Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọ Títọ́ Láyé Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣèyí Tó Wù Wọ́n

Ọmọ Títọ́ Láyé Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣèyí Tó Wù Wọ́n

Ọmọ Títọ́ Láyé Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣèyí Tó Wù Wọ́n

Ó ṢEÉ ṣe kó o ti rí òbí tí kò fẹ́ ra nǹkan ìṣeré tọ́mọ ẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ pé kó rà fóun. O sì lè ti rí ọmọ tó fẹ́ máa lọ ṣeré, tóbìí ẹ̀ sì sọ pé “Kò gbọ́dọ̀” lọ. Wàá kíyè sí pé láwọn ìgbà tọ́mọ bá ń fẹ́ nǹkan báyìí, ohun tó máa pé ọmọ náà jù lọ lòbí máa fẹ́ ṣe. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tọ́mọ fẹ́ lòbí ń ṣe. Àbí, ìgbà tọ́mọ ò yé sunkún, tó ń rin, lòbí á bá pohùn dà, á ṣèfẹ́ inú ọmọ ẹ̀.

Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn òbí ló gbà pé òbí tó bá mọyì ọmọ ò ní ṣàìṣe ohun yòówù kọ́mọ ẹ̀ fẹ́ fún un. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n fọ̀rọ̀ wá òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́wàá [750] àwọn ọmọ tó wà láàárín ọdún méjìlá sí mẹ́tàdínlógún lẹ́nu wò nípa bó ṣe máa ń rí lára wọn báwọn òbí wọn bá sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan. Èsì àádọ́ta lé nírinwó [450] lára wọn ni pé àwọn kì í jánu lórí ẹ̀ àfìgbà tí wọ́n bá ṣe é fáwọn. Irinwó ó lé méjìlá [412] lára wọn sì sọ pé ọgbọ́n yẹn kì í bà á tì. Àfàìmọ̀ kí òbí àwọn ọmọ wọ̀nyí má lọ máa rò pé bó ṣe tọ́ láti fìfẹ́ hàn sọ́mọ nìyẹn, àmọ́ ṣó tọ́ bẹ́ẹ̀ ṣá?

Gbọ́ bí òwe kan tó fọgbọ́n yọ látinú Bíbélì ṣe kà, ó ní: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí [ayé] rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.” (Òwe 29:21) A ò sọ pé ìránṣẹ́ làwọn ọmọ wa o. Àmọ́, ṣé kò yẹ ká gbà pé ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí kan ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́? Kíkẹ́ ọmọ lákẹ̀ẹ́jù, fífún wọn ní ohun yòówù tí wọ́n bá béèrè lè sọ wọ́n di abaraámóorejẹ, àkẹ́bàjẹ́, aṣèyówùú, àti aláìmoore èèyàn tí wọ́n bá dàgbà.

Ìmọ̀ràn tí Bíbélì fáwọn òbí yàtọ̀ síyẹn. Ìmọ̀ràn náà ni pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” (Òwe 22:6) Ṣe làwọn òbí tó mọ ohun táwọn ń ṣe máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, wọ́n máa ń rí i pé òfin tó ṣe kedere táwọn gbé kalẹ̀ fìdí múlẹ̀, wọ́n máa ń dúró sórí ìpinnu wọn, ó ṣe tán, àwọn òfin náà kì í le ju èyí tọ́mọ lè tẹ̀ lé lọ. Ó yé irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ pé kò dìgbà táwọn bá gbọ̀jẹ̀gẹ́ kọ́mọ tó mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun, wọn kì í sì í fọwọ́ ra ọmọ lórí nígbà tó bá ń sunkún, tó ń kùn kiri inú ilé, tàbí tó ń bínú burúkú burúkú. Dípò ìyẹn, ọ̀rọ̀ onílàákàyè tí Jésù sọ ni wọ́n máa ń fi sọ́kàn, pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Bó bá wá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí rèé, báwo ló ṣe yẹ kéèyàn tọ́mọ? Àpẹẹrẹ àtàtà kan nìyí.

