Sí Àwọn Ará Róòmù 14:1-23

  • Má ṣe dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́ (1-12)

  • Má ṣe mú ẹlòmíì kọsẹ̀ (13-18)

  • Mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà (19-23)

14  Ẹ tẹ́wọ́ gba ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára,+ àmọ́ ẹ má ṣe dá a lẹ́jọ́ nítorí èrò rẹ̀.*  Ìgbàgbọ́ ẹnì kan lè fàyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo, àmọ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára máa ń jẹ àwọn nǹkan ọ̀gbìn nìkan.  Kí ẹni tó ń jẹ má fojú àbùkù wo ẹni tí kò jẹ, kí ẹni tí kò jẹ má sì dá ẹni tó ń jẹ lẹ́jọ́,+ nítorí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba onítọ̀hún.  Ta ni ọ́, tí o fi ń ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ẹlòmíì?+ Ọ̀gá rẹ̀ ló máa pinnu bóyá ó máa ṣubú tàbí ó máa wà ní ìdúró.+ Ní tòótọ́, a máa mú un dúró, nítorí Jèhófà* lè mú un dúró.  Ẹnì kan gbà pé ọjọ́ kan ṣe pàtàkì ju òmíràn lọ;+ ẹlòmíì gbà pé ọjọ́ kan kò yàtọ̀ sí gbogbo ọjọ́ yòókù;+ kí èrò kálukú dá a lójú hán-ún hán-ún.  Ẹni tó ń pa ọjọ́ kan mọ́ ń pa á mọ́ fún Jèhófà.* Bákan náà, ẹni tó ń jẹun, ń jẹun fún Jèhófà,* nítorí ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run;+ ẹni tí kò sì jẹun kò jẹun fún Jèhófà,* síbẹ̀, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.+  Kò sí ìkankan nínú wa, ní ti gidi, tó wà láàyè nítorí ara rẹ̀,+ kò sì sí ẹni tó kú nítorí ara rẹ̀.  Nítorí pé tí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà,*+ tí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà.* Torí náà, tí a bá wà láàyè tàbí tí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.*+  Torí èyí ni Kristi fi kú, tí ó sì pa dà wà láàyè, kí ó lè jẹ́ Olúwa lórí àwọn òkú àti àwọn alààyè.+ 10  Àmọ́ kí ló dé tí o fi ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́?+ Tàbí kí ló dé tí ò ń fojú àbùkù wo arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa la máa dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.+ 11  Nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “‘Bí mo ti wà láàyè,’+ ni Jèhófà* wí, ‘gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé èmi ni Ọlọ́run.’”+ 12  Nítorí náà, kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.+ 13  Torí náà, kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́,+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ pinnu pé ẹ ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí ohun ìdènà síwájú arákùnrin yín.+ 14  Mo mọ̀, ó sì dá mi lójú nínú Jésù Olúwa pé kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ aláìmọ́ fúnra rẹ̀;+ àmọ́ tí ẹnì kan bá ka ohun kan sí aláìmọ́, ó máa jẹ́ aláìmọ́ lójú rẹ̀. 15  Nítorí bí o bá ṣẹ arákùnrin rẹ torí oúnjẹ, o ò rìn lọ́nà tó bá ìfẹ́ mu mọ́.+ Má fi oúnjẹ rẹ pa ẹni tí Kristi kú fún run.*+ 16  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tí ẹ̀ ń ṣe pé ibi ni. 17  Nítorí ìjọba Ọlọ́run kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú jíjẹ àti mímu,+ àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú òdodo àti àlàáfíà àti ayọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. 18  Nítorí ẹni tó bá ń ṣẹrú fún Kristi lọ́nà yìí ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. 19  Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà+ àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.+ 20  Ẹ má ṣe máa ya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ nítorí oúnjẹ.+ Lóòótọ́, ohun gbogbo ni ó mọ́, àmọ́ nǹkan burúkú ni* fún ẹni tó ń jẹ oúnjẹ tó máa fa ìkọ̀sẹ̀.+ 21  Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.+ 22  Ìgbàgbọ́ tí o ní, jẹ́ kó wà láàárín ìwọ àti Ọlọ́run. Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í dá ara rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ohun tó tẹ́wọ́ gbà. 23  Àmọ́ tó bá ń ṣiyèméjì, a ti dá a lẹ́bi tó bá jẹ ẹ́, nítorí kò jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, gbogbo ohun tí kò bá ti bá ìgbàgbọ́ mu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “àwọn ohun tó ń kọ ọ́ lóminú.”
Tàbí “pa ẹni tí Kristi kú fún rẹ́.”
Tàbí “àmọ́ kò tọ̀nà.”