Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?

 Kí lo máa ṣe táwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀?

  1.   Olùkọ rẹ bá ẹ wí torí pé o hùwà tí ò dáa nínú kíláàsì.

     Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ​—tó o bá tiẹ̀ rò pé ṣe ló gba ọ̀rọ̀ náà sódì?

  2.   Ọ̀rẹ́ rẹ gbọ́ pé o bú òun.

     Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ​—tó o bá tiẹ̀ gbà pé ohun tó o sọ ò burú?

  3.   O bínú sí bàbá rẹ, o sì sọ̀rọ̀ àrífín sí i.

     Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ bàbá rẹ​—tó o bá tiẹ̀ gbà pé òun ló mú inú bí ẹ?

 Bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì, tó o bá tiẹ̀ rò pé ọwọ́ ẹ kọ́ ni gbogbo ẹ̀bi wà?

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì?

  •   Ẹni tó bá tọrọ àforíjì fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun. Tó o bá ń fi hàn pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi torí ohun tó o sọ tàbí torí ohun tó o ṣe, ò ń fi hàn pé o ti ń ní àwọn ànímọ́ pàtàkì tó o máa nílò tó o bá dàgbà.

     “Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù lè mú ká tọrọ àforíjì ká sì wá tẹ́tí sí ohun tí ẹlòmíì fẹ́ sọ.”​—Rachel.

  •   Tó o bá tọrọ àforíjì, á mú kó o lè ṣe àtúnṣe. Àwọn èèyàn tó bá ń sọ pé “Máà bínú” ń fi hàn pé àlàáfíà jẹ àwọn lógún ju kí wọ́n dá ara wọn láre tàbí kí wọ́n fi àṣìṣe ẹlòmíì hàn.

     “Tó ò bá tiẹ̀ rò pé ìwọ lo jẹ̀bi, bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ló yẹ kó jẹ ọ́ lógún. Kò ná èèyàn ní nǹkan kan láti sọ pé ‘Forí jì mí,’ ṣùgbọ́n ó lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe.”​—Miriam.

  •   Tó o bá tọrọ àforíjì, ara máa tù ẹ́. Ẹrù tó wúwo láti gbé ni ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí ò dáa sí ẹlòmíì. Ṣùgbọ́n, tó o bá tọrọ àforíjì, ó ti gbé ẹrù yẹn kúrò léjìká ẹ nìyẹn. a

     “Àwọn ìgbà míì wà tí mo máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí màmá tàbí bàbá mi. Ó máa ń dùn mí, ṣùgbọ́n ó máa ń ṣòro fún mi láti tọrọ àforíjì. Àmọ́, tí mo bá tọrọ àforíjì, ará máa ń tù mí torí pé àlàáfíà á tún pa dà jọba nínú ilé.”​—Nia.

    Àbámọ̀ dà bí ẹrù tó wúwo; tó o bá ti tọrọ àforíjì, ẹrù yẹn ò sí lórí ẹ mọ́ nìyẹn

 Ṣé òótọ́ ni kì í rọrùn láti tọrọ àforíjì? Bẹ́ẹ̀ ni! Dena, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ti ní láti tọrọ àforíjì léraléra torí pé ó hùwà tí ò dáa sí mọ́mì rẹ̀, sọ pé: “Kò rọrùn láti sọ pé ‘Ẹ máà bínú.’ Ṣe ni ọkàn mi máa ń bà jẹ́ tí mi ò sì ní lé sọ nǹkan kan!”

 Bó o ṣe lè sọ pé “Máà bínú”

  •   Tó bá ṣeé ṣe, tọrọ àforíjì ní ojúkojú. Tó o bá tọrọ àforíjì ní ojúkojú, onítọ̀hún á rí i pé tinútinú lo fi kábàámọ̀ ohun tó o ṣe. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ṣe lo tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ láti fi bẹ̀ ẹ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rí bó ṣe dùn ẹ́ tó. Kódà, tó o bá fi àwòrán ojú tó fi ẹ̀dùn ọkàn hàn ránṣẹ́ pẹ̀lú àtẹ̀jíṣẹ́ náà, ó lè dà bíi pé ẹ̀bẹ̀ orí ahọ́n lásán ni, kò dénú ẹ.

     Ìmọ̀ràn: Tó ò bá lè tọrọ àforíjì ní ojúkojú, ó lè pè sórí fóònù tàbí kó o fi káàdì tó o kọ ọ̀rọ̀ sí ránṣẹ́. Ọ̀nà yòówù kó o gbà tọrọ àforíjì, mọ irú ọ̀rọ̀ tí wàá sọ.

     Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn.”​—Òwe 15:28.

  •   Tètè tọrọ àforíjì. Tó ò bá tètè tọrọ àforíjì, ọ̀rọ̀ náà lè burú ju bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ lọ, àárín ìwọ àti ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ ò sì ní gún.

     Ìmọ̀ràn: Ní àfojúsùn​—bí àpẹẹrẹ, ‘Màá tọrọ àforíjì lónìí.’ Pinnu ìgbà tó dáa jù lọ kó o ṣe bẹ́ẹ̀; má sì ṣe jẹ́ kí ọjọ́ yẹn yẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Tètè yanjú ọ̀rọ̀.”​—Mátíù 5:25.

  •   Tọrọ àforíjì látọkàn wá. Tó o bá sọ pé: “Máà bínú pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ nìyẹn” ìyẹn kì í ṣe ẹ̀bẹ̀! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Janelle sọ pé: “Bí ẹni tó o ṣẹ̀ bá rí i pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, ó máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.”

     Ìmọ̀ràn: Tọrọ àforíjì pátápátá. Má ṣe sọ pé, “Àwa méjèèjì la jọ lẹ̀bi, màá tọrọ àforíjì tèmi, kíwọ náà yáa tọrọ àforíjì tìẹ.”

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà.”​—Róòmù 14:19.

a Tó o bá ba nǹkan ẹlòmíì jẹ́ tàbí tó o sọ ọ́ nù, ó máa dára bó o ṣe ń tọrọ àforíjì kó o wá bí wàá ṣe tún ohun tó o bà jẹ́ ṣe tàbí kó o sanwó ohun tó o sọ nù.