Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Wọ́n Máa Tó Ṣẹlẹ̀

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Wọ́n Máa Tó Ṣẹlẹ̀

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Wọ́n Máa Tó Ṣẹlẹ̀

TÍ DÓKÍTÀ kan bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an lára rẹ, àmọ́ o gbọ́ pé kò tíì ṣe irú iṣẹ́ abẹ yẹn rí, ṣé ọkàn rẹ máa balẹ̀? Rárá. Ṣùgbọ́n, ká ní o gbọ́ pé dókítà yìí ló mọṣẹ́ jù láàárín àwọn tó ń ṣe irú iṣẹ́ abẹ yẹn, àti pé àìmọye irú rẹ̀ ló ti ṣe láṣeyọrí ńkọ́? Ǹjẹ́ ọkàn rẹ kò ní balẹ̀ pé dókítà náà máa lè ran ìwọ náà lọ́wọ́?

Ayé tí a wà yìí dà bí aláìsàn tó nílò iṣẹ́ abẹ tó lágbára. Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí fún wa nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun yóò sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè pa dà. (2 Pétérù 3:13) Àmọ́ kí ìyẹn tó lè ṣẹlẹ̀, ìwà ibi gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ di àwátì pátápátá. (Sáàmù 37:9-11; Òwe 2:21, 22) Ọlọ́run máa mú gbogbo ipò tó burú jáì tí à ń rí nínú ayé lónìí kúrò kí ayé tó lè pa dà di Párádísè. Iṣẹ́ ìyanu nìkan ló lè mú kí gbogbo èyí ṣẹlẹ̀.—Ìṣípayá 21:4, 5.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé àwọn ìyípadà ńláǹlà yìí máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Kí nìdí tí a fi gbà bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn jẹ́ ẹ̀rí pé ó ní agbára láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Wo mẹ́fà péré lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì àti àwọn ìlérí tí wọ́n fi hàn pé ó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.

A rọ̀ ọ́ pé kó o máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹ fún àǹfààní wa lọ́jọ́ iwájú. Bí ìgbàgbọ́ rẹ bá ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí rẹ á túbọ̀ máa dájú sí i, ìyẹn ìrètí pé wàá wà lára àwọn tó máa jàǹfààní nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà máa tó ṣe.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9, 10]

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ FI ÌṢÙ BÚRẸ́DÌ ÀTI ẸJA MÉLÒÓ KAN PÉRÉ BỌ́ ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN ÈÈYÀN NÍ ÀBỌ́YÓ.​MÁTÍÙ 14:13-21; MÁÀKÙ 8:1-9; JÒHÁNÙ 6:1-14.

ÌLÉRÍ:

“Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”​—SÁÀMÙ 67:6.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

EBI KÒ NÍ PA ẸNIKẸ́NI MỌ́ LÁÉ.

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ LA OJÚ AFỌ́JÚ.​MÁTÍÙ 9:27-31; MÁÀKÙ 8:22-26.

ÌLÉRÍ:

“Ojú àwọn afọ́jú yóò là.”​—AÍSÁYÀ 35:5.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

GBOGBO ÀWỌN AFỌ́JÚ YÓÒ RÍRAN.

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ MÚ ÀWỌN ALÁÀBỌ̀ ARA LÁRA DÁ.​MÁTÍÙ 11:5, 6; JÒHÁNÙ 5:3-9.

ÌLÉRÍ:

“Ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.”​—AÍSÁYÀ 35:6.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

ARA GBOGBO ALÁÀBỌ̀ ARA YÓÒ DÁ ṢÁṢÁ.

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ WO ORÍṢIRÍṢI ÀÌSÀN SÀN.​MÁÀKÙ 1:32-34; LÚÙKÙ 4:40.

ÌLÉRÍ:

“Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”​—AÍSÁYÀ 33:24.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

ỌLỌ́RUN YÓÒ MÚ GBOGBO ÀÌSÀN BURÚKÚ KÚRÒ. A MÁA NÍ ÌLERA PÍPÉ.

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ MÚ KÍ ÒKUN, AFẸ́FẸ́ ÀTI ÌJÌ LÍLE PA RỌ́RỌ́.​—MÁTÍÙ 8:23-27; LÚÙKÙ 8:22-25.

ÌLÉRÍ:

“Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán.”​—AÍSÁYÀ 65:21, 23.

“Ìwọ yóò jìnnà réré sí ìnilára​—nítorí tí ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìkankan—​àti sí ohunkóhun tí ń jáni láyà, nítorí pé kì yóò sún mọ́ ọ.”​—AÍSÁYÀ 54:14.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

OMÍYALÉ, ÌJÌ, ÌMÌTÌTÌ ILẸ̀ ÀTI BẸ́Ẹ̀ BẸ́Ẹ̀ LỌ, KÒ NÍ SÍ MỌ́.

IṢẸ́ ÌYANU:

JÉSÙ JÍ ÀWỌN ÒKÚ DÌDE.​—MÁTÍÙ 9:18-26; LÚÙKÙ 7:11-17.

ÌLÉRÍ:

“Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.”​—JÒHÁNÙ 5:28, 29.

“Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.”​—ÌṢÍPAYÁ 20:13.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA:

ÀWỌN ÈÈYÀN WA TÓ TI KÚ YÓÒ JÍǸDE.