Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹ̀mí Búburú

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹ̀mí Búburú

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹ̀mí Búburú

ABÚLÉ kan tó jìnnà réré ní erékùṣù Malaita ní orílẹ̀-èdè Solomon Islands ni wọ́n ti tọ́ James dàgbà. Látìgbà tó ti wà lọ́mọdé làwọn òbí ẹ̀ ti kọ́ ọ pé kó máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn ẹ̀mí. Ó sọ pé: “Kò sí nǹkan tíì bá sún mi dédìí pípe àwọn ẹ̀mí láti máa ṣèkà fáwọn èèyàn kan, àmọ́ mi ò rò pé ó ṣeé ṣe kéèyàn gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn láìlo rarafono [ìyẹn àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n máa fi ń bẹ àwọn ẹ̀mí lọ́wẹ̀] láti fi dàábò bo ara èèyàn lọ́wọ́ àwọn ayé.”

Bíi tàwọn èèyàn tó ń gbé lónírúurú ibi lágbàáyé, àwọn èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Solomon Islands náà gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí lágbára láti ranni lọ́wọ́, wọ́n sì tún lágbára láti pani lára. Kódà, inú ọ̀pọ̀ àwọn ará Melanesia máa ń dùn sáwọn ẹ̀mí tí wọ́n sọ pé ó máa ń ṣe àwọn lóore, wọn kì í sì í bẹ̀rù wọn.

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn fi máa ń jẹ́ káwọn ẹlòmíì mọ̀ pé àwọ́n mọ itú táwọn ẹ̀mí lè pa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí James wà lọ́mọdé, àwọn abiyamọ máa ń ní káwọn ọmọ wọn wọlé tí ẹyẹ kan tí wọ́n ń pè ní korokoro bá ń ké. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n gbà gbọ́ pé tẹ́yẹ yẹn bá ti ń ké, àmì pé nǹkan búburú kan fẹ́ ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan nìyẹn.

Láwọn abúlé kan, àwọn èèyàn máa ń fi òkúta funfun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sókè ẹnu ọ̀nà àbáwọlé wọn. Ohun tí James náà ṣe nìyẹn, ó gbà gbọ́ pé òkúta náà máa dáàbò bo òun lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí tó máa ń ṣèèyàn léṣe. Nígbà tí James bá sì jẹun ọ̀sán tán níbi iṣẹ́, ó máa ń kó àjẹkù sínú báàgì kan, á sì dà á nù tó bá yá. Ìdí tó fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ẹ̀rù ń bà á pé ẹni ibi kan lè kó àwọn àjẹkù náà kó sì fi sà sóun, ìyẹn sì lè sọ òun di aláìsàn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn àṣà yìí lè máà wọ́pọ̀ ládùúgbò ẹ, ó lè máa ṣèwọ náà bíi ti James pé ó yẹ kó o máa tẹ̀ lé àwọn àṣà ìbílẹ̀ yín kó o bàa lè dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú. Ó ṣeé ṣe kó o gbà gbọ́ pé ẹ̀mí ẹ wà nínú ewu tó ò bá ṣe àwọn nǹkan yìí.

Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Bíbélì, wàá fẹ́ mohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí: (1) Báwo làwọn ẹ̀mí búburú ṣe lè ṣe ẹ́ níkà? (2) Ṣáwọn ẹ̀mí búburú lè ṣe ẹ́ níkà tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan? (3) Báwo lo ṣe lè rí ojúlówó ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú, tí ìyẹn á sì fún ẹ láyọ̀?

Báwọn Ẹ̀mí Búburú Ṣe Máa Ń Ṣeni Níkà

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí àwọn tó ti kú kọ́ ló wá di àwọn ẹ̀mí búburú yìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni àwọn ẹ̀mí búburú yìí.—Ìṣípayá 12:9.

Ìwé Mímọ́ sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé a nílò ààbò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí àwọn ẹ̀mí búburú dà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—Éfésù 6:12; 1 Pétérù 5:8.

