Yorùbá
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/500600113/univ/art/500600113_univ_sqr_xl.jpg
ijwyp àpilẹ̀kọ 110

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi

 Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tó o sì ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, ó dájú pé wàá tí máa ronú nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Àmọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi? a

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Báwo ni nǹkan tí mo mọ̀ ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó?

 Tó o bá ń múra láti ṣèrìbọmi, kò pọn dandan kó o máa há ohun tó ò ń kọ́ sórí bí ìgbà tó ò ń múra ìdánwò nílé ìwé. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ lo “agbára ìrònú” rẹ kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé òtítọ́ làwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì. (Róòmù 12:1) Bí àpẹẹrẹ:

 Kí ló yẹ kí n máa ṣe?

 Kò dìgbà tó o bá di ẹni tó pé kó o tó lè ṣèrìbọmi. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o fẹ́ “jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere” (Sáàmù 34:14) Bí àpẹẹrẹ:

  •   Ṣé o máa ń fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésì ayé rẹ?

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere”​—1 Pétérù 3:16.

     Bi ara ẹ pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni mo ti ṣe tó fi hàn pé mo ti “kọ́ agbára ìfòyemọ̀” mi, kí n lè máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́”?’ (Hébérù 5:14) ‘Ṣé mo lè rántí àwọn ìgbà kan táwọn ojúgbà mi fẹ́ kí n ṣe ohun tí ò dáa, àmọ́ tí mo kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́? Ṣé àwọn tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́?’​—Òwe 13:20.

     Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?

  •   Ṣé o mọ̀ pé gbogbo ohun tó o bá ṣe lo máa jíhìn fún Jèhófà?

     Bíbélì sọ pé: “Kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run”​—Róòmù 14:12.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í tan ara mi jẹ, ṣe mo sì jẹ́ olóòótọ́ nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn èèyàn?’ (Hébérù 13:18) ‘Tí mo bá ṣe ohun tí ò dáa, ṣé mo máa ń gbà pé mo jẹ̀bi, ṣé kì í ṣe pé mo máa ń dọ́gbọ́n bo ohun tí mo ṣe mọ́lẹ̀ àbí kí n di ẹ̀bi ẹ̀ ru àwọn ẹlòmíì?’​—Òwe 28:13.

     Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Mo Lè Ṣe Nípa Àwọn Àṣìṣe Mi?

  •   Ṣé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín”​—Jémíìsì 4:8

     Bi ara ẹ pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí mò ń ṣe kí n lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ Bí àpẹẹrẹ, ‘Ṣé mo máa ń ka Bíbélì déédéé?’ (Sáàmù 1:1, 2) ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà déédéé?’ (1 Tẹsalóníkà 5:17) ‘Tí mo bá ń gbàdúrà, ṣé mo máa ń sọ àwọn nǹkan pàtó tí mo fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún mi? Ṣé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́?’​—Sáàmù 15:1, 4.

     Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?​—Apá Kejì: Jẹ́ Kí Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ” àti “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?

 ÀBÁ: Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi, ka orí 37 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2. Ní pàtàkì wo àpótí tá a pè ní “Ṣó O Ti Ń Ronú Láti Ṣèrìbọmi?” tó wà lójú ìwé 308 sí 309.

a Kó o lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹ sí mímọ́ kó o sì ṣèrìbọmi àti ìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1.”