Sí Àwọn Ará Éfésù 3:1-21

  • Àwọn Kèfèrí wọnú àṣírí mímọ́ (1-13)

    • Àwọn Kèfèrí di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi (6)

    • Ìpinnu ayérayé Ọlọ́run (11)

  • Àdúrà pé kí àwọn ará Éfésù ní òye (14-21)

3  Nítorí èyí, èmi, Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n + Kristi Jésù nítorí yín, ẹ̀yin èèyàn orílẹ̀-èdè,  tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ ti gbọ́ nípa iṣẹ́ ìríjú+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún mi nítorí yín,  pé a jẹ́ kí n mọ àṣírí mímọ́ nípasẹ̀ ìfihàn, bí mo ṣe kọ̀wé ní ṣókí tẹ́lẹ̀.  Torí náà, nígbà tí ẹ bá ka ìwé yìí, ẹ máa mọ òye tí mo ní nípa àṣírí mímọ́+ Kristi.  Ní àwọn ìran ìṣáájú, a kò fi àṣírí yìí han àwọn ọmọ èèyàn bí a ṣe fi han àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí lásìkò yìí,+  ìyẹn ni pé, nínú Kristi Jésù àti nípasẹ̀ ìhìn rere, kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lè di ajùmọ̀jogún, kí a jọ jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà,+ kí a sì jọ pín nínú ìlérí náà.  Mo di òjíṣẹ́ àṣírí mímọ́ yìí* nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Ó fún mi ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nígbà tó fún mi ní agbára rẹ̀.+  Èmi, tí mo kéré ju ẹni tó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́,+ la fún ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí,+ kí n lè kéde ìhìn rere nípa ọrọ̀ Kristi tí kò ṣeé díwọ̀n fún àwọn orílẹ̀-èdè,  kí n sì mú kí gbogbo èèyàn rí bí Ọlọ́run, ẹni tó dá ohun gbogbo, ṣe ń bójú tó àṣírí mímọ́+ tí a ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́. 10  Èyí rí bẹ́ẹ̀ kó lè jẹ́ pé ní báyìí, nípasẹ̀ ìjọ,+ kí a lè sọ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run fún àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ ní àwọn ibi ọ̀run.+ 11  Èyí bá ìpinnu rẹ̀ ayérayé mu, tí ó ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi,+ Jésù Olúwa wa, 12  ẹni tó jẹ́ ká ní òmìnira yìí láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, kí ọkàn wa sì balẹ̀ láti wọlé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13  Nítorí náà, mo sọ fún yín pé kí ẹ má juwọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ìpọ́njú tí mo ní lórí yín, torí wọ́n ń yọrí sí ògo fún yín.+ 14  Nítorí èyí, mo tẹ eékún mi ba fún Baba, 15  lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo ìdílé ní ọ̀run àti ní ayé ti gba orúkọ rẹ̀. 16  Mo gbàdúrà pé, nínú ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó jẹ́ kí a lè fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di alágbára nínú ẹni tí ẹ jẹ́ ní inú,+ 17  àti pé nípa ìgbàgbọ́ yín, kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín pẹ̀lú ìfẹ́.+ Kí ẹ ta gbòǹgbò,+ kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ 18  kí ẹ̀yin pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ lè lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́, 19  kí ẹ sì mọ ìfẹ́ Kristi+ tó ré kọjá ìmọ̀, kí a lè fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń fúnni kún inú yín. 20  Ní báyìí, fún ẹni tó lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn,+ gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa,+ 21  òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù títí dé gbogbo ìran láé àti láéláé. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “òjíṣẹ́ èyí.”