Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Máa Tó Di Párádísè!

Ayé Máa Tó Di Párádísè!

Ayé Máa Tó Di Párádísè!

“Baba wa tí ḿ bẹ ní ọ̀run: kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé bí wọ́n tí ń ṣe ní ọ̀run.”—Mátíù 6:9, 10, Ìròhìn Ayọ̀.

ÀDÚRÀ tí tọmọdé tàgbà mọ̀ nílé lóko yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pè ní Àdúrà Olúwa, mú káráyé nírètí pé ayé ń bọ̀ wá dáa. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí Àdúrà Olúwa yìí ṣe fi hàn, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe ní ayé, bó ṣe dájú pé wọ́n ń ṣe é báyìí ní ọ̀run. Ohun tó sì jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ayé yìí tún padà di Párádísè. (Ìṣípayá 21:1-5) Ṣùgbọ́n kí ni Ìjọba Ọlọ́run yìí gan-an, báwo ni yóò sì ṣe mú kí ayé padà di Párádísè?

Ìjọba Kan Tí Ọlọ́run Gbé Kalẹ̀

Ìjọba gidi kan ni Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kí ìjọba kan tó lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ní alákòóso, àwọn òfin àtàwọn èèyàn tó máa wà lábẹ́ ìjọba náà. Ǹjẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi dáhùn ìbéèrè mẹ́ta tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Àwọn wo ni yóò ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run? (Aísáyà 33:22) Jèhófà Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi ṣe alákòóso Ìjọba yẹn. (Mátíù 28:18) Jésù wá tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, ó sì yan àwọn èèyàn kéréje kan látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” tí wọn yóò jọ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí “ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.

Àwọn òfin wo ni Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe fáwọn èèyàn abẹ́ Ìjọba náà láti máa pa mọ́? Àwọn kan lára òfin náà sọ pé káwọn èèyàn tó wà lábẹ́ Ìjọba náà máa ṣe àwọn nǹkan kan. Jésù sọ èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn òfin yẹn, ó ní: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”—Mátíù 22:37-39.

Òmíràn lára òfin Ìjọba yẹn sọ pé káwọn tó wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yàgò fáwọn ìwà kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere yìí, pé: “Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekuṣe, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgberè, àwọn oníbàjẹ́, àwọn tí ó ḿ bá ọkùnrin ṣe bí obìnrin, àwọn olè, àwọn olójú-kòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para, àwọn àbanijẹ́, àti àwọn oníjìbìtì tí yóo jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, Ìròhìn Ayọ̀.

Àwọn wo ló wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Jésù fi àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run wé àgùntàn. Ó ní: “Wọn yóò sì fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòhánù 10:16) Ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ abẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run kò ní máa fẹnu lásán sọ pé òun ń tẹ̀ lé Jésù, Olùṣọ̀ Àgùntàn Rere náà. Ó ní láti máa ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ. Jésù sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.”—Mátíù 7:21.

Nítorí náà, àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ń lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, wọ́n sì tún máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ yẹn bí Jésù náà ṣe bọ̀wọ̀ fún un. (Jòhánù 17:26) Wọ́n ń pa àṣẹ Jésù mọ́, èyí tó sọ pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn nípa “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénúdénú.—Jòhánù 13:35.

Ọlọ́run Yóò “Run Àwọn Tí Ń Run Ilẹ̀ Ayé”

Ipò tí ayé wà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe ohun tí yóò mú àyípadà pàtàkì bá ilẹ̀ ayé. Báwo la ṣe mọ̀? Ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ni Jésù ti sọ onírúurú nǹkan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lásìkò kan náà, tó máa jẹ́ àmì pé “ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Bí a sì ṣe fi hàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, à ń rí àwọn àmì yẹn kedere kárí ayé báyìí.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? Jésù sọ pé: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Kì í ṣe àwọn èèyàn ló máa fa yánpọnyánrin yìí o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tí Ọlọ́run bá ń “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé” nìyẹn máa ṣẹlẹ̀. (Ìṣípayá 11:18) Gbogbo àwọn èèyàn burúkú, tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan wọn pa ayé rẹ́, ni Ọlọ́run máa “ké . . . kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” Àwọn aláìlẹ́bi tó ń sin Ọlọ́run bó ṣe fẹ́ nìkan ni yóò “jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.”—Òwe 2:21, 22.

