Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Lagbára Ìwòsàn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Iṣẹ́ Ìyanu Lónìí Ti Wá?

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Lagbára Ìwòsàn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Iṣẹ́ Ìyanu Lónìí Ti Wá?

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Lagbára Ìwòsàn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Iṣẹ́ Ìyanu Lónìí Ti Wá?

LÁWỌN ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn sábà máa ń rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ mímọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń sọ pé ibẹ̀ làwọn ti rí ìwòsàn àrùn àti àìsàn táwọn ti rò pé kò gbóògùn. Láwọn ibòmíì sì rèé, àwọn babaláwo máa ń sọ pé àwọn ń fàwọn agbára kan tó jú agbára èèyàn lọ wo àwọn èèyàn sàn. Àwọn ibì kan sì wà táwọn onísìn ti máa ń ṣe ìsọjí, àwọn aláìsàn kan sì máa ń sọ pé àwọn rí ìwòsàn gbà níbẹ̀, àwọn arọ kan lè fò dìde látorí kẹ̀kẹ́ wọn tàbí kí wọ́n sọ igi tí wọ́n fi ń rìn nù, kí wọ́n sì sọ pé ara àwọn ti yá.

Lọ́pọ̀ ibi tá a mẹ́nu kàn yìí, ẹ̀sìn àwọn tó ń ṣerú àwọn ìwòsàn bẹ́ẹ̀ ò dọ́gba, wọ́n sábà máa ń fẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ èké kanra wọn, kódà wọ́n máa ń fẹ̀sùn Kèfèrí kan àwọn kan lára wọn. Ìbéèrè tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé, Ṣé Ọlọ́run wá lè máa fún onírúurú ìsìn tó ta kora lágbára láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu? Ó ṣe tán Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Torí náà, ṣé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lagbára ìwòsàn tí wọ́n ń pè ní iṣẹ́ ìyanu ti wá lóòótọ́? Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé agbára tí Jésù fún àwọn làwọn fi ń ṣèwòsàn. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn nígbà tó wà láyé.

Bí Jésù Ṣe Wo Àwọn Èèyàn Sàn

Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn yàtọ̀ pátápátá sí báwọn oníwòsàn òde òní ṣe ń ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn tó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Jésù ló wò sàn. Kò wo àwọn kan tó ti fojú sùn lára wọn sàn, kó wá ní káwọn tó kù máa lọ láìwò wọ́n sàn. Ó máa ń wo àwọ̀n èèyàn sàn láìkù síbì kan, ó sì fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sì ń wá ọ̀nà láti fọwọ́ kàn án, nítorí pé agbára ń jáde lọ láti ara rẹ̀, ó sì ń mú gbogbo wọn lára dá.”Lúùkù 6:19.

Lódìkejì pátápátá sáwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn ìgbàlódé tí wọ́n sábà máa ń dẹ́bi fáwọn aláìsàn tí wọn ò lè wò sàn pé ìgbàgbọ́ wọn ò tó nǹkan, Jésù ṣèwòsàn fáwọn tí kò tiẹ̀ tíì gbà á gbọ́ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jésù wo ọkùnrin afọ́jú kan sàn, láìjẹ́ pé ìyẹn pè é. Lẹ́yìn tí Jésù ti wò ó sàn tán ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bi í pé: “Ìwọ ha ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ènìyàn bí?” Ọkùnrin náà fèsì pé: “Ta ni òun, sà, kí èmi lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” Jésù wá sọ fún un pé: “Ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ ni ẹni yẹn.”—Jòhánù 9:1-7, 35-38.

O lè wá ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé kò dìgbà táwọn èèyàn bá nígbàgbọ́, kí Jésù tó wò wọ́n sàn, kí wá nìdí tó fi máa ń sọ fáwọn tó bá wò sàn pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá”?’ (Lúùkù 8:48; 17:19; 18:42) Ìdí tí Jésù fi máa ń sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn tí kò wá sọ́dọ̀ òun ń pàdánù àǹfààní láti rí ìwòsàn nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn tó wá sọ́dọ̀ òun nítorí pé wọ́n gba òun gbọ́ ń rí ìwòsàn gbà. Agbára Ọlọ́run ló wo àwọn èèyàn wọ̀nyẹn sàn kì í ṣe ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní. Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣe 10:38.

Ju tìgbàkigbà rí lọ, ipa kékeré kọ́ ni owó ń kó nínú ìwòsàn tí wọ́n sọ pé àwọ́n ń ṣe lónìí. Àwọn èèyàn mọ̀ pé ẹnu àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn máa ń dùn gan-an, ìyẹn ni wọ́n sì máa fi ń rí owó tó tówó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ìròyìn sọ pé, ọ̀kan lára àwọn oníwòsàn wọ̀nyẹn pa nǹkan tó tó mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89] owó dọ́là ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún kan, látọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó ń wo ìwòsàn tó ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pàápàá ń jèrè gọbọi látara àwọn tó ń wá ìwòsàn lọ sáwọn ilẹ̀ mímọ́. Àmọ́, Jésù ò gba owó lọ́wọ́ èyíkéyìí lára àwọn tó wò sàn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fún wọn lóúnjẹ. (Mátíù 15:30-38) Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ láti lọ wàásù ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wo àwọn aláìsàn sàn, ẹ gbé àwọn ẹni tí ó ti kú dìde, ẹ mú kí àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, ẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Kí nìdí tóhun táwọn oníwòsàn ìgbàlódé wọ̀nyí ń ṣe fi yàtọ̀ sí ti Jésù?

