Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?

Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Orúkọ tí wọ́n ń pe ìwé Ìṣípayá lédè Gíríìkì ni A·po·kaʹly·psis (ìyẹn àpókálíìsì), èyí tó túmọ̀ sí “Ṣíṣí ìbòjú” tàbí “Fífi hàn.” Orúkọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ṣe ni ìwé Ìṣípayá ṣí ìbòjú lójú àwọn ohun kan tá ò mọ̀ tẹ́lẹ̀, tó sì fi àwọn ohun kan hàn wá tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n kọ ọ́. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ̀ kò sì tíì ṣẹ.

Ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá

Ohun tó máa jẹ́ ká lóye ìwé Ìṣípayá

  1.   Ìtumọ̀ rere ló ní fáwọn tó ń sin Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tá á máa dẹ́rù bà wọ́n tàbí dáyà já wọn. Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé àjálù ńlá ni “àpókálíìsì” túmọ̀ sí, àmọ́ ìwé Ìṣípayá sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí rẹ̀ pé aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, tó lóye rẹ̀, tó sì ń pa á mọ́.​—Ìṣípayá 1:3; 22:7.

  2.   Ìwé Ìṣípayá lo ọ̀pọ̀ “àmì,” ó sì mẹ́nu ba àwọn ohun kan lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.​—Ìṣípayá 1:1.

  3.   Àwọn ìwé míì nínú Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni pàtàkì àtàwọn ohun míì tí ìwé Ìṣípayá mẹ́nu bà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, irú bíi:

  4.   Àwọn ìran náà máa nímùúṣẹ ní “ọjọ́ Olúwa,” èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́dún 1914 tí Jésù sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Ìṣípayá 1:10) Torí náà, ó yẹ ká máa retí pé púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Ìṣípayá máa ṣẹ lákòókò wa yìí..

  5.   Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìwé tó kù nínú Bíbélì náà la nílò ká lè lóye ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, ìyẹn ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ìrànlọ́wọ́ àwọn tó ti lóye rẹ̀.​—Ìṣe 8:26-​39; Jákọ́bù 1:5.