Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ayé Yìí Ti Fẹ́ Pa Rẹ́ Ni?

Ṣé Ayé Yìí Ti Fẹ́ Pa Rẹ́ Ni?

Ṣé Ayé Yìí Ti Fẹ́ Pa Rẹ́ Ni?

Èwo lo rò pé ó tọ̀nà nínú àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí?

Lọ́jọ́ iwájú, ayé yìí yóò

(a) dára ju bó ṣe wà yìí

(b) wà bó ṣe wà yìí

(d) burú ju bó ṣe wà yìí

ǸJẸ́ o máa ń ní in lọ́kàn pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa? Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú kéèyàn nírú èrò bẹ́ẹ̀. Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó gbà pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa sábà máa ń ṣe dáadáa nínú ohun tí wọ́n bá dáwọ́ lé, yálà nílé ìwé tàbí láwọn ọ̀nà míì. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fún ìgbà pípẹ́ tiẹ̀ fi hàn pé àwọn ọkùnrin tó bá gbà pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa kì í sábà ní àrùn ọkàn bíi tàwọn tó ti gbà pé nǹkan ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Àwọn ohun tí ìwádìí fi hàn yìí bá nǹkan tí Bíbélì sọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn mu. Ó ní: “Inú-dídùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibanujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.”—Òwe 17:22, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Ṣùgbọ́n ohun táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń sọ pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí kò fi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan burúkú tí wọ́n ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.

Ilé Ayé Wà Nínú Ewu

Àjọ kan nílùú Stockholm táwọn èèyàn ò kóyán ẹ̀ kéré, ìyẹn Stockholm Environment Institute, èyí tó ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ilé ayé, kìlọ̀ pé tá ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí bí aráyé ṣe ń torí ọrọ̀ ajé ba àyíká jẹ́, ìyẹn lè fa “àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lè kó àyípadà burúkú bá ojú ọjọ́ àti ọ̀nà táwọn ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ẹyẹ àtàwọn ohun alààyè míì gbà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ tí ayé fi ṣeé gbé.” Ìwádìí náà fi kún un pé, òṣì tó ń ta àwọn èèyàn jákèjádò ayé, àìṣẹ̀tọ́ àti ìlò àpà táwọn èèyàn ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ayé, lè mú kí ayé yìí “máa tinú àwọn ìṣòro bí ìbàyíkájẹ́ àti rògbòdìyàn láwùjọ bọ́ sínú onírúurú ìṣòro burúkú míì.”

Lọ́dún 2005, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé àbájáde ìwádìí ọlọ́dún mẹ́rin kan nípa àyíká ilẹ̀ ayé (Millennium Ecosystem Assessment) jáde. Àwọn ògbógi tí iye wọn ju òjìdínlégbèjè [1,360] láti orílẹ̀-èdè márùndínlọ́gọ́rùn–ún [95] tó ṣe ìwádìí náà kìlọ̀ nípa ewu kan pé: “Ìlò àpà táráyé ń lo ilé ayé yìí ń ṣàkóbá fún ilẹ̀ ayé àti ẹ̀dá inú rẹ̀ débi pé tá ò bá ṣọ́ra, ìran-ìran tó ń bọ̀ kò ní lè lo ayé yìí gbádùn mọ́.” Ìwé ìkìlọ̀ yìí wá sọ pé, ká tó lè yẹra fún jàǹbá ọjọ́ iwájú yìí, a ní láti “ṣe àyípadà gidi sí àwọn ìlànà táwọn ìjọba, ilé iṣẹ́ àti àjọ gbogbo, ń tẹ̀ lé títí di báyìí lórí ọ̀ràn àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ayé.”

Ìyáàfin Anna Tibaijuka tó jẹ́ olùdarí àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn ibùgbé ọmọ èèyàn, èyí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dá sílẹ̀, sọ èrò tó ń lọ lágbo àwọn olùṣèwádìí. Ó ní: “Ká mọ̀ pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́ o tá a bá jọ̀gọ nù, tá ò tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ọ̀rọ̀ bí aráyé ṣe ń ba àyíká jẹ́.”

Ìdí Tá A Fi Lè Gbà Pé Ayé Ń Bọ̀ Wá Dáa

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń tẹ ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí jáde náà gbà gbọ́ pé àyípadà àrà ọ̀tọ̀ máa tó wáyé jákèjádò ayé. Àmọ́ ṣá, ó dá wa lójú pé kò ní jẹ́ àyípadà sí burúkú bí kò ṣe èyí tí yóò mú kí ayé di ibi tó tòrò mini, tí àlàáfíà yóò sì ti jọba. Kí ló jẹ́ ká nírú ìdánilójú bẹ́ẹ̀? Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ni. Wo ọ̀kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó ní: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

Ṣé àlá tí kò lè ṣẹ lásán nirú ìrètí yìí jẹ́? Ká tó dáhùn, kọ́kọ́ ronú lórí kókó yìí ná: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ni Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa púpọ̀ nínú àwọn òkè ìṣòro tó ń bá ilẹ̀ ayé àti aráyé fínra báyìí, tó sì wá ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Jọ̀wọ́ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, kó o wá wò ó bóyá ọ̀rọ̀ wọn bá ohun tó ò ń rí pé ó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìsinsìnyí mu. Bó o ṣe ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì wọ̀nyẹn wé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí, yóò túbọ̀ máa dá ọ lójú pé Bíbélì lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lóòótọ́.