Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ̀yin Ni Ẹlẹ́rìí Mi”

“Ẹ̀yin Ni Ẹlẹ́rìí Mi”

“‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—AÍSÁ. 43:10.

TA NI a lè pè ní ẹlẹ́rìí? Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ẹlẹ́rìí ni: “Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣojú rẹ̀ tó sì ròyìn ohun tó rí.” Bí àpẹẹrẹ, ó ti lé ní ọgọ́jọ [160] ọdún tí wọ́n ti ń tẹ ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń pè ní The Witness [Ẹlẹ́rìí] nílùú Pietermaritzburg, lórílẹ̀-èdè South Africa. Orúkọ ìwé ìròyìn yìí bá a mu gan-an, torí pé ohun tí ìwé ìròyìn wà fún ni pé kó máa gbé ìròyìn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé jáde bó ṣe ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́. Olùdásílẹ̀ ìwé ìròyìn The Witness ṣèlérí pé ìwé ìròyìn òun á máa sọ “òtítọ́, òkodoro òtítọ́, kò sí ni sọ ohun míì yàtọ̀ sí òtítọ́.”

1, 2. (a) Ta ni a lè pè ní ẹlẹ́rìí, kí ló sì fi hàn gbangba pé àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ayé ò kúnjú ìwọ̀n? (b) Kí nìdí tí Jèhófà kì í fi í gbẹnu àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ayé yìí sọ̀rọ̀?

2 Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ làwọn iléeṣẹ́ ìròyìn kì í sọ, wọ́n sì lè yí ọ̀rọ̀ náà pò, ká tiẹ̀ ní wọ́n sọ ọ́. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn tá a bá wo ohun tí Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára ńlá gbogbo sọ nípasẹ̀ Ísíkíẹ́lì, wòlíì rẹ̀ ìgbàanì pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 39:7) Àmọ́ o, Ọba Aláṣẹ tí í ṣe Olùṣàkóso ayé àtọ̀run kì í gbẹnu àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀. Ìdí sì ni pé ó ní àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ níbi gbogbo láyé, tí wọ́n ń sọ àwọn ohun tó ti ṣe fún aráyé, àtàwọn ohun tó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ògìdìgbó àwọn Ẹlẹ́rìí yìí tún ń kéde àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún aráyé. Bá a ṣe ń fi ọwọ́ gidi mú iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí, ṣe là ń fi hàn pé orúkọ tí Ọlọ́run fún wa nínú Aísáyà 43:10 ló ń rò wá. Ó ní: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’”

3, 4. (a) Ọdún wo ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ tuntun náà, báwo ló sì ṣe rí lára wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?

 3 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé kéèyàn máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, torí pe òun ni “Ọba ayérayé,” tó sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran”! (1 Tím. 1:17; Ẹ́kís. 3:15; fi wé Oníwàásù 2:16.) Ọdún 1931 ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ lẹ́tà tí àwọn ará kọ láti fi hàn pé àwọn mọyì orúkọ náà la tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn yìí. Ìjọ kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà kọ̀wé pé: “Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún wa nígbà tá a gbọ́ ìhìn rere náà pé ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà’ ni wá, ńṣe ló mú ká túbọ̀ pinnu lákọ̀tun pé a óò jẹ́ kí orúkọ tuntun náà máa rò wá.”

4 Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì àǹfààní tó o ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run? Yàtọ̀ síyẹn, ǹjẹ́ o lè fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi pè wá ní Ẹlẹ́rìí rẹ̀ nínú ìwé Aísáyà?

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ ỌLỌ́RUN LÁYÉ ỌJỌ́UN

5, 6. (a) Ọ̀nà wo làwọn òbí nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì gbà jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? (b) Kí tún ni Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí àwọn òbí nílẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe? Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àṣẹ yẹn kan àwọn òbí lónìí?

