Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?

 “Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn àníyàn gbà mí lọ́kàn gan-an, ṣe ló dà bí iná tí kò ṣeé pa. Láwọn àkókò yẹn ṣe ló ń ṣe mí bíi pé kí n pa ara mí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ́ kú. Ohun tí mo ṣáà fẹ́ ní pé kí gbogbo ìṣòro yìí dópin.”​—Jonathan ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17).

 Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000), ìdá kan nínú márùn-ún ló sọ pé láàárín ọdún kan sẹ́yìn àwọn tí gbìyánjú láti pa ara àwọn. a Tí ayé bá sú ẹ, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi kó o pa ara ẹ, kí lo lè ṣe?

  •   Ṣe sùúrù. Má ṣe kánjú ṣèpinnu tí ohun kan bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro náà lè ga bí òkè, fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà.

 Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà nǹkan lè má rí bó o ṣe rò. Kódà tó o bá rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́, ojútùú ìṣòro náà lè má le tó bó o ṣe rò.

  •  Ìlànà Bíbélì: “Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá.”​—2 Kọ́ríńtì 4:8.

     Àbá: Tó bá jẹ́ pé ó sábà máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ara ẹ, ṣèwádìí bóyá ètò kan wà tí ìjọba ti ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ronú láti para wọn, tàbí kó o wá nọ́ńbà àwọn tó máa ń ṣe ìtọ́jú pàjáwìrì. Wọ́n ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, torí wọ́n ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè bójú tó irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.

  •   Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì ẹ, tí wọ́n sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lára wọn ni àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé ẹ, àmọ́ tó ò bá sọ ìṣòro ẹ fún wọn, kò sí bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Bó ṣe jẹ́ pé àwọn kan nílò ìgò ojú kí wọ́n lè ríran dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rẹ́ gidi lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ, kó o sì pinnu pé o ní pa ara rẹ.

  •  Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

     Àbá: O lè sọ pé: “Ohun kan wà tí mò ń bá yí lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, mi ò mọ̀ bóyá mo lè bá yín sọ ọ́.” Tàbí kó o sọ pé: “Mo ní àwọn ìṣòro kan tí mi ò lè yanjú, ṣé ẹ lè ràn mí lọ́wọ́?”

  •   Lọ rí dókítà. Àwọn àìsàn kan wà tó máa ń mú kéèyàn máa ṣàníyàn tàbí soríkọ́, ó sì lè mú kéèyàn máa ronú àtipa ara ẹ̀. Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ kan ni pé àìsàn náà gbóògùn.

 Bó ṣe jẹ́ pé tí ara ẹnì kan ò bá yá, oúnjẹ ò ní wù ú jẹ, bákan náà téèyàn bá soríkọ́, ó lè máa ṣe é bíi kó para ẹ̀. Àmọ́, àwọn ìṣòro méjèèjì yìí ló gbóògùn.

  •  Ìlànà Bíbélì: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.”​—Mátíù 9:12.

     Àbá: Rí i pé ò ń sùn dáadáa, máa ṣe eré ìmárale, kó o sì máa jẹ oúnjẹ tó ṣaralóore. Torí pé to bá ní ìlera tó dáa, wàá lè ronú lọ́nà tó tọ́, ọkàn rẹ á sì balẹ̀.

  •   Gbàdúrà. Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa “ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) O ò ṣe gbàdúrà sí i lónìí, kó o lo orúkọ ẹ̀ ìyẹn Jèhófà, kó o sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un.

 Àwọn ìṣòro kan wà tó nira láti dá yanjú. Àmọ́, Jèhófà Ẹlẹ́dàá rẹ ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  •  Ìlànà Bíbélì: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.”​—Fílípì 4:​6, 7.

     Àbá: Yàtọ̀ sí pé o sọ àwọn ìṣòro rẹ fún Jèhófà, gbìyànjú láti ronú lórí ó kéré tán ohun rere kan tí Jèhófà ṣe fún ẹ lónìí, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Kólósè 3:15) Tó o bá moore, ìyẹn a jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ.

 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ayé ti sú ẹ, jẹ́ kí ẹnì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun tí Jonathan tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí n bá àwọn òbí mi sọ, kí n sì lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Ọkàn mi ti balẹ̀ dáadáa báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ kò ṣe mí bíi kí n pa ara mi mọ́.”

a Àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe ń kápá àìsàn, tí wọ́n sì ń dènà ẹ̀ ní Amẹ́ríkà, ìyẹn Centers for Disease Control and Prevention ló ṣe ìwádìí yìí lọ́dún 2019.