Oníwàásù 2:1-26

  • Àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí Sólómọ́nì ṣe (1-11)

  • Ó níbi tí ọgbọ́n èèyàn wúlò dé (12-16)

  • Asán tó wà nínú iṣẹ́ àṣekára (17-23)

  • Máa jẹ, máa mu, kí o sì gbádùn iṣẹ́ rẹ (24-26)

2  Nígbà náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Wá, jẹ́ kí n dán ìgbádùn* wò, kí n sì rí ohun rere tó máa tibẹ̀ wá.” Àmọ́ wò ó! asán ni èyí pẹ̀lú.   Mo sọ nípa ẹ̀rín pé, “Wèrè ni!” Àti nípa ìgbádùn* pé, “Kí ni ìwúlò rẹ̀?”  Mo mu wáìnì,+ kí n lè fi ọkàn mi ṣèwádìí, àmọ́ ní gbogbo àkókò yìí mi ò sọ ọgbọ́n mi nù; kódà, mo fara mọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ kí n lè rí ohun tó dáa jù lọ fún ọmọ aráyé láti máa ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa lò lábẹ́ ọ̀run.  Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá.+ Mo kọ́ àwọn ilé fún ara mi;+ mo gbin àwọn ọgbà àjàrà fún ara mi.+  Mo ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àti ọgbà ìtura fún ara mi, mo sì gbin oríṣiríṣi igi eléso sínú wọn.  Mo ṣe àwọn adágún omi fún ara mi, láti máa fi bomi rin ọgbà* tí àwọn igi tó léwé dáadáa wà.  Mo ní àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin,+ mo sì ní àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n bí ní agbo ilé mi.* Mo tún ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn, ìyẹn màlúù àti agbo ẹran,+ tó pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.  Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi,+ ìṣúra* àwọn ọba àti ti àwọn ìpínlẹ̀.+ Mo kó àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin jọ fún ara mi, títí kan ohun tó ń múnú ọmọ aráyé dùn gidigidi, ìyẹn obìnrin, àní ọ̀pọ̀ obìnrin.*  Torí náà, mo dẹni ńlá, mo sì ga ju gbogbo àwọn tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.+ Bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. 10  Mi ò fi ohunkóhun tí mo fẹ́* du ara mi.+ Kò sí irú ìgbádùn* tí ọkàn mi fẹ́ tí mi ò fún un, torí ọkàn mi ń yọ̀ nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi, èyí sì ni èrè* mi nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi.+ 11  Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe àti gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti sapá láti ṣe yọrí,+ mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo;*+ kò sí ohun gidi kan* lábẹ́ ọ̀run.*+ 12  Mo wá fiyè sí ọgbọ́n àti ìwà wèrè àti ìwà ẹ̀gọ̀.+ (Kí ni ẹni tó máa wá lẹ́yìn ọba lè ṣe? Ohun tí àwọn èèyàn ti ṣe tẹ́lẹ̀ ni.) 13  Mo rí i pé àǹfààní wà nínú ọgbọ́n ju ìwà ẹ̀gọ̀ lọ,+ bí àǹfààní ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀ ju òkùnkùn lọ. 14  Ojú ọlọ́gbọ́n wà ní orí rẹ̀;*+ àmọ́ òmùgọ̀ ń rìn nínú òkùnkùn.+ Mo sì wá rí i pé ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ 15  Lẹ́yìn náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà.”+ Kí wá ni èrè ọgbọ́n tí mo gbọ́n ní àgbọ́njù? Mo sì sọ lọ́kàn mi pé: “Asán ni èyí pẹ̀lú.” 16  Nítorí a kì í rántí ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀ títí lọ.+ Bó pẹ́ bó yá, a ò ní rántí ẹnikẹ́ni mọ́. Báwo sì ni ọlọ́gbọ́n ṣe máa kú? Á kú pẹ̀lú àwọn òmùgọ̀.+ 17  Ayé wá sú mi,+ nítorí gbogbo ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run* ló ń kó ìdààmú báni lójú tèmi, torí asán ni gbogbo rẹ̀,+ ìmúlẹ̀mófo.*+ 18  Mo wá kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,*+ torí mo gbọ́dọ̀ fi í sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.+ 19  Ta ló sì mọ̀ bóyá ó máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀?+ Síbẹ̀, òun ni yóò máa darí gbogbo ohun tí mo ti fi akitiyan àti ọgbọ́n kó jọ lábẹ́ ọ̀run.* Asán ni èyí pẹ̀lú. 20  Torí náà, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo fi gbogbo agbára mi ṣe lábẹ́ ọ̀run.* 21  Nítorí èèyàn lè fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti òye ṣiṣẹ́ ní àṣekára, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi èrè rẹ̀* sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́ fún un.+ Asán ni èyí pẹ̀lú àti àdánù* ńlá. 22  Kí tiẹ̀ ni èrè tí èèyàn rí jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti gbogbo bó ṣe ń wù ú* láti ṣiṣẹ́ kára lábẹ́ ọ̀run?*+ 23  Torí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ ń mú ìrora àti ìjákulẹ̀ bá a,+ kódà kì í rí oorun sùn lóru.+ Asán ni èyí pẹ̀lú. 24  Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì gbádùn* iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.+ Èyí pẹ̀lú ni mo ti rí pé ó wá láti ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ 25  àbí ta ló ń jẹ, tó sì ń mu ohun tó dáa ju tèmi lọ?+ 26  Ọlọ́run ń fún ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìdùnnú,+ àmọ́ ó ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ kíkó jọ àti ṣíṣà jọ kí wọ́n lè fún ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo* sì ni.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “igbó.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ilé.”
Tàbí “dúkìá tó jẹ́ ti.”
Tàbí “ọmọge, àní àwọn ọmọge.”
Ní Héb., “tí ojú mi béèrè.”
Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “ohun tó ṣàǹfààní.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “Ọlọ́gbọ́n la ojú rẹ̀ sílẹ̀.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “gbogbo rẹ̀.”
Tàbí “àjálù.”
Ní Héb., “bí ọkàn rẹ̀ ṣe ń sapá.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ rí ohun rere nínú.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”