Ibo Ni Wọ́n Ti Rí Agbára Tí Wọ́n Láwọn Fi Ń Ṣèwòsàn?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn onímọ̀ lágbo ìṣègùn ti ń ṣàyẹ̀wò ìwòsàn táwọn onísìn sọ pé àwọ́n ń ṣe. Kí ni àbájáde àyẹ̀wò wọn? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Daily Telegraph tí wọ́n ń ṣe nílùú London ṣe sọ, dókítà kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó fi odindi ogún [20] ọdún ṣèwádìí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé: “Kò sí ẹ̀rí ìmọ̀ ìṣègùn kankan tá a lè fi ti àwọn ìwòsàn táwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn ń ṣe lẹ́yìn.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ pé agbára tó wà nínú àwọn nǹkan àtijọ́ táwọn fi ń jọ́sìn, agbára tó wà láwọn ilẹ̀ mímọ́ tàbí tàwọn onísìn tó ń ṣèwòsàn ló wo àwọn sàn. Ṣé kì í ṣe pé wọ́n ti tàn wọ́n jẹ báyìí?

Nínú ìwàásù táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó tí Jésù ṣe lórí òkè, ó ní àwọn ẹlẹ́sìn tó máa ń tan àwọn èèyàn jẹ máa sọ fóun pé: “Olúwa, Olúwa, àwa kò ha . . . ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?” Àmọ́ ó ní òún máa fún wọn lésì pé: “Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:22, 23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa ibi tírú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn ti gba agbára, ó sọ pé: “Wíwàníhìn-ín aláìlófin náà jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo.”—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn iṣẹ́ wò-ó-sàn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn nǹkan àtijọ́ táwọn èèyàn fi ń jọ́sìn, òrìṣà àti ère ò lè wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà,” ó sì tún ní ká “Ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14; 1 Jòhánù 5:21) Irú àwọn iṣẹ́ wò-ó-sàn wọ̀nyẹn wà lára àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Èṣù ń lò láti fa àwọn èèyàn kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 11:14.

Ìdí Ti Jésù Àtàwọn Àpọ́sítélì Fi Wo Àwọn Èèyàn Sàn

Àwọn ìṣẹ́ ìyanu tó jóòótọ́ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì fi wo àwọn èèyàn sàn bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi hàn kedere pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ti gba agbára. (Jòhánù 3:2; Hébérù 2:3, 4) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù sì fi wo àwọn èèyàn sàn tún kín iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe lẹ́yìn, Bíbélì sọ pé: “Ó lọ yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn.” (Mátíù 4:23) Jésù ò fàwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ṣe mọ sórí wíwo àwọn aláìsàn sàn, àmọ́ ó tún fi oúnjẹ díẹ̀ bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn, ó mú kí ìjì dáwọ́ dúró, ó tiẹ̀ tún jí òkú dìde pàápàá. Gbogbo ìyẹn jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan to máa ṣe láṣeparí fáwọn tó bá jẹ́ onígbọràn nígbà tó bá ń ṣàkóso. Ẹ ò rí i pé ìròyìn ayọ̀ gbáà lèyí!

Ìgbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ti kú, táwọn tí wọ́n sì fún nírú agbára bẹ́ẹ̀ ò sì sí láyé mọ́ ni agbára tàbí ẹ̀bùn ẹ̀mí láti ṣe irú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu bẹ́ẹ̀ ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n [tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà ìyanu] wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ [tó ṣàrà ọ̀tọ̀] wà, a óò mú un wá sí òpin.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Kí nìdí? Ìdí ni pé ńṣe ni Ọlọ́run lo àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn, títí kan agbára ìwòsàn, láti jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà àti pé inú òun dùn sí ìjọ Kristẹni, nígbà tí wọ́n sì ti wá parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ fi wọ́n ṣe, ó ti “mú wọn wá sí òpin.”

Àmọ́ ohun pàtàkì kan wà tó yẹ ká mọ̀ lónìí nípa àwọn ìwòsàn tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu ṣe. Ó yẹ ká mọ̀ pé tá a bá ń fọkàn sáwọn nǹkan tí Jésù kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, a lè máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run máa nímùúṣẹ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, àsọtẹ́lẹ̀ náà ni pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí’”—Aísáyà 33:24; 35:5, 6; Ìṣípayá 21:4.