Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Ṣe?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Ṣe?

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), gbogbo òfin táwọn òbí mi ṣe ni mo fara mọ́, àmọ́ ní báyìí tí mo ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19), mo gbà pé ó yẹ kí wọ́n túbọ̀ fún mi lómìnira.”​—Sylvia.

Ṣé bó ṣe ń ṣe Sylvia ló ń ṣe ìwọ náà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń ṣe ẹ́, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe bá àwọn òbí ẹ sọ ọ́.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

Kó o tó bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tí wọ́n ṣe, ronú lórí àwọn kókó yìí:

  • Tí kò bá sí òfin láyé, ayé á ti dà rú. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ojú títì márosẹ̀ kan tí mọ́tò ti pọ̀. Tí kò bá sí àwọn àmì ojú ọ̀nà, tí kò sí àwọn iná ojú ọ̀nà tó ń darí àwọn onímọ́tò tó ń lọ, tó ń bọ̀, tí kò sí àkọlé kankan tó sọ iye eré téèyàn lè sá, báwo lo rò pé ó ṣe máa rí? Bí àwọn òfin ìrìnnà ṣe máa ń jẹ́ kí nǹkan lọ létòlétò, bẹ́ẹ̀ náà làwọn òfin táwọn òbí ṣe nínú ilé máa ń jẹ́ kí ètò wà.

  • Òfin táwọn òbí ẹ ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹ jẹ wọ́n lógún. Tí wọn ò bá fún ẹ lófin kankan, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ ò tu irun kankan lára wọn nìyẹn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé a lè sọ pé òbí rere ni wọ́n?

ǸJẸ́ O MỌ̀? Àwọn òbí náà ní àwọn òfin tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé? Tí kò bá dá ẹ lójú, lọ ka Jẹ́nẹ́sísì 2:​24; Diutarónómì 6:​6, 7; Éfésù 6:4; àti 1 Tímótì 5:8.

Àmọ́, kí lo lè ṣe tó bá ṣì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òfin táwọn òbí ẹ ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ dáa tó?

 Ohun tó o lè ṣe

Kó o tó bá wọn sọ ọ́, kọ́kọ́ rò ó. Ṣé o máa ń tẹ̀ lé àwọn òfin táwọn òbí ẹ ṣe tẹ́lẹ̀? Tó bá jẹ́ pé o kì í fìgbà gbogbo tẹ̀ lé òfin wọn tẹ́lẹ̀, á dáa kó o má tíì bá wọn sọ ọ́ báyìí pé kí wọ́n fún ẹ lómìnira sí i. Dípò ìyẹn, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?

Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o ti máa ń pa òfin wọn mọ́ tẹ́lẹ̀, múra ohun tó o fẹ́ bá àwọn òbí ẹ sọ sílẹ̀. Tó o bá ti kọ́kọ́ ronú ohun tó o fẹ́ sọ, ó máa jẹ́ kíwọ fúnra ẹ mọ̀ bóyá ohun tó o fẹ́ béèrè lọ́wọ́ wọn bọ́gbọ́n mu. Lẹ́yìn ìyẹn, sọ fún àwọn òbí ẹ kí wọ́n sọ ìgbà tẹ́ ẹ lè sọ̀rọ̀ àti ibi tẹ́ ẹ ti máa sọ ọ́, kó jẹ́ ibi tí ara á ti tu gbogbo yín, tí ẹ̀ẹ́ sì lè túra ká. Tó o bá ti wá ń bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, má gbàgbé àwọn kókó yìí:

Bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Torí náà, ṣọ́ra, sì fi sọ́kàn pé: Tó o bá bá àwọn òbí ẹ jiyàn tàbí tó o fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọn ò ṣe é dáa tó, ìjíròrò yín lè má yọrí síbi tó dáa.

“Bí mo bá ṣe bọ̀wọ̀ fáwọn òbí mi tó làwọn náà ṣe máa ń fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Tá a bá ti fọ̀wọ̀ kálukú wọ̀ ọ́, ó máa ń rọrùn láti fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀.”​—Bianca, 19.

Tẹ́tí sí wọn. Bíbélì sọ fún wa pé ká “yára láti gbọ́rọ̀, kí [a sì] lọ́ra láti sọ̀rọ̀.” (Jémíìsì 1:​19) Rántí pé, ṣe ni ìwọ àtàwọn òbí ẹ jọ ń jíròrò, torí náà, ìwọ nìkan kọ́ lo máa sọ̀rọ̀.

“Bá a ṣe ń dàgbà, ó lè máa ṣe wá bíi pé a mọ̀ ju àwọn òbí wa lọ, àmọ́ irọ́ gbáà ni. Ó yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn wọn, ká sì máa gbọ́ tiwọn.”​—Devan, 20.

Fọ̀rọ̀ rora ẹ wò. Gbìyànjú láti fira ẹ sípò àwọn òbí ẹ. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé ki ẹ máa “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan”​—tó fi hàn pé, kó o ro ti àwọn òbí ẹ náà.​—Fílípì 2:4.

Èwo lo rò pé ó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fún ẹ lómìnira?

“Tẹ́lẹ̀, mo máa ń wo àwọn òbí mi bíi pé ṣe ni wọ́n ń ta kò mí. Àmọ́ mo ti wá rí i báyìí pé ṣe làwọn náà ń sapá kí wọ́n lè jẹ́ òbí rere fún mi, bí èmi náà ṣe ń sapá kí n lè di ọmọlúàbí. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí mi ló mú kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.”​—Joshua, 21.

Mú àbá tó lè yanjú ọ̀rọ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn òbí ẹ sọ pé wọn ò ní gbà ẹ́ láyè láti wakọ̀ kọjá wákàtí kan lọ síbi àríyá èyíkéyìí tó o bá fẹ́ lọ. Gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀. Ṣé ọ̀nà tó jìn yẹn nìṣòro ni, àbí àríyá yẹn gan-an ni wọn ò fẹ́ kó o lọ?

  • Tó bá jẹ́ ọ̀nà tó jìn ni, ṣé wọ́n lè gbà kí ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọ mọ́tò wà dáadáa bá ẹ rìn?

  • Tó bá jẹ́ àríyá yẹn nìṣòro, ṣé o lè sọ àwọn tó máa wà níbẹ̀ fún wọn, kó o sì fi dá wọn lójú pé ètò gidi wà láti bójú tó àríyá náà kí nǹkan má bàa yíwọ́?

Má gbàgbé, bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun táwọn òbí ẹ bá sọ. Jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ pé o “bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:​2, 3) Wọ́n lè gbà pẹ̀lú ẹ, wọ́n sì lè má gbà. Èyí ó wù kó jẹ́, rí i pé o . . .

Fìrẹ̀lẹ̀ gba ohun táwọn òbí ẹ bá sọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀. Táwọn òbí ẹ ò bá ṣe ohun tó o fẹ́ fún ẹ, tó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jiyàn, ara ẹ lò ń ṣe torí ọjọ́ míì tó o bá tún máa bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ tó o bá fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó ṣeé ṣe káwọn náà rò ó pé káwọn jẹ́ kó o lómìnira díẹ̀ sí i.