Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ní Ìtumọ̀ Àwọn Nọ́ńbà Tí Bíbélì Lò? Ǹjẹ́ Fífi Nọ́ńbà Sọ Ìtumọ̀ Nǹkan Bá Bíbélì Mu?

Kí Ní Ìtumọ̀ Àwọn Nọ́ńbà Tí Bíbélì Lò? Ǹjẹ́ Fífi Nọ́ńbà Sọ Ìtumọ̀ Nǹkan Bá Bíbélì Mu?

Ohun tí Bíbélì sọ

 A sábà máa ń lóye àwọn nọ́ńbà inú Bíbélì gẹ́gẹ́ bó ṣe wà níbẹ̀, àmọ́ nígbà míì, Bíbélì máa ń fi àwọn nọ́ńbà yìí ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. Ohun tí Bíbélì sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ tí nọ́ńbà kan ti fara hàn ló máa pinnu bóyá Bíbélì fi nọ́ńbà náà ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. Wo ohun tí àwọn nọ́ńbà yìí ṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì:

  •   1 Ìṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ.”​—Jòhánù 17:21; Mátíù 19:6.

  •   2 Nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, ẹlẹ́rìí méjì ló máa ń fìdí òótọ́ múlẹ̀. (Diutarónómì 17:6) Bákan náà, tí Bíbélì bá tún ìran kan tàbí ọ̀rọ̀ kan sọ lẹ́ẹ̀mejì, ńṣe ló ń jẹ́rìí sí nǹkan náà pé ó dájú àti pé òótọ́ ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jósẹ́fù túmọ̀ àlá tí Fáráò ọba Íjíbítì lá, ó sọ pé: “Òtítọ́ náà pé àlá náà ni a sì fi han Fáráò lẹ́ẹ̀mejì túmọ̀ sí pé nǹkan náà fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 41:32) Ní ti àsọtẹ́lẹ̀, “ìwo méjì” tí wòlíì Dáníẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé, èyí tí Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà dúró fún.​—Dáníẹ́lì 8:20, 21; Ìṣípayá 13:11.

  •   3 Bó ṣe jẹ́ pé ẹlẹ́rìí mẹ́ta ló máa ń túbọ̀ fìdí ọ̀rọ̀ kan múlẹ̀ pé òótọ́ ni, bẹ́ẹ̀ náà ni àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ṣe máa ń fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ gbọn-in tàbí kó tẹnu mọ́ ọn.​— Ìsíkíẹ́lì 21:27; Ìṣe 10:9-​16; Ìṣípayá 4:8; 8:13.

  •   4 Nọ́ńbà yìí dúró fún nǹkan tó gún régé. Bí àpẹẹrẹ, “igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.”​—Ìṣípayá 11:12 7:1; 21:16; Aísáyà 11:12.

  •   6 Torí pé ẹyọ kan ni nọ́ńbà yìí fi dín ní méje tó dúró fún ìpé pérépéré, nígbà náà mẹ́fà á dúró fún àìpé pérépéré tàbí àìpé tàbí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Ọlọ́run.​—1 Kíróníkà 20:6; Dáníẹ́lì 3:1; Ìṣípayá 13:18.

  •   7 Bíbélì máa ń lo nọ́ńbà yìí fún ìpé pérépéré. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n yan yíká ìlú Jẹ́ríkò fún ọjọ́ méje, kí wọ́n sì tún yan ní ẹ̀ẹ̀méje yíká ìlú náà ní ọjọ́ keje. (Jóṣúà 6:15) Bíbélì fún wa ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ibi tí a ti lo nọ́ńbà náà, eéje. (Léfítíkù 4:6; 25:8; 26:18; Sáàmù 119:164; Ìṣípayá 1:20; 13:1; 17:10) Nígbà tí Jésù sọ fún Pétérù pé kó dárí jí arákùnrin rẹ̀ “kì í ṣe, títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje,” bí Jésù ṣe tún nọ́ńbà náà, eéje sọ ní ẹ̀ẹ̀mejì fí hàn pé “kò lópin.”​—Mátíù 18:21, 22.

  •   10 Nọ́ńbà yìí máa ń dúró fún gbogbo nǹkan pátápátá porogodo tàbí kí nǹkan pé géérégé.​—Ẹ́kísódù 34:28; Lúùkù 19:13; Ìṣípayá 2:10.

  •   12 Ó jọ pé nọ́ńbà yìí máa ń dúró fún nǹkan tó pé pérépéré tó sì jẹ́ ìṣètò àtọ̀runwá. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fi ìran ohun tó ṣẹlẹ̀ ní òkè ọ̀run han àpọ́sítélì Jòhánù. Jòhánù rí ìlú ńlá kan tó ní “òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá àti lára wọn, orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì méjìlá.” (Ìṣípayá 21:14; Jẹ́nẹ́sísì 49:28) Ìtumọ̀ kan náà ni nọ́ńbà méjìlá lọ́nà méjìlá dúró fún.​—Ìṣípayá 4:4; 7:4-8.

  •   40 Nọ́ńbà yìí máa ń ṣàpẹẹrẹ àwọn àkókò ìdájọ́ kan tàbí bí ìjìyà ṣe máa gùn tàbí kúrú tó.​—Jẹ́nẹ́sísì 7:4; Ìsíkíẹ́lì 29:11, 12.

Fífi Nọ́ńbà Sọ Ìtumọ̀ Nǹkan àti gematria

 Àpẹẹrẹ ni Bíbélì fi àwọn nọ́ńbà tá a gbè yẹ̀wò yìí ṣe, kò fi wọ́n sọ ìtumọ̀ nǹkan. Àwọn tó máa ń fi nọ́ńbà sọ ìtumọ̀ nǹkan máa ń fi iṣẹ́ awo kún un, wọ́n máa ń wo bí àwọn nọ́ńbà ṣe wà pa pọ̀ àti iye tí gbogbo àwọn nọ́ńbà náà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Júù tó ń ṣiṣẹ́ awo máa ń lo ọgbọ́n ìtumọ̀ nọ́ńbà kan tí wọ́n ń pè ní “gematria” láti ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, tí wọ́n á sì wo àwọn àmì kan tí wọ́n sọ pé ó fara sin láàárín àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn lẹ́tà náà dúró fún. Ara iṣẹ́ wíwò ni fífi nọ́ńbà sọ ìtumọ̀ nǹkan, Ọlọ́run sì kórìíra rẹ̀.​—Diutarónómì 18:10-​12.