Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá Báni Ṣèṣekúṣe?​—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Kọ́fẹ Pa Dà

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá Báni Ṣèṣekúṣe?​—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Kọ́fẹ Pa Dà

 Ohun tó o lè ṣe bí ọkàn rẹ bá ń dá ẹ lẹ́bi

Ojú máa ń ti àwọn tí wọ́n bá fipá bá ṣèṣekúṣe gan-an torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí. Wọ́n tiẹ̀ máa ń ronú pé àwọn làwọn fa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen, tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà sí mẹ́tàlá àmọ́ tó ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] báyìí sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú ìṣòro mi ni bí mo ṣe máa ń dá ara mi lẹ́bi. Mo máa ń rò ó pé ‘Kí nìdí tí mo fi wá jẹ́ kí irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí pẹ́ tó báyìí?”’

Tó bá jẹ́ pé ohun tí ìwọ náà ń rò nìyẹn, gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀wò:

  • Ó rọrùn láti bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe torí wọ́n ò lè kọ̀ ọ́. Wọn ò mọ ohun tí ìbálòpọ̀ túmọ̀ sí àti ohun tó lè yọrí sí. Torí náà, a ò lè dá ọmọ kan lẹ́bi tí wọ́n bá bá a ṣèṣekúṣe.

  • Àwọn ọmọdé máa ń fọkàn tán àwọn àgbàlagbà, wọn ò sì ní ìrírí débi tí wọ́n máa mọ̀ ọgbọ́n táwọn tó ń hùwà ìbàjẹ́ yìí máa ń dá, ìdí nìyẹn tó fi rọrùn láti fipá bá wọn ṣèṣekúṣe. Ìwé kan tí wọ́n pè ní The Right to Innocence sọ pé: “‘Ọlọ́gbọ́n féfé’ làwọn tó máa ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe, ìrònú àwọn ọmọdé ò sì lè tó tiwọn láé.”

  • Tí wọ́n bá ń fipá bá ọmọdé kan ṣèṣekúṣe, ọkàn rẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ìṣekúṣe. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn, má ronú jù torí pé bó ṣe máa ń rí nìyẹn tó bá ti ń di pé wọ́n ti ń fọwọ́ kan àwọn ibì kan lára wa. Ìyẹn ò sì túmọ̀ sí pé ẹ̀bi rẹ ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tàbí pé o kò bá ti má fàyè gba irú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀.

Àbá: Ronú nípa ọmọ kan tó o mọ̀ tí kò ju ọmọ ọdún tó o wà nígbà ti wọ́n fipá bá ẹ ṣèṣekúṣe lọ. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo lè dá ọmọ yìí lẹ́bi tí n bá gbọ́ pé ẹnì kan fipá bá a ṣèṣekúṣe?’

Karen ronú lórí kókó tá a ṣẹ̀ sọ tán yìí nígbà tó ń bójú tó àwọn ọmọ mẹ́ta kan tí ọ̀kan nínú wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ọdún mẹ́fà, ìyẹn ọmọ ọdún tó wà nígbà tí wọ́n fipá bá a ṣèṣekúṣe. Karen sọ pé: “Mo ṣẹ̀ wá rí bó ṣe rọrùn tó láti fipá bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe, mo ti wá rí ohun tó fà á tí ọ̀rọ̀ tèmi náà fi rí bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn.”

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ẹni tó fipá bá ẹ ṣèṣekúṣe ló jẹ̀bi. Bíbélì sọ pé: “Ìwà burúkú ẹni burúkú yóò sì wà lórí [ẹni burúkú náà].”​Ìsíkíẹ́lì 18:20.

 Àǹfààní tó wà nínú kó o fi ọ̀rọ̀ lọ ẹnì kan

Ara máa tù ẹ́ tó o bá lè fọ̀rọ̀ náà lọ ẹnì kan. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”​—Òwe 17:17.

Lóòótọ́, ọkàn ẹ lè balẹ̀ pé àwọn èèyàn ò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ torí pé o kò sọ fún ẹnì kankan. Bí o kò ṣe fọ̀rọ̀ náà lọ ẹnì kankan dà bí ìgbà tí o bá mọ ògiri yí ara rẹ ká kó o lè dáàbò bo ara rẹ. Àmọ́, má gbàgbé pé bí ògiri náà ṣe máa dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ ìṣòro náà ni kò ṣe ní jẹ́ kó o rí ìrànlọ́wọ́ gbà.

