Ẹ́kísódù 40:1-38
40 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:
2 “Ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, kí o to àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà.+
3 Gbé àpótí Ẹ̀rí sínú rẹ̀,+ kí o sì ta aṣọ ìdábùú bo ibi tí Àpótí náà wà.+
4 Kí o gbé tábìlì+ náà wọlé, kí o sì to àwọn nǹkan tó yẹ kó wà lórí rẹ̀ síbẹ̀, kí o wá gbé ọ̀pá fìtílà+ wọlé, kí o sì tan àwọn fìtílà rẹ̀.+
5 Kí o gbé pẹpẹ tùràrí+ tí wọ́n fi wúrà ṣe síwájú àpótí Ẹ̀rí, kí o sì ta aṣọ* sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn.+
6 “Kí o gbé pẹpẹ ẹbọ sísun+ síwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà,
7 kí o gbé bàsíà sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+
8 Kí o wá ṣe àgbàlá+ yí i ká, kí o sì ta aṣọ*+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.
9 Lẹ́yìn náà, kí o gbé òróró àfiyanni,+ kí o fòróró yan àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+ kí o sì ya àgọ́ náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ sí mímọ́, kó lè di ohun mímọ́.
10 Kí o fòróró yan pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, kí o sì ya pẹpẹ náà sí mímọ́, kó lè di pẹpẹ mímọ́ jù lọ.+
11 Kí o fòróró yan bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́.
12 “Lẹ́yìn náà, kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+
13 Kí o wọ àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Áárónì,+ kí o fòróró yàn án,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, yóò sì di àlùfáà mi.
14 Kí o wá mú àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ tòsí, kí o sì wọ aṣọ fún wọn.+
15 Kí o fòróró yàn wọ́n bí o ṣe fòróró yan bàbá wọn,+ kí wọ́n lè di àlùfáà mi, ìran wọn á sì máa ṣiṣẹ́ àlùfáà títí lọ torí o ti fòróró yàn wọ́n.”+
16 Mósè ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.+ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
17 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún kejì, wọ́n to àgọ́ ìjọsìn náà.+
18 Nígbà tí Mósè to àgọ́ ìjọsìn náà, ó fi àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀+ sísàlẹ̀, ó to àwọn férémù,+ ó fi àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ sí i, ó sì to àwọn òpó rẹ̀.
19 Ó fi aṣọ àgọ́+ bo àgọ́ ìjọsìn náà, ó sì fi ìbòrí+ àgọ́ náà bò ó, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
20 Lẹ́yìn náà, ó mú Ẹ̀rí,+ ó sì fi sínú Àpótí náà.+ Ó ki àwọn ọ̀pá+ sí ẹ̀gbẹ́ Àpótí náà, ó sì fi ìbòrí+ bo Àpótí náà.+
21 Ó gbé Àpótí náà wá sínú àgọ́ ìjọsìn, ó sì ta aṣọ ìdábùú+ bo ibẹ̀. Ó fi bo ibi tí àpótí Ẹ̀rí náà+ wà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
22 Lẹ́yìn náà, ó gbé tábìlì+ sínú àgọ́ ìpàdé ní apá àríwá àgọ́ ìjọsìn náà ní ìta aṣọ ìdábùú,
23 ó sì to búrẹ́dì+ náà sórí ara wọn lórí rẹ̀ níwájú Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà+ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú tábìlì náà, ní apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà.
25 Ó tan àwọn fìtílà+ náà níwájú Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
26 Lẹ́yìn náà, ó gbé pẹpẹ wúrà+ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú aṣọ ìdábùú,
27 kó lè mú kí tùràrí onílọ́fínńdà+ rú èéfín lórí rẹ̀,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
28 Ó wá ta aṣọ*+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn náà.
29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà, kó lè fi ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà rúbọ lórí rẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
30 Lẹ́yìn náà, ó gbé bàsíà sí àárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, ó sì bu omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀.+
31 Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀.
32 Nígbàkigbà tí wọ́n bá wọnú àgọ́ ìpàdé tàbí tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ, wọ́n á wẹ̀,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
33 Níkẹyìn, ó ṣe àgbàlá+ yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ náà ká, ó sì ta aṣọ* sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.+
Bí Mósè ṣe parí iṣẹ́ náà nìyẹn.
34 Ìkùukùu* sì bẹ̀rẹ̀ sí í bo àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.+
35 Mósè ò lè wọnú àgọ́ ìpàdé torí pé ìkùukùu ò kúrò lórí àgọ́ náà, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.+
36 Tí ìkùukùu bá ti kúrò lórí àgọ́ ìjọsìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tú àgọ́ wọn ká bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu gbogbo ìrìn àjò wọn.+
37 Àmọ́, tí ìkùukùu náà ò bá kúrò, wọn ò ní tú àgọ́ wọn ká títí di ọjọ́ tí ìkùukùu náà bá kúrò.+
38 Torí ìkùukùu Jèhófà máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà ní ọ̀sán, iná sì máa ń wà lórí rẹ̀ ní òru, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì máa ń rí i, bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu gbogbo ìrìn àjò wọn.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”