5 Nígbà ayé Aísáyà, ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan ló jẹ́ “ẹlẹ́rìí” fún Jèhófà, orílẹ̀-èdè náà lódindi sì jẹ́ “ìránṣẹ́” Ọlọ́run. (Aísá. 43:10) Ọ̀nà kan tí àwọn òbí nílẹ̀ Ísírẹ́lì gbà jẹ́rìí nípa Ọlọ́run ni bí wọ́n ṣe máa ń sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ń fún àwọn òbí ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe Ìrékọjá lọ́dọọdún, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá wí fún yín pé, ‘Kí ni iṣẹ́ ìsìn yìí túmọ̀ sí fún yín?’ nígbà náà, kí ẹ wí pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá ni sí Jèhófà, ẹni tí ó ré ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tí ó mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ará Íjíbítì, ṣùgbọ́n ó dá ilé wa nídè.’” (Ẹ́kís. 12:26, 27) Ó tún ṣeé ṣe kí àwọn òbí yẹn ṣàlàyé fún àwọn ọmọ wọn pé nígbà tí Mósè kọ́kọ́ lọ bá alákòóso Íjíbítì pé  kó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti lọ jọ́sìn Jèhófà nínú aginjù, Fáráò dáhùn pé: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀ láti rán Ísírẹ́lì lọ?” (Ẹ́kís. 5:2) Ó dájú pé wọ́n tún lè sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa bí Jèhófà ṣe dáhùn ìbéèrè Fáráò, tó sì mú kí gbogbo èèyàn mọ irú ẹni tí Òun jẹ́. Èyí ṣe kedere lẹ́yìn tó ti fi ìyọnu mẹ́wàá kọ lu ilẹ̀ náà tó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì ní Òkun Pupa. Ó ṣe kedere pé Jèhófà ni Olódùmarè nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti nísinsìnyí. Bákan náà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fojú ara wọn rí i pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, òun sì ni Ẹni tó ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

6 Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà náà á ròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yẹn fún àwọn ọmọ wọn. Kì í ṣèyẹn nìkan, wọ́n á tún ròyìn rẹ̀ fún àwọn àtìpó tó ń sìnrú nínú ilé wọn. Ohun míì tó tún ṣe pàtàkì ni pé, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìjẹ́mímọ́. Jèhófà sọ pé: “Kí ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” (Léf. 19:2; Diu. 6:6, 7) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí lónìí! Ìdí sì ni pé àwọn náà gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn láti jẹ́ mímọ́, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bọlá fún orúkọ ológo Ọlọ́run.—Ka Òwe 1:8; Éfésù 6:4.

Tá a bá ń kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Jèhófà ńṣe là ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6)

7. (a) Ní gbogbo ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ipa wo ló máa ń ní lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká? (b) Ojúṣe wo ni gbogbo àwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run ní?

7 Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe ohun tó tọ́, ṣe ni wọ́n máa ń jẹ́rìí nípa orúkọ Ọlọ́run. Ọlọ́run sì ti sọ fún wọn pé: “Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni a fi ń pè ọ́, àyà rẹ yóò sì máa fò wọ́n ní tòótọ́.” (Diu. 28:10) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ìwà àìṣòótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hù lọ́pọ̀ ìgbà. Léraléra ni wọ́n ń yí pa dà láti máa bọ àwọn òrìṣà. Bákan náà, wọ́n tún ń hùwà ìkà bíi ti àwọn òrìṣà ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n ń bọ, tó fi jẹ́ pé wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ tí wọ́n sì ń fayé ní àwọn òtòṣì lára. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá lèyí jẹ́ fún wa pé ká máa sapá nígbà gbogbo láti wà ní mímọ́ bíi ti Ẹni Mímọ́ Jù Lọ náà tá à ń jẹ́ orúkọ mọ́!

“WÒ Ó! ÈMI YÓÒ ṢE OHUN TUNTUN KAN”

8. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé lé Aísáyà lọ́wọ́, báwo ló sì ṣe rí lára Aísáyà?

8 Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́nà àgbàyanu kúrò lábẹ́ ìsìnrú, èyí tí wọ́n máa jẹ́rìí sí. (Aísá. 43:19) Ìkìlọ̀ nípa àwọn àjálù kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àtàwọn ìlú tó yí i ká ló kún inú orí mẹ́fà àkọ́kọ́ nínú ìwé Aísáyà. Jèhófà tó máa ń rí ohun tó wà lọ́kàn sọ fún Aísáyà pé kó máa kéde ìkìlọ̀ rẹ̀ nìṣó fáwọn èèyàn náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé alágídí ni wọ́n, tí wọ́n sì máa kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ wòlíì rẹ̀. Ó ya Aísáyà lẹ́nu ó sì fẹ́ mọ bó ṣe máa pẹ́ tó tí àwọn èèyàn náà á fi wà láìronú pìwà dà. Kí ni Ọlọ́run fi dá a lóhùn? Ó ní: “Títí àwọn ìlú ńlá náà yóò fi fọ́ bàjẹ́ ní tòótọ́, tí wọn yóò fi wà láìsí olùgbé, tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ará ayé, tí a ó sì run ilẹ̀ pàápàá di ahoro.”—Ka Aísáyà 6:8-11.