“Bí Àwọn Ọfà ní Ọwọ́”

Ọ̀nà tí Bíbélì gbà ṣàlàyé àjọṣe òbí sọ́mọ túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ó pọn dandan kí òbí tọ́ ọmọ ẹ̀ sọ́nà. Sáàmù 127:4, 5 sọ pé: “Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí. Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi wọ́n kún apó rẹ̀.” Ẹsẹ Bíbélì yìí fi àwọn ọmọ wé ọfà, ó sì fi àwọn òbí wé akin lójú ogun. Gẹ́gẹ́ bí tafàtafà ṣe mọ̀ pé òun ò kàn lè ṣèèṣì ta ọfà kó sì dé ibi tóun fẹ́ kó lọ, àwọn òbí tó fẹ́ràn ọmọ wọn mọ̀ dáadáa pé àfi káwọn sapá gan-an kọ́mọ tó lè ṣe ohun tó tọ́. Olórí àníyàn irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ni pé kọ́mọ wọn “débiire” tí wọ́n ní lọ́kàn, ìyẹn ni pé kọ́mọ ọ̀hún yàn kó yanjú, káyé ẹ̀ dùn bí oyin, kó sì mọ̀wàá hù. Wọ́n fẹ́ kọ́mọ wọn ṣèpinnu tó dáa, kó lọ́gbọ́n lórí, kó mọ béèyàn ṣeé rìn tí ò fi ní sọnù kó tó sọnú, kí ọwọ́ ẹ̀ sì tẹ nǹkan gidi tó fojú sùn. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn òbí ń fẹ́ àwọn ọmọ wọn fẹ́re, àfi káwọn òbí yáa fún ṣòkòtò wọn kó le.

Bí ọfà kan bá máa débi tí tafàtafà fẹ́ kó dé, kí ló gbọ́dọ̀ ṣe? Ó gbọ́dọ̀ gbẹ́ ọfà náà dáadáa, kó fi síbi tó láàbò tí nǹkan kan ò ti ní í gbún-un, kó sì rí i pé gbogbo agbára inú òun lòun fi ta á. Bákan náà, òbí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáadáa, kó dáàbò bò wọ́n, kó sì darí wọn síbi tó dáa kí ayé wọn bàa lè nítumọ̀ bí wọ́n bá dàgbà. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò apá mẹ́tà tí títọ́ ọmọ pín sí lọ́kọ̀ọ̀kan.

Bá A Ṣe Lè Gbẹ́ Ọfà Dáadáa

Àwọn tafàtafà ayé ọjọ́un máa ń fara balẹ̀ gbẹ́ ọfà wọn dáadáa. Àwọn igi tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ lọ́ọ̀rìn ni wọ́n sábà máa ń fi gbẹ́ ẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ni wọ́n ń lò, wọ́n máa ń rí i pé ó tọ́ dáadáa. Ṣóṣóró lẹ́nu rẹ̀ sì máa ń rí. Wọ́n máa ń fi ìyẹ́ bíi mélòó kan sídìí rẹ̀ kí atẹ́gùn má bàa gbé e gba ibòmíì.

Ohun tó jẹ òbí lógún ni bọ́mọ ẹ̀ ṣe máa rí bí ọfà tó tọ́ yẹn, ìyẹn ọfà tí atẹ́gùn kì í gbé gba ibòmíì yàtọ̀ síbi tẹ́ni tó tá a bá fẹ́ kó gbà. Torí náà, kò ní bójú mu fún òbí tó bá mọ ohun tó ń ṣe láti gbójú fo àwọn nǹkan tọ́mọ ń ṣe tí kò dáa, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́mọ náà mọ àwọn nǹkan náà, kó sì ràn án lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Bóyá la fi máa rí òbí tí kò ní ní irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ láti ṣe lórí ọmọ, ó ṣe tán Bíbélì sọ pé “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 22:15) Lọ́rọ̀ kan, ohun tí Bíbélì ń sọ ni pé, káwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn wí. (Éfésù 6:4) Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé ìbáwí ń ṣe gudugudu méje nínú títọ́ ọmọ débi tó fi máa ṣàtúnṣe tó bá yẹ lọ́kàn ara ẹ̀, tó sì máa mọ̀wàá hù.

Torí ẹ̀ ni Òwe 13:24 ṣe sọ pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.” Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀pá ìbáwí túmọ̀ sí ọ̀nà yòówù téèyàn lè gbé e gbà tọ́mọ á fi gbẹ̀kọ́. Bí òbí bá ń fìfẹ́ bá ọmọ wí, ńṣe lòbí náà ń tipa bẹ́ẹ̀ gba ọmọ lọ́wọ́ ohun tíì bá kó ìbànújẹ́ bá a dọjọ́ alẹ́ bí wọ́n bá jẹ́ kó jingíri sí i lára. Ó ti wá ṣe kedere pé, òbí tó bá kórìíra ọmọ ẹ̀ ni ò ní í bá a wí, bá a bá wá rí òbí tó ń bọ́mọ wí, a jẹ́ pé òbí ọ̀hún fẹ́ràn ọmọ ẹ̀ gan-an.

