Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 17:1-34

  • Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Tẹsalóníkà (1-9)

  • Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Bèróà (10-15)

  • Pọ́ọ̀lù ní Áténì (16-22a)

  • Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Áréópágù (22b-34)

17  Wọ́n rin ìrìn àjò gba Áńfípólì àti Apolóníà kọjá, wọ́n sì wá sí Tẹsalóníkà,+ níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà.  Torí náà, bí àṣà Pọ́ọ̀lù,+ ó wọlé lọ bá wọn, ó sì bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́ fún sábáàtì mẹ́ta,+  ó ń ṣàlàyé, ó sì ń tọ́ka sí àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà,+ kí ó sì dìde kúrò nínú ikú,+ ó sọ pé: “Èyí ni Kristi náà, Jésù tí mò ń kéde fún yín.”  Nítorí èyí, àwọn kan lára wọn di onígbàgbọ́, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà,+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Gíríìkì tó ń sin Ọlọ́run àti díẹ̀ lára àwọn obìnrin sàràkí-sàràkí ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.  Àmọ́ inú bí àwọn Júù,+ wọ́n kó àwọn ọkùnrin burúkú kan jọ tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ní ibi ọjà, wọ́n di àwùjọ onírúgúdù, wọ́n sì dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ nínú ìlú náà. Wọ́n ya wọ ilé Jásónì, wọ́n ń wá ọ̀nà láti mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà wá fún àwùjọ náà.  Nígbà tí wọn ò rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì àti àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú, wọ́n ń pariwo pé: “Àwọn ọkùnrin tó ń dojú ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dé* ti wá síbí o,+  Jásónì sì gbà wọ́n lálejò. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló ń ta ko àwọn àṣẹ Késárì, tí wọ́n ń sọ pé ọba míì wà tó ń jẹ́ Jésù.”+  Nígbà tí àwọn èrò àti àwọn alákòóso ìlú gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù bà wọ́n;  lẹ́yìn tí wọ́n gba ohun ìdúró tí ó tó* lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn yòókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀. 10  Gbàrà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ará ní kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí Bèróà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n wọ sínágọ́gù àwọn Júù. 11  Àwọn tó wà ní Bèróà ní ọkàn rere ju àwọn tó wà ní Tẹsalóníkà lọ, torí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní lójoojúmọ́ láti rí i bóyá àwọn nǹkan yìí rí bẹ́ẹ̀. 12  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára wọn di onígbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni díẹ̀ lára àwọn obìnrin Gíríìkì tó ní orúkọ rere àti lára àwọn ọkùnrin wọn. 13  Àmọ́ nígbà tí àwọn Júù ní Tẹsalóníkà gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Bèróà, wọ́n wá síbẹ̀ láti ru àwọn èèyàn sókè, kí wọ́n sì kó sí wọn nínú.+ 14  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ará ní kí Pọ́ọ̀lù máa lọ sí etí òkun,+ àmọ́ Sílà àti Tímótì dúró síbẹ̀. 15  Nígbà tí àwọn tó wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù mú un dé Áténì, wọ́n pa dà lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé kí Sílà àti Tímótì+ tètè wá bá òun ní kíá. 16  Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń dúró dè wọ́n ní Áténì, inú bí i nígbà tó rí i pé àwọn òrìṣà kún inú ìlú náà. 17  Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Júù àti àwọn míì tó ń jọ́sìn Ọlọ́run fèròwérò nínú sínágọ́gù, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tó bá wà ní àrọ́wọ́tó. 18  Àmọ́ lára àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Epikúríà àti ti Sítọ́ìkì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jiyàn, àwọn kan ń sọ pé: “Kí ni onírèégbè yìí fẹ́ sọ?” Àwọn míì ń sọ pé: “Ó jọ ẹni tó ń kéde àwọn ọlọ́run àjèjì.” Èyí jẹ́ nítorí pé ó ń kéde ìhìn rere Jésù àti àjíǹde.+ 19  Nítorí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Áréópágù, wọ́n sọ pé: “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ tuntun tí ò ń sọ yìí jẹ́? 20  Nítorí àwọn ohun tó ṣàjèjì sí etí wa lò ń sọ, a sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí.” 21  Ní tòótọ́, gbogbo àwọn ará Áténì àti àwọn àjèjì tó ń gbé níbẹ̀* kò ní nǹkan míì tí wọ́n ń fi àkókò tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀ ṣe ju pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa fetí sí ohun tuntun. 22  Ni Pọ́ọ̀lù bá dúró láàárín Áréópágù,+ ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Áténì, mo kíyè sí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run ju bí àwọn yòókù ṣe bẹ̀rù wọn lọ.*+ 23  Bí àpẹẹrẹ, bí mo ṣe ń lọ, tí mo sì ń fara balẹ̀ wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń júbà,* mo rí pẹpẹ kan, tí wọ́n kọ àkọlé sí pé ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’ Nítorí náà, ohun tí ẹ̀ ń sìn láìmọ̀ ni mo wá kéde fún yín. 24  Ọlọ́run tó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ Olúwa ọ̀run àti ayé,+ kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ kọ́;+ 25  bẹ́ẹ̀ ni kì í retí pé kí èèyàn ran òun lọ́wọ́ bíi pé ó nílò ohunkóhun,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí+ àti ohun gbogbo. 26  Láti ara ọkùnrin kan ló ti dá+ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn láti máa gbé lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ó yan àkókò fún àwọn nǹkan, ó sì pa ààlà ibi tí àwọn èèyàn á máa gbé,+ 27  kí wọ́n lè máa wá Ọlọ́run, tí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi,+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. 28  Torí ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn kan lára àwọn akéwì yín tó sọ pé, ‘Nítorí àwa náà jẹ́ ọmọ* rẹ̀.’ 29  “Nítorí náà, bí a ṣe jẹ́ ọmọ* Ọlọ́run,+ kò yẹ kí a rò pé Olú Ọ̀run rí bíi wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a fi ọgbọ́n àti iṣẹ́ ọnà èèyàn gbẹ́ lére.+ 30  Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbójú fo ìgbà àìmọ̀ yìí;+ àmọ́ ní báyìí, ó ń sọ fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n ronú pìwà dà. 31  Torí ó ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ + ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.”+ 32  Nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yẹ̀yẹ́,+ àwọn míì sì sọ pé: “A máa gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu rẹ nígbà míì.” 33  Torí náà, Pọ́ọ̀lù fi wọ́n sílẹ̀, 34  àmọ́ àwọn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́. Lára wọn ni Díónísíù tó jẹ́ adájọ́ ní kọ́ọ̀tù Áréópágù àti obìnrin kan tó ń jẹ́ Dámárì pẹ̀lú àwọn míì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “dá wàhálà sílẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”
Tàbí “gba owó ìtúsílẹ̀.”
Tàbí “ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.”
Tàbí “ẹ ní ẹ̀mí ìsìn ju àwọn yòókù lọ.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”
Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”