbésí ayé rẹ̀ àti nínú ọ̀nà tó ń gbà ronú. Ó wá kẹ́kọ̀ọ́ pé “ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dúró nínú ikú. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra . . . jẹ́ apànìyàn, kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:14, 15.

Ìpèníjà ńláǹlà ló jẹ́ fún un láti fi àwọn apániláyà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí sílẹ̀. Gbogbo ìgbà tó bá ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní wọ́n máa ń gbá tọ̀ ọ́. Díẹ̀ lára wọn tiẹ̀ wá sí ìpàdé bíi mélòó kan láti lóye ohun tó mú kí José yí padà lọ́sàn-án gangan bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i pé kì í ṣe pé ó fẹ́ dà wọ́n tàbí kó bá wọn, ni wọ́n bá fi í lọ́rùn sílẹ̀. Nígbà tí José pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ṣèrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lójú méjèèjì. Dípò tí ì bá fi máa gbèrò àti pààyàn, ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ àti ìrètí ló kù tó ń mú tọ àwọn èèyàn lọ báyìí!

Pípa Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yà Tì Sẹ́gbẹ̀ẹ́ Kan

Ǹjẹ́ àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà lè mú ìkórìíra tó ti pààlà sáàárín wọn kúrò? Ìwọ wo ti àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè Amharic ní London, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn èèyàn bíi márùndínlógójì ló wà nínú àwùjọ yìí, ogún lára wọn jẹ́ ará Etiópíà nígbà tí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sì jẹ́ ará Eritrea. Pẹ̀lú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ni wọ́n fi ń jọ́sìn pa pọ̀ láìka ti pé àwọn ará Eritrea àti Etiópíà ja ogun tó gbóná janjan kan láìpẹ́ yìí ní Áfíríkà.

Ará Etiópíà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni ìdílé rẹ̀ ti sọ fún nígbà kan rí pé: ‘Má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ará Eritrea láéláé!’ Àmọ́ ní báyìí, kì í ṣe pé ó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará Eritrea nìkan ni, ó tún ń pè wọ́n ní arákùnrin àti arábìnrin! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Tigrinya làwọn ará Eritrea yìí ń sọ, wọ́n dìídì lọ kọ́ èdè Amharic, ìyẹn èdè àwọn arákùnrin wọn ọmọ ilẹ̀ Etiópíà kí wọ́n ba lè jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí ńlá gbáà lèyí jẹ́ nípa agbára tí ìfẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run ní, èyí tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé”!—Kólósè 3:14.

Ẹ Jẹ́ Ká Gbàgbé Ọ̀rọ̀ Àná

Àmọ́ ká wá sọ pé ẹnì kan ti hùwà àìtọ́ síni tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ṣé ohun kan burú nínú kéèyàn máa ṣe gbúngbùngbún sáwọn tó ń fìyà jẹni? Wo ti Manfred tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti Jámánì. Ọdún mẹ́fà gbáko ló lò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Kọ́múníìsì nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ǹjẹ́ ó fìgbà kan ronú pé kóun kórìíra àwọn tó fojú òun rí màbo yìí tàbí pé kóun gbẹ̀san? Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Jámánì náà Saarbrücker Zeitung ṣe sọ, Manfred ṣàlàyé pé: “Béèyàn bá ní òun fẹ́ hùwà àìdáa tàbí gbẹ̀san . . . látìgbàdégbà ni ohun téèyàn dá sílẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn á máa yọrí sí àìdáa mìíràn.” Ó ṣe kedere pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” ni Manfred ń fi sílò.—Róòmù 12:17, 18.

Ayé Kan Tí Kò Ní Sí Ìkórìíra!

Kì í ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ pé àwọn làwọn gbọ́n tán táwọn mọ̀ tán lórí ọ̀rọ̀ yìí o. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn náà máa ń rí i pé kì í rọrùn láti mú kèéta tó ti ń jà ràn-ìn tipẹ́ àti ìkórìíra kúrò. Ó máa ń gba ìsapá àṣekára téèyàn á sì máa ṣe ní àṣetúnṣe láti fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé. Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Bíbélì lágbára láti fòpin sí ìwà ìkórìíra. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé láti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́wọ́ lọ́dọọdún láti jáwọ́ nínú ìwà ẹ̀yà tèmi lọ̀gá àti ìwà àìfẹ́ gba èrò ẹlòmíràn. c (Wo àpótí náà “Ìmọ̀ràn Bíbélì Ń Lé Ìkórìíra Lọ Ráúráú.”) Àṣeyọrí ọ̀hún ń ṣàpẹẹrẹ àbájáde ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé tó máa tó mú ìkórìíra àti ohun tó ń fà á kúrò pátápátá. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ọjọ́ iwájú yìí á wáyé lábẹ́ àbójútó Ìjọba Ọlọ́run, tàbí ìjọba táá kárí gbogbo ayé. Jésù kọ́ wa láti gbàdúrà fún Ìjọba yẹn nínú Àdúrà Olúwa, nígbà tó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé.”—Mátíù 6:9, 10.

Bíbélì ṣèlérí pé lábẹ́ àbójútó Ìjọba tó máa wà lọ́run yìí, “ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 11:9; 54:13) Ìgbà náà ni àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà táa sábàá máa ń fà yọ á ní ìmúṣẹ ní gbogbo ayé pé: “[Ọlọ́run] yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ á tipa báyìí fòpin sí ìkórìíra, a ò ní gbúròó rẹ̀ mọ́ láéláé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan.

b Wo orí kẹjọ, “Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?” nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni L Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jáde.

c Bóo bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ, wọ́n lè ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí kóo kọ̀wé sáwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Ìmọ̀ràn Bíbélì Ń lé Ìkórìíra Lọ Ráúráú

“Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín? Wọn kì í ha ṣe láti orísun yìí, èyíinì ni, láti inú àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara èyí tí ń bá ìforígbárí nìṣó nínú àwọn ẹ̀yà ara yín?” (Jákọ́bù 4:1) Báa bá kọ́ láti yàgò fún ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan, wàhálà kò ní máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn.

“Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ọ̀nà mìíràn láti yàgò fún rògbòdìyàn ni láti máa fi ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tara wa.

“Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) Ó yẹ kí á ṣàkóso àwọn èrò tó lè ba nǹkan jẹ́ a sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

“Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:24, 26) Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa rò pé òun sàn ju àwọn èèyàn ẹ̀yà mìíràn lọ, torí pé mẹ́ńbà ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kan náà ni gbogbo wa jẹ́.

‘Má ṣe ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’ (Fílípì 2:3) Kò bójú mu rárá ká máa fojú tín-ínrín àwọn ẹlòmíràn, torí pé wọ́n máa ń láwọn ànímọ́ rere tiwọn wọ́n sì láwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe àmọ́ táwa kò lè ṣe. Kò sí ẹ̀yà kan tàbí àwùjọ kan tó gbọ́dọ̀ sọ pé òun nìkan lòún ni gbogbo nǹkan tó bá ti dára.

“Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Fífi ìdánúṣe bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́ àti ríràn wọ́n lọ́wọ́ láìka ẹ̀yà tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sí lè ṣe púpọ̀ láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wà yóò sì tún mú èdè àìyedè kúrò.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Etiópíà àti Eritrea jọ ń jọ́sìn pa pọ̀ ní àlàáfíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Manfred, tó jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kọ́múníìsì kò torí ẹ̀ kórìíra àwọn èèyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bíbélì lè bá wa mú ohun tó ń ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ kúrò