Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ní ilé ìjọsìn tí wọ́n máa ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀, àǹfààní wo lo sì máa rí tó o bá lọ síbẹ̀?

 Kí ni wọ́n máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti máa ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó lè ṣe wá láǹfààní. Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe níbẹ̀ máa jẹ́ kó o:

  • mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.

  • mọ ìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ láyé.

  • máa hùwà rere.

  •  rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń pe ibi ìpàdé wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ni pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run là ń sọ níbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.​​—Mátíù 6:​9, 10; 24:14; Lúùkù 4:43.

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o lọ?

Àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn ìlànà Bíbélì tá à ń kọ́ ní ibi ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa jẹ́ kó o “ní ọgbọ́n.” (Òwe 4:5) Ìyẹn ni pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ ní ìgbésí ayé rẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa jẹ́ kó o rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì ní ìgbésí ayé, irú bíi:

Díè rèé lára àwọn àsọyé Bíbélì tá a máa ń gbọ́ ní òpin ọ̀sẹ̀ láwọn ìpàdé wa:

  • Kí nìdí Tó Fi Yẹ Kí Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Rẹ?

  • Ọ̀dọ̀ Ta Lo Ti Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Lákòókò Wàhálà?

  • Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run Ń Ṣe Fún Wa Nísinsìnyí.

“Ọmọ kíláàsì mi kan wá sí ìpàdé. Ó jókòó pẹ̀lú ìdílé wa, a sì fún un ní ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, ó sọ fún mi pé òun fẹ́ràn báwọn èèyàn ṣe ń dáhùn nígbà tí wọ́n ń béèrè ìbéèrè. Ó tún sọ pé àwọn ò ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn bíi tiwa.”​​—Brenda.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ọ̀fẹ́ ni àyè ìjókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a kì í sì gbé igbá owó.

Wàá rí ìṣírí gbà. Bíbélì sọ pé ọ̀kan lára ìdí táwa Kristẹni fi ń péjọ pọ̀ ni láti “fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” (Hébérù 10:​24, 25) Nínú ayé táwọn èèyàn ò ti mọ̀ ju tara wọn lọ yìí, ó dájú pé ó máa dára gan-an téèyàn bá ń péjọ pẹ̀lú àwọn tó máa ń fi Ọlọ́run ṣáájú, tọ́rọ̀ àwọn míì sì jẹ lógún.

“Mo lè ti ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan kó sì ti rẹ̀ mí gan-an, àmọ́ tí mo bá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn èèyàn máa ń mú kí ara tù mí. Tí mo bá ń pa dà sílé lẹ́yìn tá a bá parí ìpàdé, inú mi máa ń dùn, ara mi sì máa ń yá gágá láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọjọ́ lọ́jọ́ kejì.”​​—Elisa.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé, láwọn ibi tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà [60,000]. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ̀ [1,500] Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń kọ́ lọ́dọọdún nítorí àwọn ẹni tuntun tó ń wá sí ìpàdé wa. *

^ ìpínrọ̀ 20 Tó o bá fẹ́ mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà, lọ sí ìkànnì jw.org ní abala “Ìpàdé Ìjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” kó o sì tẹ “Wá Ibi Tó Sún Mọ́ Ẹ.”