Ẹ́kísódù 3:1-22

  • Mósè àti igi ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó (1-12)

  • Jèhófà sọ ìtúmọ̀ orúkọ Rẹ̀ (13-15)

  • Jèhófà fún Mósè ní ìtọ́ni (16-22)

3  Mósè ń bójú tó agbo ẹran Jẹ́tírò+ bàbá ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ àlùfáà Mídíánì. Nígbà tó ń da agbo ẹran náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn aginjù, ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run tòótọ́.+  Áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú ọwọ́ iná tó ń jó láàárín igi ẹlẹ́gùn-ún kan.+ Bó ṣe ń wò ó, ó rí i pé iná ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún náà, síbẹ̀ igi náà ò jóná.  Mósè wá sọ pé: “Jẹ́ kí n lọ wo nǹkan àrà yìí, kí n lè mọ ohun tí kò jẹ́ kí igi ẹlẹ́gùn-ún náà jóná.”  Nígbà tí Jèhófà rí i pé ó lọ wò ó, Ọlọ́run pè é látinú igi ẹlẹ́gùn-ún náà pé: “Mósè! Mósè!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.”  Ó wá sọ pé: “Má ṣe sún mọ́ ibí yìí. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.”  Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run bàbá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù.”+ Ni Mósè bá fojú pa mọ́, torí ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọ́run tòótọ́.  Jèhófà sì sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.+  Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+  Wò ó! Mo ti gbọ́ igbe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì ti rí bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fìyà jẹ wọ́n gidigidi.+ 10  Ní báyìí, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, wàá sì mú àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.”+ 11  Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ta ni mo jẹ́, tí màá fi lọ bá Fáráò, tí màá sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì?” 12  Ó fèsì pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ ohun tí yóò sì jẹ́ àmì fún ọ pé èmi ni mo rán ọ nìyí: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn èèyàn náà kúrò ní Íjíbítì, ẹ máa jọ́sìn* Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè yìí.”+ 13  Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ká ní mo lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí mo sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì bi mí pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’+ Kí ni kí n sọ fún wọn?” 14  Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.”*+ Ó sì sọ pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Èmi Yóò Di ti rán mi sí yín.’”+ 15  Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí. 16  Wá lọ, kí o kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fara hàn mí, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, ó sì sọ pé: “Mo ti kíyè sí yín,+ mo sì ti rí ohun tí wọ́n ń ṣe sí yín ní Íjíbítì. 17  Torí náà, mo ṣèlérí pé màá gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fìyà jẹ yín,+ màá sì mú yín lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì,+ àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ sí ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.”’+ 18  “Ó dájú pé wọ́n á fetí sí ohùn rẹ,+ ìwọ àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò lọ bá ọba Íjíbítì, ẹ ó sì sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù+ ti bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ ká rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká lè rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.’+ 19  Àmọ́ èmi fúnra mi mọ̀ dáadáa pé ọba Íjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ àfi tí mo bá fi ọwọ́ agbára mú un.+ 20  Ṣe ni màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Íjíbítì nípasẹ̀ gbogbo nǹkan àgbàyanu tí màá ṣe níbẹ̀, lẹ́yìn náà, á jẹ́ kí ẹ lọ.+ 21  Màá mú kí àwọn èèyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, tí ẹ bá sì ń lọ, ó dájú pé ẹ ò ní lọ lọ́wọ́ òfo.+ 22  Kí obìnrin kọ̀ọ̀kan béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ àti obìnrin tó ń gbé nílé rẹ̀, kí ẹ sì fi wọ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin yín; ẹ ó sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “sin.”
Tàbí “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Yàn; Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” Wo Àfikún A4.