Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wà?

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. “Àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀” ni àwọn ẹ̀mí èṣù, ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run sì ni wọ́n. (2 Pétérù 2:4) Sátánì Èṣù ni áńgẹ́lì tó kọ́kọ́ sọ ara rẹ̀ di ẹ̀mí èṣù, òun sì ni Bíbélì pè ní “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”—Mátíù 12:24, 26.

Ìwà ọ̀tẹ̀ tó wáyé nígbà ayé Nóà

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn áńgẹ́lì kan ṣe hùwà ọ̀tẹ̀ ṣáájú Ìkún-omi ọjọ́ Nóà, ó ní: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:2) Àwọn áńgẹ́lì burúkú tàbí àwọn áńgẹ́lì tó ṣubú yìí fi “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” ní ọ̀run sílẹ̀, wọ́n sì gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ torí kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin.—Júúdà 6.

 Nígbà tí Ìkún-omi dé, ńṣe ni àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí bọ́ ara èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì padà sí ọ̀run. Àmọ́, Ọlọ́run lé wọn dànù, torí wọn kì í ṣe ara ìdílé rẹ̀ mọ́. Bí Ọlọ́run kò ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ mọ́ jẹ́ ara ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—Éfésù 6:11, 12.