Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe

ÌWÉ Ìṣe inú Bíbélì sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn nípa bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe ń gbilẹ̀. Lúùkù oníṣègùn ló kọ ìwé Ìṣe yìí, ó sì jẹ́ àkọsílẹ̀ tó wúni lórí nípa ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni láàárín ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, èyí tó bẹ̀rẹ̀ látọdún 33 Sànmánì Kristẹni sí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni.

Apá àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣe dá lórí ìgbòkègbodò àpọ́sítélì Pétérù, apá kejì sì dá lórí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bí Lúùkù ṣe ń lo àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ bí “a” àti “àwa” fi hàn pé ojú rẹ̀ láwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìwé náà ṣẹlẹ̀. Tá a bá fiyè sáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣe, á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ní. (Héb. 4:12) Á tún jẹ́ ká máa lo ara wa gan-an nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, yóò sì mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ìjọba Ọlọ́run lágbára sí i.

PÉTÉRÙ LO “ÀWỌN KỌ́KỌ́RỌ́ ÌJỌBA Ọ̀RUN”

(Ìṣe 1:1–11:18)

Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àpọ́sítélì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láìṣojo. Pétérù wá lo àkọ́kọ́ nínú “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run” láti fi jẹ́ káwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n “fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀” ní ìmọ̀ àti àǹfààní tí wọ́n á fi lè wọ Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 16:19; Ìṣe 2:5, 41) Inúnibíni ńlá tó bẹ́ sílẹ̀ tú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ká, àmọ́ ńṣe ló jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ gbòòrò sí i.

Báwọn àpọ́sítélì ní Jerúsálẹ́mù ṣe gbọ́ pé àwọn ará Samáríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ sọ́dọ̀ wọn. Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ kejì nígbà tó wàásù fáwọn ará Samáríà tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní láti lè wọ Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 8:14-17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láàárín ọdún kan lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ni ìgbésí ayé Sọ́ọ̀lù ará Tásù yí padà tó sì di Kristẹni. Ọdún 36 Sànmánì Kristẹni ni Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ kẹta, tí Ọlọ́run sì tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ aláìdádọ̀dọ́.—Ìṣe 10:45.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

2:44-47; 4:34, 35—Kí nìdí táwọn onígbàgbọ́ fi ta ohun ìní wọn tí wọ́n sì pín owó ohun tí wọ́n tà? Ọ̀nà jíjìn ni púpọ̀ lára àwọn tó di onígbàgbọ́ ti wá sí Jerúsálẹ́mù, wọn ò sì ní oúnjẹ tó pọ̀ tó èyí tí wọ́n á fi lè dúró pẹ́ níbẹ̀. Àmọ́, wọ́n ṣì fẹ́ dúró díẹ̀ kí wọ́n lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìjọsìn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yìí, kí wọ́n sì wàásù fáwọn ẹlòmíì. Láti lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, àwọn Kristẹni kan ta àwọn ohun ìní wọn, wọ́n sì pín owó rẹ̀ fáwọn tó jẹ́ aláìní.

4:13—Ṣé èèyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù ni Pétérù àti Jòhánù? Rárá o. Ìdí táwọn kan fi pè wọ́n ní “ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni pé wọn ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì láti lọ gba ẹ̀kọ́ ìsìn.

5:34-39—Báwo ni Lúùkù ṣe mọ ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ nínú àpérò tí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ṣe ní ìdákọ́ńkọ́? Ó kéré tán, ọ̀nà mẹ́ta kan wà tó lè gbà mọ̀ ọ́n: Àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù tó ti fìgbà kan kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì ló sọ fún Lúùkù; èkejì, ó ṣeé ṣe kí Lúùkù béèrè lọ́wọ́ èyí tó ṣeé sún mọ́ lára ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, irú bíi Nikodémù; ẹ̀kẹta, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nípa ìmísí Ọlọ́run ni Lúùkù fi mọ ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ.