Ọ̀nà pàtàkì kan tí Sátánì máa ń gbà ṣe àwọn èèyàn níkà ni pé ó máa ń ṣì wọ́n lọ́nà, ó máa ń tàn wọ́n jẹ, ó sì máa ń fàwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run bínú sí wọn dẹ wọ́n wò. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì “máa [ń] pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ó máa ń díbọ́n bíi pé ẹ̀dá ẹ̀mí tó máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn lòun, àmọ́ elétekéte ni. Sátánì ti fọ́ àwọn èèyàn lójú inú débi tí wọn ò fi mọ irú ẹni tó jẹ́, kò sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Ọlọ́run náà jẹ́. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Kí nìdí tó fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?

Sátánì ń fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun, ìdí nìyẹn tó fi ń ṣàwọn nǹkan táwọn èèyàn á fi máa jọ́sìn ẹ̀, yálà wọ́n mọ̀ pé òun làwọn ń jọ́sìn tàbí wọn ò mọ̀. Nígbà tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run pàápàá wà láyé, Sátánì fẹ́ kó ‘wólẹ̀, kó sì jọ́sìn òun.’ Àmọ́, Jésù fún un lésì pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn.’” (Mátíù 4:9, 10) Jésù ò ṣohun tó máa mú kó dà bíi pé ńṣe lòún ń jọ́sìn Sátánì.

Jèhófà lágbára ju gbogbo ẹ̀mí èyíkéyìí lọ, kò sì ní jẹ́ kí wàhálà ayérayé kankan ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ṣèfẹ́ inú rẹ̀. (Sáàmù 83:18; Róòmù 16:20) Àmọ́, tá a bá máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ohunkóhun tó máa jẹ́ kó dà bíi pé à ń jọ́sìn Sátánì tàbí àwọn ẹ̀mí rẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn àṣà ìbílẹ̀ tó lè mú ká máa jọ́sìn àwọn ẹ̀mí búburú. Báwo lo ṣe lè mọ irú àwọn àṣà ìbílẹ̀ yìí?

Mọ Àwọn Àṣà Tínú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

Jèhófà Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣọ́ra fáwọn àṣà ìbílẹ̀ kan tó jẹ́ tàwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn. Ọlọ́run sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń . . . woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn.” Bíbélì sọ nípa àwọn tó bá ń ṣohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ yìí pé: “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Diutarónómì 18:10-12.

Nítorí náà, tó o bá ń ronú lórí àwọn àṣà kan tó wọ́pọ̀ ládùúgbò rẹ, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: Ṣáwọn àṣà yìí ò ní jẹ́ kéèyàn nígbàgbọ́ nínú iṣẹ́ wíwò? Ṣáwọn àṣà yìí ò máa dọ́gbọ́n kọ́ni pé àwọn ohun tí kò lẹ́mìí lágbára láti dáàbò boni lọ́wọ́ ewu? Ṣé àṣà yìí ò kan pé kí wọ́n máa fagbára òkùnkùn fèèdì di àwọn ẹlòmíì tàbí kí wọ́n máa fi dáàbò bo ara wọn? Ṣé àṣà yìí ò ní mú kéèyàn máa tẹrí ba fáwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan dípò Jèhófà àti aṣojú rẹ̀ tí ó yàn, ìyẹn Jésù?—Róòmù 14:11; Fílípì 2:9, 10.

Ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣọ́ra fún àṣà èyíkéyìí tó lè jẹ́ kó o lọ́wọ́ nínú àwọn àṣàkaṣà yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” Ó kìlọ̀ pé àwọn tó bá rò pé àwọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run káwọn sì tún máa jọ́sìn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan ń “ru Jèhófà lọ́kàn sókè sí owú.” (1 Kọ́ríńtì 10:20-22) Jèhófà Ọlọ́run ń béèrè pé òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn tọkàntọkàn, irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ sì tọ́ sí i.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Tún ronú lórí ìbéèrè yìí pẹ̀lú: Ṣé àṣà yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn máa gbà gbọ́ pé kò yẹ kí wọ́n máa dá èèyàn lẹ́bi fún ìwà tó bá hù? Bí àpẹẹrẹ, láwọn apá ibì kan láyé, ìwà tí kò bójú mu ni ṣíṣe panṣágà tàbí níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, Bíbélì náà sì dẹ́bi fún un. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Àmọ́, àwọn èèyàn lè máà dá obìnrin kan lẹ́bi tó bá sọ pé ọkùnrin tó bá òun lò pọ̀ ló fi èèdì di òun nípa fífún òun “lóògùn” jẹ, a ìyẹn ló sì sún òun débi tóun fi gbà pé kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun.