Òbí tó bá fẹ́ràn ọmọ máa ń ṣàlàyé fọ́mọ ẹ̀ ohun tó fà á tóun fi ṣe àwọn òfin tóun ṣe. Torí pé ìbáwí ju kéèyàn kàn pàṣẹ, tàbí kéèyàn fìyà jẹ ẹni tó bá tàpá sí àṣẹ, ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì ni pé kéèyàn jẹ́ kọ́mọ lóye àwọn àṣẹ náà dáadáa. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ọmọ tí ó lóye máa ń pa òfin mọ́.”—Òwe 28:7.

Ìyẹ́ tí tafàtafà máa ń fi sídìí ọfà máa ń mú kí ọfà náà lè lọ tààràtà lẹ́yìn tó bá ti ta á. Bákan náà, bí òbí bá fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jẹ́ ti Ẹni tó pilẹ̀ ìdílé kọ́ ọmọ, àwọn ẹ̀kọ́ náà kò ní kúrò lọ́kàn rẹ̀, kódà bó bá tiẹ̀ lọ ń dá gbé, àǹfààní ńlá nìyẹn sì máa jẹ́ fọ́mọ náà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Ọ̀nà wo làwọn òbí wá lè gbé e gbà táwọn ẹ̀kọ́ yẹn á fi ríbi dúró lọ́kàn àwọn ọmọ wọn?

Gbọ́ ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fáwọn òbí nígbà ayé Mósè, ó sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 6:6, 7) Nítorí náà, nǹkan méjì làwọn òbí ní láti ṣe. Àkọ́kọ́, wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa fi sílò, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n á lè fẹ́ràn òfin Ọlọ́run. (Sáàmù 119:97) Nígbà náà ni wọ́n á tó lè fi apá kejì nínú ẹsẹ Bíbélì yìí sílò, ìyẹn ni pé kí wọ́n “tẹ” òfin Ọlọ́run mọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé bí òbí bá ń kọ́ ọmọ lọ́nà tó já fáfá, tí kò sì mẹ́nu kúrò lórí ohun tó ń kọ́ ọ, ọmọ á lè rí báwọn òfin náà ṣe ṣe pàtàkì tó.

Ó ṣe kedere pé kò sígbà kankan táwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì àtàwọn ìlànà rẹ̀ kì í ṣàìwúlò, bẹ́ẹ̀ ni kò sígbà kankan tó lòdì láti fìfẹ́ bọ́mọ wí kó bàa lè ṣàtúnṣe tó yẹ sáwọn àṣìṣe rẹ̀. Àwọn ọ̀nà pàtàkì mélòó kan tá a ti jíròrò yìí á wúlò gan-an bá a bá fẹ́ mú káwọn “ọfà” ṣíṣeyebíye yìí, ìyẹn àwọn ọmọ wa gbórí dúró láti gbẹ̀kọ́ tó máa sọ wọ́n di àgbàlagbà tó mọ̀wàá hù.

Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọfà Náà

Jẹ́ ká wá padà sórí àfiwé tó wà nínú Sáàmù 127:4, 5. Wàá ṣì rántí tafàtafà yẹn tí “apó rẹ̀ kún fún” ọfà. Lẹ́yìn tó ti gbẹ́ ẹ tán, ó fi síbi tó láàbò. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú apó níbi tí nǹkan kan ò ti ní ṣe é ló fi sí. A wá lè rídìí tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà gẹ́gẹ́ bí idà dídán tí Baba rẹ̀ fi “pa mọ́ . . . sínú apó tirẹ̀.” (Aísáyà 49:2) Jèhófà Ọlọ́run, tá a mọ̀ sẹ́ni tó fẹ́ràn ẹ̀dá jù lọ dáàbò bo Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n lọ́wọ́ gbogbo ewu yòówù tó lè wu ú títí dìgbà tí Òun fúnra rẹ̀ ti ṣètò nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n pa Mèsáyà. Síbẹ̀ náà, Ọlọ́run ò gbà kí ikú rí i gbé ṣe tán pátápátá, ó rí i pé òun gbà á padà sọ́run láti lè máa gbé lọ́hùn-ún títí láé.

