Àkọsílẹ̀ Lúùkù 7:1-50

  • Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun (1-10)

  • Jésù jí ọmọkùnrin opó Náínì dìde (11-17)

  • Ó yin Jòhánù Arinibọmi (18-30)

  • Ó dá ìran ọlọ́kàn líle lẹ́bi (31-35)

  • Ó dárí ji obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ (36-50)

    • Àpèjúwe àwọn tó jẹ gbèsè (41-43)

7  Nígbà tó parí gbogbo ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá àwọn èèyàn náà sọ, ó wọ Kápánáúmù.  Ẹrú ọ̀gágun kan, tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ràn gan-an ń ṣàìsàn gidigidi, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.+  Nígbà tí ọ̀gágun náà gbọ́ nípa Jésù, ó rán àwọn kan lára àwọn àgbààgbà àwọn Júù sí i, kí wọ́n sọ fún un pé kó wá, kó lè mú ẹrú òun lára dá.  Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ taratara, wọ́n ní: “Ó yẹ lẹ́ni tí o lè ṣe é fún,  torí ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa, òun ló sì kọ́ sínágọ́gù wa.”  Torí náà, Jésù tẹ̀ lé wọn. Àmọ́ nígbà tó sún mọ́ ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà ti rán àwọn ọ̀rẹ́ pé kí wọ́n sọ fún un pé: “Ọ̀gá, má ṣèyọnu, torí mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀.+  Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ka ara mi sí ẹni tó yẹ láti wá sọ́dọ̀ rẹ. Àmọ́, sọ̀rọ̀, kí o sì jẹ́ kí ara ìránṣẹ́ mi yá.  Torí èmi náà wà lábẹ́ àṣẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ àṣẹ mi, tí mo bá sọ fún eléyìí pé, ‘Lọ!’ á lọ, tí mo bá sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Wá!’ á wá, tí mo bá sì sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe báyìí!’ á ṣe é.”  Nígbà tí Jésù gbọ́ àwọn nǹkan yìí, ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà yà á lẹ́nu, ó wá yíjú sí àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé e, ó sì sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì pàápàá tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.”+ 10  Nígbà tí àwọn tí ọkùnrin náà rán wá pa dà sílé, wọ́n rí i pé ara ẹrú náà ti yá.+ 11  Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó rìnrìn àjò lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Náínì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti èrò rẹpẹtẹ sì ń bá a rìnrìn àjò. 12  Bó ṣe sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, wò ó! wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, òun nìkan ṣoṣo ni ìyá rẹ̀ bí.*+ Yàtọ̀ síyẹn, opó ni obìnrin náà. Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e látinú ìlú náà. 13  Nígbà tí Olúwa tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é,+ ó sì sọ fún un pé: “Má sunkún mọ́.”+ 14  Ló bá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kan àga ìgbókùú* náà, àwọn tó gbé e sì dúró. Ó wá sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+ 15  Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.+ 16  Ẹ̀rù ba gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ní: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa”+ àti pé, “Ọlọ́run ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀.”+ 17  Ìròyìn yìí nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká. 18  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún un.+ 19  Torí náà, Jòhánù pe méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rán wọn sí Olúwa pé kí wọ́n bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀,+ àbí ká máa retí ẹlòmíì?” 20  Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọkùnrin náà sọ pé: “Jòhánù Arinibọmi rán wa sí ọ láti béèrè pé, ‘Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?’” 21  Ní wákàtí yẹn, ó ṣe ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn,+ àwọn tó ní àrùn tó le àti àwọn tó ní ẹ̀mí burúkú, ó sì mú kí ọ̀pọ̀ afọ́jú pa dà ríran. 22  Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti rí, tí ẹ sì ti gbọ́ fún Jòhánù: Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn,+ à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+ 23  Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+ 24  Nígbà tí àwọn tí Jòhánù rán wá lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù? Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+ 25  Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni?+ Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ tó rẹwà, tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ máa ń wà? 26  Ká sòótọ́, kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 27  Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́.’+ 28  Mò ń sọ fún yín, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba Ọlọ́run tóbi jù ú lọ.”+ 29  (Nígbà tí gbogbo èèyàn àti àwọn agbowó orí gbọ́ èyí, wọ́n kéde pé olódodo ni Ọlọ́run, torí Jòhánù ti ṣe ìrìbọmi fún wọn.+ 30  Àmọ́ àwọn Farisí àti àwọn tó mọ Òfin dunjú kò ka ìmọ̀ràn* tí Ọlọ́run fún wọn sí,+ torí pé kò tíì ṣe ìrìbọmi fún wọn.) 31  “Ta ni màá wá fi àwọn èèyàn ìran yìí wé, ta ni wọ́n sì jọ?+ 32  Wọ́n dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n sì ń ké pe ara wọn, tí wọ́n ń sọ pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò sunkún.’ 33  Bákan náà, Jòhánù Arinibọmi wá, kò jẹ búrẹ́dì, kò sì mu wáìnì,+ àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ 34  Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, àmọ́ ẹ sọ pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’+ 35  Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”*+ 36  Ọkàn lára àwọn Farisí ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kó wá bá òun jẹun. Torí náà, ó wọ ilé Farisí náà, ó sì jókòó* sídìí tábìlì. 37  Wò ó! obìnrin kan tí wọ́n mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú náà gbọ́ pé ó ń jẹun* nínú ilé Farisí náà, ó sì mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá.+ 38  Ó dúró sẹ́yìn níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wá ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Bákan náà, obìnrin náà rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì da òróró onílọ́fínńdà náà sí i. 39  Nígbà tí Farisí tó pè é wá rí èyí, ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ọkùnrin yìí lóòótọ́, ó máa mọ obìnrin tó ń fọwọ́ kàn án yìí àti irú ẹni tó jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+ 40  Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Símónì, mo fẹ́ sọ nǹkan kan fún ọ.” Ó fèsì pé: “Olùkọ́, sọ ọ́!” 41  “Ọkùnrin méjì jẹ ayánilówó kan ní gbèsè; ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) owó dínárì,* àmọ́ èkejì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta (50). 42  Nígbà tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa fi san án pa dà fún un, ó dárí ji àwọn méjèèjì pátápátá. Torí náà, èwo nínú wọn ló máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” 43  Símónì dá a lóhùn pé: “Mo rò pé ẹni tó dárí púpọ̀ jì ni.” Ó sọ fún un pé: “Bí o ṣe dájọ́ yẹn tọ́.” 44  Ó wá yíjú sí obìnrin náà, ó sì sọ fún Símónì pé: “Ṣé o rí obìnrin yìí? Mo wọ ilé rẹ; o ò fún mi ní omi láti fọ ẹsẹ̀ mi. Àmọ́ obìnrin yìí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun rẹ̀ nù ún kúrò. 45  O ò fẹnu kò mí lẹ́nu, àmọ́ obìnrin yìí, láti wákàtí tí mo ti wọlé, kò yéé rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ mi. 46  O ò da òróró sí orí mi, àmọ́ obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà sí ẹsẹ̀ mi. 47  Torí èyí, mò ń sọ fún ọ, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀,* a dárí wọn jì í,+ torí ó ní ìfẹ́ púpọ̀. Àmọ́ ẹni tí a dárí díẹ̀ jì ní ìfẹ́ díẹ̀.” 48  Ó wá sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 49  Àwọn tó jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Ta ni ọkùnrin yìí tó tún lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini?”+ 50  Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là;+ máa lọ ní àlàáfíà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “òun ni ọmọ bíbí kan ṣoṣo ìyá rẹ̀.”
Tàbí “ibùsùn ìgbókùú.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Grk., “aṣọ múlọ́múlọ́.”
Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
Tàbí “a dá ọgbọ́n láre.”
Tàbí “àwọn èso rẹ̀.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ìgò.”
Tàbí “burú jáì.”