9. (a) Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ nípa Jerúsálẹ́mù ṣẹ? (b) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí, tó gba pé ká wà lójúfò?

9 Nǹkan bí ọdún 778 ṣáájú Sànmánì Kristẹni tàbí ọdún tí Ùsáyà Ọba lò kẹ́yìn lórí oyè, ni Jèhófà gbéṣẹ́ lé Aísáyà lọ́wọ́. Nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] ló sì fi ṣe iṣẹ́ wòlíì náà, ìyẹn títí di ọdún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ní àsìkò tí Hesekáyà Ọba wà lórí ìtẹ́. Tá a bá ṣírò ìgbà tó parí iṣẹ́ rẹ̀ sí ìgbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó jẹ́ ọdún márùnlélọ́gọ́fà [125]. Èyí fi hàn pé ó pẹ́ tí Ọlọ́run ti jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè wọn.  Bákan náà lóde òní, ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń mú kí àwa èèyàn rẹ̀ máa kéde ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó ti pé ọdún márùnléláàádóje [135] báyìí tí Ilé Ìṣọ́ àkọ́kọ́ ti sọ fún àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn náà pé kí wọ́n fi sọ́kàn pé ìṣàkóso búburú Sátánì máa tó dópin, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi yóò sì rọ́pò rẹ̀.—Ìṣí. 20:1-3, 6.

10, 11. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ wo ló ṣẹ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Bábílónì?

10 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó ṣègbọràn nípa jíjọ̀wọ́ ara wọn fún àwọn ará Bábílónì la ìparun Jerúsálẹ́mù já, àwọn ará Bábílónì sì kó wọn nígbèkùn. (Jer. 27:11, 12) Lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà ní Bábílónì, àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu kan ní ìmúṣẹ lójú wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà yín, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì: ‘Nítorí yín, ṣe ni èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì, èmi yóò sì mú kí àwọn ọ̀pá ìdábùú ẹ̀wọ̀n kí ó wálẹ̀.’”—Aísá. 43:14.

11 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé kan ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ṣẹlẹ̀ pé ọba Bábílónì àtàwọn olóyè rẹ̀ ń fi àwọn ohun èlò mímọ́ tí wọ́n kó nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù mu ọtí, wọ́n sì ń gbógo fún àwọn òrìṣà lásánlàsàn. Ẹnu ìyẹn ni wọ́n wà nígbà tí àwọn ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà wọ ìlú Bábílónì, tí wọ́n sì ṣẹ́gun ìlú náà. Nígbà tó di ọdún 538 tàbí ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì tó ṣẹ́gun ìlú Bábílónì pàṣẹ pé kí àwọn Júù pa dà sílé láti lọ tún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Gbogbo èyí ni Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀, títí kan ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa pèsè fún àwọn èèyàn òun tó ronú pìwà dà, òun sì máa dáàbò bò wọ́n bí wọ́n ṣe ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run pè wọ́n ní “àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.” (Aísá. 43:21; 44:26-28) Nígbà tí àwọn ìgbèkùn tẹ́lẹ̀ rí yìí ti pa dà wálé tí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́, ó wá dá wọn lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, máa ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

12, 13. (a) Àwọn míì wo ló kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú mímú ìjọsìn Jèhófà pa dà bọ̀ sípò? (b) Kí ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ní láti ṣe bí wọ́n ṣe ń ti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” lẹ́yìn? Ìrètí wo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ní?

12 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè tuntun náà, lẹ́yìn ìgbà yẹn ni ọ̀pọ̀ àwọn míì tó jẹ́ Kèfèrí di Aláwọ̀ṣe Júù. (Ẹ́sírà 2:58, 64, 65; Ẹ́sít. 8:17) Lóde òní, tọkàntọkàn ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù fi ń ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí í ṣe “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” lẹ́yìn. (Ìṣí. 7:9, 10; Jòh. 10:16; Gál. 6:16) Àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ń bá wọn jẹ́ orúkọ tí Ọlọ́run fi pè wọ́n náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 13 Ìdùnnú á ṣubú láyọ̀ fún àwọn àgùntàn mìíràn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, torí pé àwọn ló máa ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Àmọ́ o, ìyẹn á ṣeé ṣe kìkì tá a bá ń jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá nísinsìnyí, tá a sì ń sapá láti wà ní mímọ́. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa bẹ Ọlọ́run lójoojúmọ́ pé kó dárí ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tá a bá hù jì wá torí pé, bó ti wù ká sapá tó, a ní láti gbà pé a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé àǹfààní ńlá tí kò láfiwé ló jẹ́ pé Ọlọ́run yọ̀ǹda fún wa láti máa jẹ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 1:8, 9.

