Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 20:1-15

  • A de Sátánì fún 1,000 ọdún (1-3)

  • Àwọn tó máa jọba pẹ̀lú Kristi fún 1,000 ọdún (4-6)

  • A tú Sátánì sílẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn náà, a pa á run (7-10)

  • A ṣèdájọ́ àwọn òkú níwájú ìtẹ́ náà (11-15)

20  Mo rí i tí áńgẹ́lì kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀  + àti ẹ̀wọ̀n ńlá dání.  Ó gbá dírágónì náà+ mú, ejò àtijọ́ náà,+ òun ni Èṣù+ àti Sátánì,+ ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.  Ó jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,+ ó tì í, ó sì gbé èdìdì lé ibi àbáwọlé rẹ̀, kó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà fi máa parí. Lẹ́yìn èyí, a gbọ́dọ̀ tú u sílẹ̀ fúngbà díẹ̀.+  Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.  (Àwọn òkú yòókù+ ò pa dà wà láàyè títí dìgbà tí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà parí.) Èyí ni àjíǹde àkọ́kọ́.+  Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́;+ ikú kejì+ kò ní àṣẹ lórí wọn,+ àmọ́ wọ́n máa jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.+  Gbàrà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá parí, a máa tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀,  ó sì máa jáde lọ láti ṣi àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọ fún ogun náà. Wọ́n pọ̀ níye bí iyanrìn òkun.  Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ayé, wọ́n sì wà yí ká ibùdó àwọn ẹni mímọ́ àti ìlú tí a fẹ́ràn. Àmọ́ iná wá láti ọ̀run, ó sì jó wọn run.+ 10  A sì ju Èṣù tó ń ṣì wọ́n lọ́nà sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko  + náà àti wòlíì èké náà wà;+ wọ́n á sì máa joró* tọ̀sántòru títí láé àti láéláé. 11  Mo rí ìtẹ́ funfun kan tó tóbi àti Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀.+ Ayé àti ọ̀run sá kúrò níwájú rẹ̀,+ kò sì sí àyè kankan fún wọn. 12  Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 13  Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 14  A sì ju ikú àti Isà Òkú* sínú adágún iná.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì,+ adágún iná náà.+ 15  Bákan náà, a ju ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè+ sínú adágún iná náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀ àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Ifi 6:9.
Ní Grk., “àwọn tí wọ́n fi àáké pa.”
Tàbí “dè wọ́n; fi wọ́n ṣẹ́wọ̀n.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.