Jèhófà làwọn òbí máa ń fẹ́ fìwà jọ tó bá dọ̀rọ̀ kí wọ́n dáàbò bo ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn ewu tó wà nínú ayé burúkú tá à ń gbé yìí. Òbí lè ṣe òfin pé kí ọmọ òun má ṣe ṣe àwọn nǹkan kan tó lè kó o sí wàhálà. Bí àpẹẹrẹ, ìlànà kan wà táwọn òbí tó mọ ohun tí wọ́n ń ṣe kì í fẹ́ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, ìlànà náà sì ni: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Bí òbí bá ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí i pé ọmọ òun ò ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ, á tipa bẹ́ẹ̀ gba ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ àṣìṣe tó lè kó ìṣòro bá a tàbí èyí tó tiẹ̀ lè gbẹ̀mí ẹ̀ pàápàá.

Gbogbo ohun táwọn obí ń ṣe láti rí i pé àwọn ọmọ wọn ò kó sí wàhálà kì í sábà jọ àwọn ọmọ lójú. Kódà wọ́n máa ń kọ etí ikún sí ìbáwí òbí wọn lọ́pọ̀ ìgbà, nítorí náà, bó o bá máa gba ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé èyí tó pọ̀ jù lára nǹkan tó bá lóun fẹ́ ni wàá máa kọ̀ fún un. Gbajúgbajà òǹkọ̀wé kan tí ìwé rẹ̀ máa ń dá lórí ọmọ títọ́ sọ̀rọ̀, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n máa jẹ́ kó o mọ̀, kódà, bóyá gan-an ni wọ́n á fẹ́ kí ẹ pé o ṣeun lákòókò yẹn, àmọ́ òbí lọ́mọ máa ń gbójú lé bó bá dọ̀rọ̀ ààbò, àti bí wọ́n ṣe máa rìn ín nígbèésí ayé tó fi máa yẹ wọ́n. Ọ̀nà tóbìí sì lè gbà ṣe é ni pé kò má ṣe gba gbẹ̀rẹ́, kó sì jẹ́ kọ́mọ mọ irú ìwà tó gbọ́dọ̀ hù.”

Ibi tá à ń lọ la dé yìí o, ọ̀nà tí òbí lè gbà fi hàn pé òun fẹ́ràn ọmọ òun ni pé, kó máa ṣe ohun téwu kankan ò fi ní wu ú, kó sì rí i pé ọmọ náà fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Bọ́jọ́ bá ṣe ń gorí ọjọ́, ọmọ ń bọ̀ wá mọ ohun tó mú kó o ṣe àwọn òfin wọ̀nyẹn, á sì mọrírì gbogbo ọgbọ́n tó o ta téwu ò fi wu ú.

Bá A Ṣe Lè Darí Ọfà Náà

Kíyè sí bí Sáàmù 127:4, 5 ṣe fi òbí wé “abarapá ọkùnrin.” Ṣó wá túmọ̀ sí pé bàbá nìkan ló ni ojúṣe ọmọ títọ́? Rárá o. Ó dájú pé bàbá àti màmá ni àfiwé yìí ń tọ́ka sí, kódà ó tún kan òbí tó ń dá tọ́mọ. (Òwe 1:8) Ó jọ pé ohun tí gbólóhùn náà “abarapá ọkùnrin” túmọ̀ sí ni pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gan-an kó tó lè ta ọfà jáde látinú ọrun. Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, bàbà ni wọ́n sábà máa fi ń ṣe ọrun, ìyẹn ni wọ́n ṣe máa ń sọ pé ńṣe ni sójà “ń fa ọrun,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló máa fẹsẹ̀ ti ọrun náà kó tó lè fà á. (Jeremáyà 50:14, 29) Ó hàn gbangba pé agbára lèèyàn gbọ́dọ̀ fi fa okùn náà le dáadáa kó tó lè ba ohun téèyàn fẹ́ kó bà!