Ó tọ́ kí Jèhófà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Kí nìdí? Ìwọ wo àpèjúwe yìí ná: Jẹ́ ká sọ pé o kọ́ ilé kan táwọn èèyàn ń gbé. Àwọn kan lára àwọn ayálégbé tó wà níbẹ̀ jẹ́ ọmọlúwàbí tó ń gbatẹnirò, wọ́n ń sanwó ilé déédéé wọ́n sì ń tọ́jú ibùgbé wọn dáadáa. Àmọ́ àwọn míì lára àwọn ayálégbé yẹn jẹ́ oníwàhàlá àti onímọtara-ẹni-nìkan; wọn kì í sanwó ilé, wọ́n sì tún ń ba ilé yẹn jẹ́ gan-an. O kìlọ̀ fún wọn títí àmọ́ ibi pẹlẹbẹ náà lọ̀bẹ fi ń lélẹ̀. Kí lo máa ṣe? Ó dájú pé ńṣe lo máa lé àwọn tó jẹ́ ayálégbé burúkú yẹn jáde.

Bákan náà lọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé àti ohun gbogbo tó wà níbẹ̀ ṣe rí. Ó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ẹni tóun máa gbà láyè kó máa gbénú ayé. (Ìṣípayá 4:11) Jèhófà ti sọ ìpinnu rẹ̀ pé ńṣe lòun máa mú gbogbo àwọn ẹni ibi tó kọ etí ikún sọ́rọ̀ òun, tí wọ́n sì tún ń rẹ́ ọmọnìkejì wọn jẹ, kúrò láyé yìí.—Sáàmù 37:9-11.

Ayé Yóò Wá Padà Di Párádísè

Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run, tí Jésù Kristi máa jẹ́ Ọba rẹ̀ ni yóò máa ṣàkóso ayé yìí. Jésù pe ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìrọ̀rùn yìí ní ìgbà “àtúndá.” (Mátíù 19:28) Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nígbà yẹn? Wo àwọn ohun tí Bíbélì ṣèlérí yìí:

Sáàmù 46:9. “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”

Aísáyà 35:1. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”

Aísáyà 65:21-23. “Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu.”

Jòhánù 5:28, 29. “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”

Ìṣípayá 21:4. “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbà Á Gbọ́

Ǹjẹ́ o gba àwọn ìlérí inú Bíbélì yìí gbọ́? Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní gbà á gbọ́. Ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá . . . wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pétérù 3:3, 4) Ṣùgbọ́n àṣìṣe gbáà nirú àwọn olùyọṣùtì bẹ́ẹ̀ ṣe o. Ìwọ tiẹ̀ wo ìdí mẹ́rin yìí tó yẹ kó mú ọ gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́:

(1) Ọlọ́run ti dá àwọn ẹni ibi inú ayé yìí lẹ́jọ́ láwọn ìgbà kan rí. Ìkún-omi ọjọ́ Nóà jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì kan.—2 Pétérù 3:5-7.

(2) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ipò àwọn nǹkan láyé máa rí bó ṣe rí lóde òní yìí, ó sì ṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

(3) Ohun gbogbo kò máa “bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” Kò tíì sígbà kan rí láyé yìí tí ìwà ọmọ èèyàn, ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ àti ìbàyíkájẹ́ burú tó tòde òní yìí.

(4) A ń “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí” jákèjádò ayé báyìí, èyí tó ń fi hàn pé “òpin yóò . . . dé” láìpẹ́.—Mátíù 24:14.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà ọ́ níyànjú pé kó o jẹ́ ká jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, kó o lè túbọ̀ mọ̀ nípa bí ìyè àìnípẹ́kun ṣe máa ṣeé ṣe lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, aráyé máa tó bọ́ sínú ìgbádùn ayérayé. Àní sẹ́, ìgbé ayé ìrọ̀rùn dé tán! Ǹjẹ́ wàá wà nínú irú ayé bẹ́ẹ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Àṣìṣe gbáà làwọn tó sọ pé nǹkan kan kò ní yí padà láyé yìí ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ǹjẹ́ wàá wà nínú irú ayé yìí?