7:59—Ṣé Jésù ni Sítéfánù ń gbàdúrà sí? Ó tì o, kò gbàdúrà sí Jésù. Jèhófà Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn, torí náà òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. (Lúùkù 4:8; 6:12) Sítéfánù sì ti máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lórúkọ Jésù látẹ̀yìn wá. (Jòh. 15:16) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Sítéfánù rí ìran kan tí ‘Ọmọ ènìyàn ti dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’ (Ìṣe 7:56) Nígbà tí Sítéfánù sì ti mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára láti jí òkú dìde, ó bá Jésù sọ̀rọ̀ ní tààràtà pé kó pa ẹ̀mí òun mọ́, àmọ́ kì í ṣe pé ó gbàdúrà sí i.—Jòh. 5:27-29.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

1:8. Iṣẹ́ ìwàásù táwọn olùjọsìn Jèhófà ń ṣe kárí ayé kò lè ṣeé ṣe láìsí ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́.

4:36–5:11. Jósẹ́fù ọmọ ìbílẹ̀ Kípírù ni àwọn àpọ́sítélì fún ní orúkọ àpèlé náà Bánábà, èyí tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú.” Ó lè jẹ́ torí pé ó jẹ́ ẹni tó láájò èèyàn àti onínúure tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ gan-an làwọn àpọ́sítélì ṣe ń pè é ní Bánábà. Ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Bánábà, ká má fi jọ Ananíà àti Sáfírà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ̀tàn, alágàbàgebè àti elétekéte.

9:23-25. Kì í ṣe ìwà ojo tá a bá fọgbọ́n yẹra fáwọn ọ̀tá ká bàa lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ.

9:28-30. Tí wíwàásù fáwọn èèyàn kan tàbí ní àgbègbè kan yóò bá jẹ́ ewu fún wa tàbí tó lè ṣàkóbá fún wa lọ́nàkọnà títí kan ọ̀nà ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ lo òye ká sì fọgbọ́n yan ìgbà àti ibi tá a ó ti máa wàásù fún wọn.

9:31. Ní àkókò àlàáfíà, ìyẹn àkókò tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí inúnibíni, ó yẹ ká sapá láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nípa ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò. Èyí ni yóò jẹ́ ká lè máa rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà, ká máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ká sì jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

PỌ́Ọ̀LÙ FÌTARA ṢE IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ̀

(Ìṣe 11:19–28:31)

Lọ́dún 44 Sànmánì Kristẹni, Ágábù lọ sílùú Áńtíókù níbi tí Sọ́ọ̀lù àti Bánábà ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ “fún odindi ọdún kan.” Ágábù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìyàn ńlá” kan, èyí tó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjì. (Ìṣe 11:26-28) “Lẹ́yìn tí [Sọ́ọ̀lù àti Bánábà] ti parí iṣẹ́ ní kíkún lórí ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ní Jerúsálẹ́mù,” wọ́n padà sí Áńtíókù. (Ìṣe 12:25) Lọ́dún 47 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún méjìlá lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni, ẹ̀mí mímọ́ rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì. (Ìṣe 13:1-4) Nígbà tó di ọdún 48 Sànmánì Kristẹni, wọ́n padà sí Áńtíókù “níbi tí a ti fi wọ́n sábẹ́ ìtọ́jú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Ìṣe 14:26.

Oṣù mẹ́sàn án lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù (tá a tún mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù) mú Sílà tí wọ́n jọ lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì. (Ìṣe 15:40) Tímótì àti Lúùkù sì lọ bá Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn àjò yẹn nígbà tó yá. Ìlú Fílípì ni Lúùkù dúró sí, tí Pọ́ọ̀lù fi lọ sí ìlú Áténì, tó sì tún wá lọ sí Kọ́ríńtì níbi tó ti pàdé Ákúílà àti Pírísílà, ó sì lo ọdún kan àtààbọ̀ níbẹ̀. (Ìṣe 18:11) Nígbà tó di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 52 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù mú Ákúílà àti Pírísílà wọ́n sì jọ wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Síríà, àmọ́ ó fi Tímótì àti Sílà sílẹ̀ ní Kọ́ríńtì. (Ìṣe 18:18) Ákúílà àti Pírísílà tẹ̀ lé e dé ìlú Éfésù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.

Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù lo àkókò díẹ̀ ní ìlú Síríà ti Áńtíókù lọ́dún 52 Sànmánì Kristẹni, ó wá gbéra ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta. (Ìṣe 18:23) “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá” ní ìlú Éfésù. (Ìṣe 19:20) Pọ́ọ̀lù sì lo nǹkan bí ọdún mẹ́ta níbẹ̀. (Ìṣe 20:31) Nígbà tó fi máa di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù ti wà ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n sì fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù, ó fìgboyà wàásù fáwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba. Nílùú Róòmù, wọ́n fòfin de Pọ́ọ̀lù pé kò gbọ́dọ̀ jáde nínú ilé (ní nǹkan bí ọdún 59 sí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni), àmọ́, ó ṣì wá ọ̀nà láti máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń kọ́ni ní “àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa.”—Ìṣe 28:30, 31.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

14:8-13—Kí nìdí táwọn ará Lísírà fi pe ‘Bánábà ní Súúsì tí wọ́n sì pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì’? Nínú ìtàn àròsọ àwọn ará Gíríìkì, wọ́n gbà pé Súúsì ni olùṣàkóso àwọn òòṣà, àti pé Hẹ́mísì ọmọ rẹ̀ jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Torí pé Pọ́ọ̀lù ló máa ń sọ̀rọ̀ jù làwọn ará Lísírà ṣe pè é ní Hẹ́mísì, tí wọ́n sì pe Bánábà ní Súúsì.

16:6, 7—Kí nìdí tí ẹ̀mí mímọ́ kò fi jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wàásù ní àgbègbè Éṣíà àti Bítíníà? Ohun tó fà á ni pé àwọn oníwàásù díẹ̀ ló wà. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé, ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa tẹ́tí sí ìhìn rere ni ẹ̀mí mímọ́ darí wọn lọ.

18:12-17—Torí kí ni Gálíò Alákòóso Ìbílẹ̀ kò fi dá sí i nígbà táwọn kan ń lu Sótínésì? Gálíò lè máa rò ó pé ìyà tó tọ́ sí Sótínésì ló ń jẹ, bóyá nítorí ó rò pé òun ló kó àwọn èèyàn sòdí láti gbéjà ko Pọ́ọ̀lù. Àmọ́ ṣá o, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí yọrí sí rere, nítorí ó jọ pé ó wà lára ohun tó jẹ́ kí Sótínésì di Kristẹni. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù pè é ní “arákùnrin wa.”—1 Kọ́r. 1:1.

18:18—Ẹ̀jẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀jẹ́ Násírì ni. (Núm. 6:1-21) Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò sọ ohun tí ẹ̀jẹ́ náà jẹ́. Bákan náà, Ìwé Mímọ́ kò sọ bóyá Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kó tó di Kristẹni, kò sì sọ bóyá ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀jẹ́ náà ni tàbí bóyá ó fẹ́ parí rẹ̀. Ohun yòówù kó jẹ́, kò dẹ́ṣẹ̀ kankan bó ṣe jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

12:5-11. A lè gbàdúrà fáwọn ará wa, ó sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀.

12:21-23; 14:14-18. Hẹ́rọ́dù gba ògo tó jẹ́ ti Ọlọ́run láìjanpata. Ẹ ò rí bí ìyẹn ti yàtọ̀ tó sí bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe yára kọ ìyìn àti ògo tí kò tọ́ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ máa wá bá a ṣe máa gbògo lórí àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

14:5-7. Tá a bá ń lo ọgbọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, a ó lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó.—Mát. 10:23.

14:22. Àwọn Kristẹni mọ̀ pé àwọn lè ní ìpọ́njú. Àmọ́, wọn kì í gbìyànjú láti yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tó ta ko ìgbàgbọ́ wọn.—2 Tím. 3:12.

16:1, 2. Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni máa fìtara ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní orúkọ rere nínú ìjọ.

16:3. A gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe, lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu, láti rí i pé àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere.—1 Kọ́r. 9:19-23.

20:20, 21. Iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé jẹ́ apá pàtàkì lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

20:24; 21:13. Jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ṣe pàtàkì jú dídáàbò bo ẹ̀mí wa lọ.

21:21-26. Ó yẹ ká máa tètè gba ìmọ̀ràn rere.

25:8-12. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní lè lo ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin lẹ́nu “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”—Fílí. 1:7.

26:24, 25. A gbọ́dọ̀ máa sọ “àwọn àsọjáde tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ti ìyèkooro èrò inú” bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú “ènìyàn ti ara.”—1 Kọ́r. 2:14.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ìgbà wo ni Pétérù lo “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Iṣẹ́ ìwàásù tá a ń ṣe kárí ayé kò lè ṣeé ṣe láìsí ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́