Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹgbẹ́ Òkùnkùn Ò Léwu?

Ṣé Ẹgbẹ́ Òkùnkùn Ò Léwu?

 Kí lèrò ẹ?

  •   Ṣó burú téèyàn bá wo ìràwọ̀, tó bẹ́mìí lò tàbí tó wofá?

  •   Ṣé ìtàn àròsọ lásán ni ẹgbẹ́ òkùnkùn, ìyẹn ìjà láàárín ire àti ibi, àbí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ?

 Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ ohun tó mú kí ìbẹ́mílò dà bí ohun tí kò burú àti ìdí tó fi yẹ kó o ṣọ́ra.

 Kí ló mú kó wù ẹ́?

 Àwọn tó ń gbé eré ìnàjú jade ti dolówó rẹpẹtẹ tórí pé wọ́n ń ṣe àwọn fíìmù, ètò orí Tẹlifíṣọ̀n, géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù àtàwọn ìwé tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ. Èyí ti mú káwọn ọ̀dọ́ kan nífẹ̀ẹ́ sí wíwo ìràwọ̀, ẹ̀mí èṣù, àwọn àǹjọ̀ọ̀nú, iṣẹ́ oṣó àti àjẹ́. Kí nìdìí? Lára ohun tó fà á nìyí:

  •   Ojúmìító: Wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà lóòótọ́

  •   Ohun tó jẹ wọ́n lọ́kàn: Wọ́n fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la

  •   Àárò: Wọ́n fẹ́ bá àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú sọ̀rọ̀

 Àwọn ìdí yìí lè má burú. Bí àpẹẹrẹ, ìwà ẹ̀dá ni pé ká ronú nípa ọjọ́ ọ̀lá tàbí ká ṣàárò àwọn olólùfẹ́ wa tó ti kú. Àmọ́, àwọn ewu kan wà tó yẹ kó o mọ̀.

 Kí nìdìí tó fi yẹ kó o ṣọ́ra?

 Bíbélì kìlọ̀ lọ́nà tó rinlẹ̀ pé ká má ṣe ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Bí àpẹẹrẹ, ó ní:

 “Ẹnì kankan láàárín yín . . . kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ pidán, kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di oṣó, kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dò wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú. Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyì.”—Diutarónómì 18:10-12.

 Kí nìdìí tí Bíbélì fi sọ pé ìbẹ́mìílò burú jáì?

  •   Ìbẹ́mìílò ń mú kéèyàn máa ti ẹ̀mí èṣù lẹ́yìn. Bíbélì kọ́ wa pé àwọn áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ara wọn di ọ̀tá rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:2; Júùdù 6) Àwọn áńgẹ́lì burúkú yìí là ń pé ní ẹ̀mí ẹ̀ṣù, wọ́n máa ń lo àwọn abókùúsọ̀rọ̀, àwọn abẹ́mìílò, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn awòràwọ̀ láti tan èèyàn jẹ. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa di ọ̀rẹ́ àwọn tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run.

  •   Ẹ̀kọ́ èké tí ìbẹ́mìílò ń mú kó gbilẹ̀ ni pé àwọn èèyàn kan lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Àmọ́, Ọlọ́run nìkan ló lè sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ni mo sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.”—Àìsáyà 46:10; Jémíìsì 4:13, 14.

  •   Ẹ̀kọ́ èké míì tí ìbẹ́mìílò ń mú kó gbilẹ̀ ni pé àwọn òkú lè bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Àwọ̀n òkú kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú.”—Oníwàásù 9:5, 10.

 Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fara mọ́ ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Wọ́n tún máa ń yẹra fún eré ìnàjú tó ń ṣàfihàn àwọn òkú, àwọn àǹjọ̀ọ̀nú àtàwọn ohun abàmì. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maria sọ pé; “Tí ìbẹ́mìílò bá ti wà ńbẹ̀, kò yẹ kí n wò ó.” a

Bí àwọn ọ̀daràn ṣe máa ń fi ẹ̀tàn mú káwọn èèyàn rò pé ẹlòmíì làwọn, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa ń díbọ́n bíi pé olólùfẹ́ rẹ tó ti kú làwọn

 Kí lo máa ṣe?

  •   Pinnu pé wàá máa yẹra fún àwọn àṣà àti eré ìnàjú tó jẹ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn ‘kí ẹ̀rí ọ̀kàn rẹ lè mọ́’ níwájú Jèhófà.—Ìṣe 24:16.

  •   Kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn dà nù. Ka Ìṣe 19:19, 20, kó o lè kíyè sí àpẹẹrẹ àtàtà àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lórí ọ̀rọ̀ yìí.

 Rántí pé: Tó o bá yẹra fún iṣẹ́ awo àti eré ìnàjú tó ń gbé e lárugẹ, ṣe lò ń fi hàn pé Jèhófà lò ń tì lẹ́yìn. Ìyẹn sì máa múnú ẹ dùn!—Òwe 27:11.

a Kì í ṣe gbogbo nǹkan àràmàǹdà àtàwọn nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ tó ń jáde nínú fíìmù ló ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ. Àmọ́, àwọn Kristẹni tó ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn máa ń yẹra fún àwọn àṣà àti eré ìnàjú tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ.—2 Kọ́ríńtì 6:17; Hébérù 5:14.