Bí o kò ṣe sọ ohun tó ṣe ẹ́ fún ẹnì kan dà bí ògiri tó dáàbò bò ẹ́ àmọ́ tí kò lè jẹ́ kó o rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà ìṣòrò

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Janet sọ pé ọkàn òun balẹ̀ gan-an lẹ́yìn tí òun bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun. Ó sọ pé: “Ẹnì kan tí mo mọ̀ dáadáa tí mo sì fọkàn tán ló fipá bá mi ṣèṣekúṣe, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ lẹ́yìn tí mo sọ̀rọ̀ náà fún Mọ́mì mi, ńṣe ló dà bíi pé mo sọ ẹrù tó wúwo kalẹ̀.”

Janet mọ ohun tó fà á tí àwọn kan kì í fi í sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, torí pé ó ti ṣe òun náà rí. Ó sọ pé: “Kì í rọrùn fún ẹni tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe láti dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Ó máa ń dùn mí gan-an tí n bá rántí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo tètè fọ̀rọ̀ náà lọ ẹnì kan kó tó pẹ́ jù.”

 “Ìgbà ìmúláradá”

Ẹni tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe lè máa ro èròkerò sí ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa rò ó pé ó ti tán fún òun àti pé òun ò wúlò mọ́ tàbí kó máa rò pé kí wọ́n kàn máa bá òun ṣèṣekúṣe ni òun wà fún. O lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn èrò tí kò tọ́ yìí kó o sì rí “ìgbà ìmúláradá.” (Oníwàásù 3:3, Bíbélì Mímọ́) Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro yìí?

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, ó sì ‘lágbára láti . . . dojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé’​—títí kan àwọn èrò tí kò tọ́ tí ò ń rò nípa ara rẹ. (2 Kọ́ríńtì 10:​4, 5) Bí àpẹẹrẹ, ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí kó o sì ronú lé wọn lórí: Aísáyà 41:10; Jeremáyà 31:3; Málákì 3:​16, 17; Lúùkù 12:​6, 7; 1 Jòhánù 3:​19, 20.

Máa gbàdúrà. Tí ó bá ń ronú pé o kò wúlò mọ́ tàbí pé ìwọ lo lẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ, “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà” nípasẹ̀ àdúrà. (Sáàmù 55:22) Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ!

Àwọn alàgbà ìjọ. Àwọn arákùnrin tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ yìí “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísáyà 32:2) Wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó ò lè máa fojú tó tọ́ wo ara rẹ kó o sì máa gbádùn ìgbésí ayé rẹ nìṣó.

Àwọn ọ̀rẹ́ tó dára. Máa kíyè sí ìwà àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kíyè sí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí ara wọn. Wàá rí i pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń hùwàkiwà sí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́.

Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tanya gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Láti kékeré làwọn ọkùnrin kan ti máa ń fipá bá a ṣèṣekúṣe. Ó sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tí mo fọkàn tán ló fipá bá mi ṣèṣekúṣe.” Nígbà tó yá, Tanya wá rí i pé àwọn ọkùnrin kan wà tí wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́. Báwo ló ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

Èrò tó ní tẹ́lẹ̀ yí pa dà nígbà tó di ọ̀rẹ́ àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ìwà ọkùnrin yẹn ti jẹ́ kí ń rí i pé kì í ṣe gbogbo ọkùnrin ló ń hùwàkiwà. Ọkùnrin yìí ń ṣìkẹ́ ìyàwó rẹ̀, bí Ọlọ́run sì ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn.” *​—Éfésù 5:​28, 29.

^ ìpínrọ̀ 19 Tó o bá ní ìṣòro ìdààmú ọkàn tó le gan-an, ìṣòro àìlè-jẹun dáadáa, ìṣòro kéèyàn máa dá ọgbẹ́ sí ara rẹ̀ lára, tó o bá ń lo ògùn ní ìlòkulò, ìṣòro àìróorun sùn, tó bá ń ṣe ẹ́ bí i pé kó o pa ara rẹ, ohun tó máa dára jù ni pé kó o lọ rí dókítà.