Bákan náà, àfi kéèyàn múra gírí kó tó lè tọ́mọ yanjú. Àwọn ọmọ ò lè dá ara wọn tọ́ yanjú bí ọfà ò ṣe lè dá ara rẹ̀ fà kó sì débi tó yẹ kó dé. Ohun kan tó kàn ń kọni lóminú ni pé ọ̀pọ̀ òbí ni kò múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti tọ́mọ lọ́nà tó yẹ. Ọ̀nà tó rọrùn ni wọ́n fẹ́. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí tẹlifíṣọ̀n, ilé ẹ̀kọ́, àtàwọn ojúgbà àwọn ọmọ náà máa bá wọn kọ́ ọmọ lóhun tó dáa àtèyí tí ò dáa, irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù, àti gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Ohun yòówù kọ́mọ wọn fẹ́, ó ti yá ni. Àtiwá sọ pé rárá fọ́mọ á dẹtì, kíá wọ́n ti ní kọ́mọ ṣe ohun tó bá wù ú, àwáwí kan tó wà lẹ́nu wọn náà ò ju pé àwọn ò fẹ́ kọ́mọ àwọn bínú. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, fífọwọ́ sí gbogbo ohun tọ́mọ bá ti béèrè gan-an lohun tó máa ṣàkóbá fọ́mọ lẹ́yìnwá ọ̀la.

Iṣẹ́ àṣekára niṣẹ́ ọmọ títọ́. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé kéèyàn wá máa fi tọkàntọkàn tọ́ ọmọ kan nílànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ o, èrè ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn Parents sọ pé: “Ìwádìí . . . ti fi hàn pé àwọn ọmọ tóbìí wọn fẹ́ràn wọn àmọ́ tí wọn kì í gbàgbàkugbà, ìyẹn àwọn òbí tó máa ń ṣìkẹ́ ọmọ àmọ́ tí wọn jẹ́ kọ́mọ mọ ohun tó gbọ́dọ̀ ṣe àtèyí tí ò gbọ́dọ̀ ṣe, sábà máa ń ṣe dáadáa nílé ẹ̀kọ́, wọ́n máa ń mọ bó ṣe yẹ kéèyàn ṣe láàárín èrò, inú wọn máa ń dùn sí àṣeyọrí tí wọ́n bá fúnra wọn ṣe, wọ́n sì máa ń láyọ̀ ju àwọn tóbìí wọn gbọ̀jẹ̀gẹ́ lọ tàbí tí wọ́n le koko jù.”

Kódà èrè míì wà tó dáa jùyẹn lọ. Wàá rántí pé a ti jíròrò díẹ̀ nínú Òwe 22:6 lẹ́ẹ̀kan, èyí tó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” Ọ̀rọ̀ ìtùnú gbáà lèyí tó ṣẹ́kú lára rẹ̀, ó ní: “Nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ṣé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé gbogbo ọmọ ló máa gbórí dúró tí òbí á fi lè tọ́ wọn yanjú? Ó ṣeé ṣe kó má rí bẹ́ẹ̀. Torí pé ọmọ rẹ ní ẹ̀tọ́ láti pinnu ohun tó bá wù ú, bó bá sì dàgbà, fúnra rẹ̀ ló máa pinnu bó ṣe fẹ́ kí ayé òun rí. Síbẹ̀, ẹsẹ yìí fẹ́ kí nǹkan kan dá àwọn òbí lójú. Kí lohun náà?

Bó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn inú Bíbélì lo fi kọ́ ọmọ rẹ, ohun tó máa jẹ́ kí etí rẹ gbọ́ ìròyìn ayọ̀ ló ti ṣe yẹn—wàá rí i pé báwọn ọmọ ẹ̀ bá dàgbà, wọ́n á láyọ̀, ìgbé ayé wọn á nítumọ̀, wọ́n á sì mọ̀wàá hù. (Òwe 23:24) Pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ tá a ti ń sọ bọ̀, ohun tó tọ́ ni pé kó o gbẹ́ àwọn “ọfà” ṣíṣeyebíye yìí dáadáa, kó o dáàbò bò wọ́n, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti darí wọn. Ó dájú pé o ò ní kábàámọ̀ láé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ṣé òbí tó bá ń ṣe gbogbo ohun tọ́mọ bá béèrè fẹ́ràn ọmọ yẹn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Òbí tó fẹ́ràn ọmọ ẹ̀ ló máa ń ṣàlàyé ìdí tóun fi ṣe àwọn òfin kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ńṣe lòbí tó mọyì ọmọ máa ń rí i pé ewu kankan ò wu ọmọ òun nínú ayé burúkú tá à ń gbé yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Iṣẹ́ àṣekára niṣẹ́ ọmọ títọ́, àmọ́ èrè rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