Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 4:1-11

  • Ìran nípa bí ìtẹ́ Jèhófà ṣe rí lókè ọ̀run (1-11)

    • Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ (2)

    • Àwọn àgbààgbà 24 wà lórí ìtẹ́ (4)

    • Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà (6)

4  Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ilẹ̀kùn kan tó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn tí mo sì kọ́kọ́ gbọ́ tó ń bá mi sọ̀rọ̀ dún bíi kàkàkí, ó sọ pé: “Máa bọ̀ lókè níbí, màá sì fi àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.”  Lẹ́yìn èyí, mo wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní àyè rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+  Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà rí bí òkúta jásípérì+ àti òkúta sádísì,* òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì wà yí ká ìtẹ́ náà.+  Ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún (24) wà yí ká ìtẹ́ náà, mo rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24)+ tí wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n jókòó sórí àwọn ìtẹ́ náà, wọ́n sì dé adé wúrà.  Mànàmáná+ àti ohùn àti ààrá+ sì ń jáde wá láti ibi ìtẹ́ náà; fìtílà méje tó ní iná ń jó níwájú ìtẹ́ náà, àwọn yìí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.+  Ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ wà níwájú ìtẹ́ náà, ó dà bíi kírísítálì. Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ tí ojú kún iwájú àti ẹ̀yìn wọn wà ní àárín ìtẹ́ náà* àti yí ká ìtẹ́ náà.  Ẹ̀dá alààyè àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ẹ̀dá alààyè kejì dà bí akọ ọmọ màlúù,+ ẹ̀dá alààyè kẹta+ ní ojú bíi ti èèyàn, ẹ̀dá alààyè kẹrin+ sì dà bí ẹyẹ idì tó ń fò.+  Ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ojú kún ara rẹ̀ yí ká àti lábẹ́.+ Tọ̀sántòru ni wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà*+ Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.”+  Nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá fi ògo àti ọlá fún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé,+ tí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, 10  àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) náà+ á wólẹ̀ níwájú Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n á jọ́sìn Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọ́n á sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n á sọ pé: 11  “Jèhófà,* Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo+ àti ọlá+ àti agbára,+ torí ìwọ lo dá ohun gbogbo,+ torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “òkúta aláwọ̀ pupa tó ṣeyebíye.”
Tàbí “ní àárín pẹ̀lú ìtẹ́ náà.”