Àmọ́, Bíbélì kọ́ wa pé àwa èèyàn máa jíhìn fún ohunkóhun tá a bá ṣe. (Róòmù 14:12; Gálátíà 6:7) Bí àpẹẹrẹ, obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Éfà gbà pé Sátánì ló tan òun láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí, nítorí náà, mo sì jẹ.” Àmọ́, Jèhófà mú kí Éfà jíhìn fún ìwà tó hù yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:13, 16, 19) Àwa náà máa jíhìn fún Jèhófà lórí ohunkóhun tá a bá ṣe.—Hébérù 4:13.

Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe?

Tó o bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, tó o sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, o gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo nǹkan tó bá gbà láti dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn kan tó ń gbé nílùú Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n mọyì òtítọ́ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Kí wọ́n bàa lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú, wọ́n kó gbogbo ìwé tí wọ́n ní tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn “wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.”—Ìṣe 19:19.

Kí wọ́n tó dáná sun àwọn ìwé yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń wá láti ‘jẹ́wọ́, wọ́n sì ròyìn àwọn ohun tí wọ́n ṣe ní gbangba.’ (Ìṣe 19:18) Ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa Kristi wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé wọ́n dáná sun àwọn ìwé tí wọ́n ní tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn, wọn kò sì tún lọ́wọ́ sáwọn àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn láti pa àwọn àṣà ìbílẹ̀ téèyàn ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ tì. James tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nírú ìṣòro yìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ̀kọ́ yìí sì ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Àmọ́ kò fi rarafono sílẹ̀. Nígbà tó ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àṣà yìí, ó rí i pé òún nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà nípa ọjọ́ ọ̀la lóòótọ́, àmọ́ òun ṣì nílò àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan láti fi dáàbò bo ara òun.

Kí ló ran James lọ́wọ́ láti yí èrò yìí pa dà? Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bò mí, kó sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Mo sì tún pa àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí mò ń ṣe tì.” Ṣé ohunkóhun wá ṣẹlẹ̀ sí i? James sọ pé: “Rárá o, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ò ju pé mo ti kọ́ béèyàn ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Mo ti wá rí i béèyàn ṣe lè sún mọ́ Jèhófà bí ọ̀rẹ́ gidi.” Láti nǹkan bí ọdún méje sẹ́yìn báyìí ni James ti ń lo àkókò tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì.

Ìwọ náà ò ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ James? Ṣàyẹ̀wò àwọn àṣà ìbílẹ̀ àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò rẹ, kó o fi “agbára ìmọnúúrò” mọ̀ bóyá wọ́n bá “ìfẹ́ Ọlọ́run” mu. (Róòmù 12:1, 2) Lẹ́yìn náà, kó o fìgboyà gbara ẹ lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé Jèhófà máa “gbà [ẹ́] wọlé,” á sì dáàbò bò ẹ́. (2 Kọ́ríńtì 6:16-18) Bíi ti James, ìwọ náà á rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì yìí pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.”—Òwe 18:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí wọ́n bá sọ pé ọkùnrin fún obìnrin “lóògùn” jẹ, ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ọkùnrin yẹn fi oògùn tó máa jẹ́ kí obìnrin kan nífẹ̀ẹ́ òun tipátipá sínú oúnjẹ tàbí ọtí tó gbé fún un. Èyí yàtọ̀ sí lílo oògùn olóró fún obìnrin kan kí wọ́n sì wá fi tipátipá bá a lòpọ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn gbà pé obìnrin yẹn ò mọwọ́ mẹsẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ẹyẹ “Korokoro”

[Credit Line]

Látọwọ́ Dókítà Bakshi Jehangir

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ọmọbìnrin yìí ń kó àjẹkù oúnjẹ tó jẹ kúrò nílẹ̀ kẹ́nì kan má bàa fi sà sí i