KÍ NI ÌTUMỌ̀ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN?

14. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà?

14 Ká lè túbọ̀ mọyì àǹfààní tá a ní pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì ká ṣàṣàrò lórí ìtumọ̀ orúkọ náà. Wọ́n sábà máa ń túmọ̀ orúkọ náà sí “Jèhófà” látinú ọ̀rọ̀-ìṣe èdè Hébérù kan tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ohun téèyàn ń ṣe tí wọ́n sì lè túmọ̀ sí “láti di.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn gbà pé orúkọ náà, Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Àlàyé yìí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ipò Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run àtàwọn ẹ̀dá alààyè tó wà nínú wọn, òun náà si ni Ẹni tó ń mú ète rẹ̀ ṣẹ. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ń mú kí ète rẹ̀ àti ohun tó ní lọ́kàn di ṣíṣe. Kò sì sí ohun tí alátakò èyíkéyìí, irú bíi Sátánì, lè ṣe láti bẹ́gi dínà bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

15. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn nínú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀? (Wo àpótí náà, “ Orúkọ Tí Ìtumọ̀ Rẹ̀ Pọ̀.”)

15 Nígbà tí Jèhófà yan Mósè pé kó lọ kó àwọn èèyàn òun jáde ní Íjíbítì, ó mú ká mọ apá kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ nígbà tó lo ọ̀rọ̀-ìṣe míì láti ṣàpèjúwe orúkọ rẹ̀, ó sì pé ọ̀rọ̀ náà mọ́ ara rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: ‘ÈMI YÓÒ JẸ́ OHUN TÍ ÈMI YÓÒ JẸ́.’ Ó sì fi kún un pé: ‘Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, “ÈMI YÓÒ JẸ́ ti rán mi sí yín.”’” (Ẹ́kís. 3:14) Nípa bẹ́ẹ̀, lábẹ́ ipò èyíkéyìí, Jèhófà máa ṣe ohunkóhun tó bá gbà pé kó ṣe láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Ó sọ ara rẹ̀ di Olùdáǹdè, Olùdáàbòbò àti Atọ́nisọ́nà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ẹrú tẹ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ Olùpèsè tó tẹ́ wọn lọ́rùn dáadáa nípa tara àti nípa tẹ̀mí.

BÍ A ṢE LÈ FI ÌMỌRÍRÌ HÀN

16, 17. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

16 Jèhófà ṣì ń fi hàn títí dòní pé Alèwílèṣe lòun ni ti pé ó ń fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run kọjá ohun tí òun alára lè jẹ́ tàbí tó lè sọ ara rẹ̀ dì. Ó tún kan ohun tó ń mú kó ṣẹlẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ń ṣe láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí kókó yìí, á mú ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó yẹ orúkọ rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Arákùnrin Kåre, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] nìyẹn. Orílẹ̀-èdè Norway ni Ẹlẹ́rìí onítara yìí ń gbé, àádọ́rin [70] ọdún sì rèé tó ti wà nínú òtítọ́, ó sọ pé: “Mo gbà pé ọlá ńlá ló jẹ́ pé kéèyàn máa sin Jèhófà, Ọba ayérayé, kéèyàn sì wà lára àwọn èèyàn tá à ń fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ pè. Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ nígbàkigbà téèyàn bá ń ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn tó sì hàn lójú wọn pé inú wọn dùn àti pé wọ́n lóye ohun tí wọ́n kọ́. Bí àpẹẹrẹ, inú mi máa ń dùn nígbà tí mo bá ń kọ́ wọn nípa iṣẹ́ tí ẹbọ ìràpadà Kristi ń ṣe, àti bó ṣe jẹ́ pé nípasẹ̀ rẹ̀, a máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun kan tí àlàáfíà àti òdodo ti máa gbilẹ̀.”

17 Ká sòótọ́, àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan wà tó ti túbọ̀ ń ṣòro láti rí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àtikẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Àmọ́, bíi ti Kåre, ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn tó o bá rẹ́ni gbọ́rọ̀ rẹ tó o sì kọ́ onítọ̀hún nípa orúkọ Jèhófà? Àmọ́, báwo la ṣe lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ká sì tún jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jésù? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ni kókó tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.