Diutarónómì 6:1-25

  • Fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà (1-9)

    • “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì” (4)

    • Kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn (6, 7)

  • Ẹ má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-15)

  • Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà wò (16-19)

  • Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín (20-25)

6  “Èyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi lélẹ̀ láti kọ́ yín, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ tí ẹ bá ti sọdá sí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà,  kí ẹ lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin àti àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín mọ́, ẹ̀yin àti ọmọ yín àti ọmọ ọmọ yín,+ ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ̀mí yín lè gùn.+  Kí o fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì rí i pé ò ń pa wọ́n mọ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́.  “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.+  Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ+ àti gbogbo okun rẹ*+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.  Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn,  kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+  So ó mọ́ ọwọ́ rẹ bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí rẹ.*+  Kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sí àwọn ẹnubodè rẹ. 10  “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé òun máa fún ọ,+ àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ,+ 11  àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, tí o jẹ, tí o sì yó,+ 12  rí i pé o ò gbàgbé Jèhófà,+ ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú. 13  Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù,+ òun ni kí o máa sìn,+ orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra.+ 14  Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, èyíkéyìí nínú ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká,+ 15  torí Ọlọ́run tó fẹ́ kí á máa sin òun nìkan ṣoṣo ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ+ tó wà láàárín rẹ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí ọ gidigidi,+ yóò sì pa ọ́ run kúrò lórí ilẹ̀.+ 16  “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò,+ bí ẹ ṣe dán an wò ní Másà.+ 17  Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín mọ́ délẹ̀délẹ̀ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀, tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa tẹ̀ lé. 18  Kí o máa ṣe ohun tó tọ́, tó sì dáa ní ojú Jèhófà, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o lè wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ nípa rẹ̀, kí o sì gbà á,+ 19  nígbà tí o bá lé gbogbo ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.+ 20  “Lọ́jọ́ iwájú, tí ọmọ rẹ bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìránnilétí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín?’ 21  kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì. 22  Ojú wa ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó lágbára tó sì ń ṣọṣẹ́ kọ lu Íjíbítì,+ Fáráò àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+ 23  Ó sì mú wa kúrò níbẹ̀, kó lè mú wa wá síbí láti fún wa ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá wa nípa rẹ̀.+ 24  Jèhófà wá pàṣẹ fún wa pé ká máa tẹ̀ lé gbogbo ìlànà yìí, ká sì máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa fún àǹfààní ara wa títí lọ,+ ká lè máa wà láàyè+ bí a ṣe wà láàyè títí dòní. 25  A ó sì kà wá sí olódodo tí a bá rí i pé gbogbo àṣẹ yìí là ń pa mọ́ láti fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí* Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe pa á láṣẹ fún wa.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “okunra rẹ; ohun tí o ní.”
Tàbí “tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ọmọ rẹ; tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn.”
Ní Héb., “láàárín ojú rẹ.”
Ní Héb., “là ń pa mọ́ níwájú.”